Carolyn Branch Brooks (tí wọ́n bí ní July 8, 1946) jẹ́ microbiologist ti ilẹ̀ America, tó gbajúmọ̀ fún àwọn iṣẹ́-ìwádìí rẹ̀ nínú immunology, nutrition, àti ìṣàgbéjáde ohun ọ̀gbìn.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Brooks ní July 8, ọdún 1946, ní Richmond, Virginia sínú ìdílé Shirley Booker Branch àti Charles Walker Branch, tí wọ́n dìjọ jẹ́ oní-ilé-ìtàjà. Àwọn òbí òbí rẹ̀ àti ẹ̀gbọ́nbìnrin rẹ̀ jìjọ tọ́ ọ. Ó lọ sí ilé-ìwé ní apá Àríwá Richmond. Ní àwọn ọdún tó tẹ̀lé 1950, ìdílé náà kó lọ sí apá Ìwọ̀-oòrùn ìlú náà, èyí sì mú kí ètò ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ náà le, nítorí wọ́n ní láti wọ ọkọ̀ èrò. Brooks fẹ́ lọ sí ilé-ìwé rẹ̀ àtijọ́, èyí sì mu kí ó wọ ọkọ̀ èrò lọ sí ilé-ìwé lójoojúmọ́. Lójoojúmọ́, Carolyn máa san owó ọkọ, ó sì máa jókòo sí ẹ̀yìn awakọ̀, láìmọ̀ pé ní ìbámu pẹ̀lú òfin, ó yẹ kí òun jókòó sí ẹ̀yìn ọkọ̀ náà. Lásìkò tí ẹ̀tọ̀ ọmọnìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní hànde ní Richmond, ó ri pé òun tí jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn tipẹ́ tipẹ́, láìmọ̀. [1]

Gẹ́gẹ́ bí i akẹ́kọ̀ọ́, ó lọ sí ilé-ìwé fún àwọn ọmọ sáyẹ̀ǹsì ti ilẹ̀ Africa tó tan mọ́ America, tó wà ní Virginia Union University, ní Richmond. Níbí ni iṣẹ́ agbọ̀rọ̀sọ kan nínú ẹ̀kọ́ microbiology ti wú u lórí. Pẹ̀lú àtìlẹ́yìn àwọn òbí rẹ̀, Brooks ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùkọ́ tó gbà á níyànjú láti lépa àwọn ohun tó wù ú nínú ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì. Lẹ́yìn tí wọ́n fún ní ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ìwé gíga mẹ́fá̀, ó yan Tuskegee Institute (University) ní Alabama láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa microbiology. Ní òpin ọdún kejì rẹ̀ ní ilé-ìwé, ó fẹ́ Henry Brooks, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní Tuskegee. Lásìkò tó ń kẹ́kọ̀ọ́, ó bí àwọn ọmọ méjì àkọ́kọ́ rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjì. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ọdún 1968, ó sì tẹ̀síwájú láti lọ gba oyè master's degree ní Tuskegee. Ó ní ọmọbìnrin rẹ̀ lásìkò yìí. Lásìkò tó ń kẹ́kọ̀ọ́ láti gba oyè PhD nínú ẹ̀kọ́ microbiology láti The Ohio State University, ó bímọ ìkẹrin rẹ̀, tó jẹ́ ọmọbìnrin.[2][3]

Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀ àtúnṣe

  • Award at the first annual White House Initiative on Historically Black Colleges and Universities in 1988 given to professors for "exemplary achievements as educators, researchers, and role models"
  • Award from Maryland Association for Higher Education in 1990[4][5]
  • George Washington Carver Public Service Hall of Fame Award from the Professional Agricultural Workers Conference in 2013[6]

Òun ni Minton Laureate láti the American Society of Microbiology, tí wọ́n pè sínú USDA NIFA Hall of Fame. Wọ́ sì dá a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí i ọ̀kan lára àwọn ọgọ́rùn-ún obìnrinntó gboyè aṣíwájú àti èyí tó tayọ nínú ètò ìdarí láti Experiment Station Section ní Association of Public Land Grant Universities.

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. Kessler, James H. (1996). Distinguished African American scientists of the 20th century ([Online-Ausg.]. ed.). Phoenix, Ariz.: Oryx Press. p. 27. ISBN 0-89774-955-3. https://archive.org/details/distinguishedafr00kess. "Carolyn Brooks." 
  2. Krapp, Kristine (1990). Notable black American scientists. NY: Gale. ISBN 0-7876-2789-5. https://archive.org/details/notableblackamer0000unse. 
  3. Kessler, James, H (1996). Distinguished African American Scientists of the 20th Century. Phoenix, AZ: Oryx Press. p. 27. ISBN 0-89774-955-3. https://archive.org/details/distinguishedafr00kess/page/27. 
  4. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Kessler2
  5. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Krapp2
  6. "ERROR: The requested URL could not be retrieved". 2013-06-20. Archived from the original on 2013-06-20. Retrieved 2018-04-03.