Akilu Aliyu

Akéwì ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Alhaji Dr. Aliyu Akilu M.F.R tí a bí ní ọdún 1918 tí ó saláìsí ní ọjọ́ konkàndílógún osù kewá odún 1999 tí a tún mò sí Malam Akilu Aliyu tàbí Aqilu Aliyu ni ó jẹ́ akéwì, ònkọ̀tàn, ọ̀jọ̀gbọ́n àti olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1] Ó sì tún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì láàrín àwọn akéwì ẹ̀yà Hausa lásìkò twentieth century.[2]

Nípa rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Akliu Aliyu ní ìlú Jega nínú abúlé kan tí wọ́n ń pè ní (Kyarmi) àmọ̀ tí ó ti di ìpínlẹ̀ Kebbi lóde òní. Akilu lo púpọ̀ ìṣẹ̀mí rẹ̀ ní ìlú Kano, níbi ti ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀sìn Mùsùlùmí nígbà èwe rẹ̀. Ó wà ní ìlú Maiduguri fún àìmọye ọdún ṣááj̀ú kí ó tó padà sí ìlú Kano níbi tí ó wà títí ó fi fayé sílẹ̀. Ó jẹ́ olùkọ́ ìmọ̀ ẹ̀sìn Islam, akéwì àti aránṣọ. Òun ni ó dá ilé-ẹ̀kọ́ ̀Azare sílẹ̀ ní ìlú Miaduguri.


Itokasi àtúnṣe

  1. "Akilu Aliyu". www.linguistics.ucla.edu. Archived from the original on 2012-09-07. Retrieved 2016-02-05.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. Gikandi, Simon (2003). Encyclopedia of African Literature. Taylor & Francis. p. 25. ISBN 978-1-134-58223-5. https://books.google.com/books?id=hKmCAgAAQBAJ&pg=PA25. Retrieved 2018-11-19.