Ìjẹ̀bú jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà èdè Yorùbá.[1][2] Ó ṣòro láti sọ pàtó ìgbà tí a dá ìlú Ìjẹ̀bú sílẹ̀ nítorí pé àwọn àgbà tí a fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò wọ́n kò mọ̀-ọ́n-kọ tàbí mọ̀-ọ́n-kà. Ṣùgbọ́n wọ́n sọ wí pé “Ajẹbú” ni orúkọ ẹni tí ó dá ìlú Ìjẹ̀bú sílẹ̀ ń jẹ́.

Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ Ìjẹ̀bú àtúnṣe

Ìtàn ṣókí nípa Ìjẹ̀bú láti ẹnu ọmọ bíbí ìlú Ìjẹ̀bú

Ajẹbú àti Olóde jẹ́ ọdẹ. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti sọ, níbi tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ti ń dẹ igbó kiri ni wọ́n ti pàdé ara wọn nínú igbó. Báyìí ni wọ́n ṣe di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Ní ọjọ́ kan, wọ́n dá ìmọ̀ràn láàrin ara wọn pé ó yẹ kí wọ́n dá ibìkan sílẹ̀ tí àwọn yóò fi ṣe ìbùgbé lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe ọdẹ lọ. Wọ́n lọ bi Ifá léèrè, Ifá si ṣe atọ́nà Ajẹbú wí pé kí ó lọ tẹ̀dó sí ibi kan, èyí tí à ń pè ní Imẹ̀pẹ̀. Olóde àti Àjànà darapọ̀ wọ́n tẹ ibi tí à ń pè ní Ìta Ajànà dó, èyí sì wà ni ìlú Ìjẹ̀bú-Òde títí di òní yìí.

Ibojì Ajẹbú wà ní Imẹ̀pẹ̀ lẹ́bàá ọjà Òyìngbò lọ́nà Èjirín tí Olóde sì wà ní ibi tí à ń pè ní “Itún Olóde” ní Ìta Àjàná títí di òní yìí. Àwọn méjì tí ó jẹ́ akíkanjú jùlọ ìyẹn Ajẹbú àti Olóde ni a pa orúkọ wọn pọ̀ tí ó wá di “AJẸ́BU-OLÓDE” èyí tí à ń pè ní ÌJẸ̀BÚ-ÒDE títí di òní olóni yìí.

Èdè Ìjẹ̀bu ni àwọn ẹ̀yà yìí máa ń sọ. A sì le rí wọn káàkiri ilẹ̀ Nàìjíríà. Àpẹẹrẹ àwọn ìlú tí a lè rí ni ẹkùn Ìjẹ̀bú ni Ìjẹ̀bú-Òde, Musin, Ata-Ìjẹ̀bú, Imọ̀pè, Òdo-Pótu, Àgọ́-Ìwòyè, Ìjẹ̀bú-Igbó, Orù, Awà, Ìlápòrú, Ìṣònyìn, Ìpàrí-Ńlá, Òdokálàbà, Ìdọwá, Merígò, Òdoogbolú, Ọ̀ṣọṣà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìtàn sọ pé Ilé-Ifẹ́ ni wọ́n ti sí wá. Àtipé wọ́n pẹ̀lú àwọn tí ó bá Odùduwà kúrò ní Mẹ́kà nígbà tí àwọn Mùsùlùmí gbógun ti wọ́n. Adétoun (2003:1) ṣàlàyé pé orí ìtàn àtẹnudẹ́nu ni ìtàn Ìjẹ̀bú àti ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn dá lé.[3] Ọ̀kan nínú àwọn ìtàn wọ̀nyìí sọ pé Ọ̀báńta ni ó kó àwọn Ìjẹ̀bú kúrò ní Ilé-Ifẹ̀ wá tẹ̀dó sí Ìjẹ̀bú-Òde Ìtàn mìíràn fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé orísun àwọn Ìjẹ̀bú ni Wàdáì. Olú-Ìwà ni ẹni tó ṣe atọ́nà wọn wá sí ilẹ̀ Ìjẹ̀bú. Ajẹ́bu àti Olóde tẹ̀lé Olú-Ìwà nínú ìrìnàjò wọn wá sí agbègbè Ìjẹ̀bú. Wọ́n ṣèdàá orúkọ ìlú Ìjẹ̀bú-Òde láti ara àpapọ̀ orúkọ Ajẹ́bu àti Olóde tí ó jẹ́ àtèté tó gbajúgbajà.

Adétoun gbà pé àwọn Ìjẹ̀bú tí wọ́n sí wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni a lè bá ní abẹ́ ọ̀wọ́ mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ọ̀wọ́ àkọ́kọ́ ni wọ́n wà lábẹ́ Olú-Ìwà tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Ajẹ́bu àti Olóde tẹ̀lé àwọn wọ̀nyìí ni wọ́n tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìletò dó ní ìlú Ìjẹ̀bú-Òde. Ọ̀wọ́ kejì ni àwọn tó wà lábẹ́ Arisu ìbátan Olú-Ìwà. Ògborogondá tí a mọ̀ sí Ọ̀bánta tí o ń wá Olú-Ìwà baba baba rẹ tí ó ti kú kí ó tó dé ni ó jẹ́ ìpín kẹta.

Àjàlọ́run àti Balufẹ́ ni ó jẹ́ adarí ọ̀wọ́ kẹrìn. Èbúmàwé àti Òsémàwé ni ó wà ní ìpín karùn ún. Àwọn wọ̀nyìí ni ó ń gbé ní Àgọ́-Ìwòyè. Ọ̀wọ́ kẹfà ni Koyolu àti Ẹlẹ́pẹ̀ẹ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n wá láti Ilé-Ifẹ̀ láti ṣe àwárí ọ̀wọ́ ti Ọbanta. Wọ́n dé ní Ọ̀rùndún keje. Àwọn wọ̀nyìí ni ojúlówó Ìjẹ̀bú-Rẹ́mọ ní ìpìlẹ̀

Àwọn itọ́ka sí àtúnṣe

  1. Ogunkoya, T.O.. "The Early History of Ijebu". Journal of the Historical Society of Nigeria 1 (1): 48–58. https://www.africabib.org/rec.php?RID=188449442. Retrieved 2022-05-03. 
  2. Ogunkoya, T. O. (1956). "THE EARLY HISTORY OF IJEBU". Journal of the Historical Society of Nigeria (Historical Society of Nigeria) 1 (1): 48–58. ISSN 00182540. JSTOR 41856613. http://www.jstor.org/stable/41856613. Retrieved 2022-05-03. 
  3. Oluwalana, Sam; Chief, Ibadan Bureau (2016-02-29). "‘Ijebu, Igbo are Jews from Israel’ - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Retrieved 2022-05-03.