Adéníkẹ̀ẹ́ Grange

Àdàkọ:EngvarB

Adéníkẹ̀ẹ́ Grange
Ilé-iṣẹ́ ètò ìlera ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (Federal Minister of Health)
In office
26 July 2007 – 26 March 2008
AsíwájúEyitayo Lambo
Arọ́pòBabatúndé Oṣótìmẹ́yìn

Adenike Grange jẹ́ Mínísítà àná fún ètó ìlera lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ọdún 2007 sí 2008.

Ayé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àtúnṣe

Adéníkẹ̀ẹ́ Grange kàwé ní ìlú Èkó kí ó tó kọjá sí St. Francis' College, LetchworthUnited Kingdom láti tẹ̀ síwájú. Ó kàwé gboyè nínú ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó lọ́dún 1958 sí 1964 ní University of St Andrews lórílẹ̀-èdè Scotland. Ó ṣiṣẹ́ ní ilé-ìwòsàn Dudley Road Hospital ní Birmingham kí ó tó padà sí Nàìjíríà lọ́dún 1965, tí ó sìn ṣiṣẹ́ ní àwọn ilé-ìwòsàn ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Ó tún padà sí òkè-òkun, United Kingdom lọ́dún 1967, tí ó sìn ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí dókítà àwọn ọmọdé St Mary's Hospital for children. Ó kàwé gboyè dípólómà si nínú ìmọ̀ ìlera ọmọdé lọ́dún 1969. Lọ́dún 1971, ó dára pọ̀ mọ́ Lagos University Teaching Hospital, ó sìn di olùkọ́ ní Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ (College of Medicine) , Lọ́dún 1978 ní University of Lagos. Ó di olùkọ́ àgbà lọ́dún 1981,bẹ́ẹ̀ náà ó di Ọ̀jọ̀gbọ́n lọ́dún 1995.[1]

Adéníkẹ̀ẹ́ Grange ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbani-nímọ̀ràn sí ilé-iṣẹ́ ètò ìlera ìjọba àpapọ̀, Federal Ministry of Health, WHO, UNICEF, UNFPA àti USAID.[2] Òun ni olùdámọ̀ràn sí àjọ WHO ní Nàìjíríà lórí ètò ìlera ọmọ bíbí láti ọdún 1993 sí 1999. Ó ti kọ ju ìwé àádọ́ta lọ lórí ètò ìlera, pàápàá jù lọ lórí àìsàn diarrhoeal àti ètò oúnjẹ ẹ̀tọ́ fún ọmọdé. Ó jẹ́ Ààrẹ fún ẹgbẹ́ International Paediatric Association.[3] Lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, wọ́n mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí aṣègbè fún ìlera tó péye fún àwọn ọmọdé.[4]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Professor Adenike Grange" (PDF). World Health Organization. Retrieved 31 October 2009. 
  2. Pediatrics, American Academy of (2007-09-01). "Dr. Grange named Nigerian health minister" (in en). AAP News 28 (9): 40–40. ISSN 1073-0397. https://www.aappublications.org/content/28/9/40.1. 
  3. "Welcoming Adenike Grange and Gabriel Aduku". Nigeria Health Watch. 27 July 2007. Archived from the original on 29 April 2010. Retrieved 31 October 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "Article: Adenike Grange – Crusading for the African Child's Health". Women & Environments International Magazine Article. 1 October 2002. Retrieved 31 October 2009. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]