Oloye Alimotu Pelewura, (1865–1951) jẹ onísòwò Naijiria kàn tó jẹ adarí ẹgbẹ awon obinrin ti oja Eko, egbé agbawi obìnrin tí o jẹ onísòwò ní Eko. O tún jẹ ẹlẹgbẹ òṣèlú pàtàkì ti Herbert Macaulay . [1]

Alimotu Pelewura
Political partyNigerian National Democratic Party

Ìgbésí ayé ìbẹ̀rẹ̀ àtúnṣe

Ìlú Eko ní wón tí bí Pelewura si idile nla kan. Ó jẹ́ àgbà ti àwọn ọmọ méjì tí ìyá rẹ̀ bí. Ìya rẹ jẹ oníṣòwò ẹja àti Pelewura tún yan ìṣòwò ẹja gégébí iṣẹ. Ní ọdún 1900, o tí di aṣáájú àwọn obìnrin àti onísòwò ọjà pàtàkì àti ní ọdún 1910, Oba Eshugbayi Eleko fún ní oye olori . Ní awọn ọdun 1920, o jẹ aṣaaju ọjà ẹran Ereko pẹlu atilẹyin Herbert Macaulay, o dìde láti di olórí ẹgbẹ tuntun tí àwọn obìnrin tí Ọjà eko. Ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yà Awori ti Yorùbá [2]

Awọn itọkasi àtúnṣe

  1. Johnson 1978, pp. 45.
  2. Historical Society of Nigeria. 1965. Tarikh. [Ikeja, Lagos State, Nigeria]: Published for the Historical Society of Nigeria by Longmans of Nigeria Ltd. P. 2