Catherine Kamau
Ọjọ́ìbíỌjọ́ kẹta ọsù kejì ọdún 1987
Kenya
Iṣẹ́Òsèré
Gbajúmọ̀ fúnSue Na Jonnie (2017)
Disconnect (2018)
Plan B (2019)
Olólùfẹ́Àdàkọ:Married
Àwọn ọmọ2

Catherine Kamau Karanja tí a bí ní ọjọ́ kẹta osù kejì ọdún 1987 jẹ́ òsèré tí ó gba ààmì ẹ̀yẹ tí gbogbo ènìyàn sì mọ́ ọ́ sí "Celina" tàbí "Kate Actress"

Ó di ẹnití àwọn ènìyàn mọ̀ látàrí ipa tí ó kó nínú eré Citizen TV "Mother In-Law" níbi tí ó ti kópa Celina. Ó tún kópa nínú àwọn eré mìíràn bí Sue na Jonie (2017-2019), Plan B, and Disconnect.

Catherine lọ sí ilé-ìwé gíga Chogoria níbití ó ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ eré tí ó sì di olókìkí fún èbùn rẹ̀, ṣaájú kí ó tó kó lọ sí Loreto Convent Msongari níbití ó ti gba Ààmì ẹ̀yẹ ‘Miss Loreto’.

Ó ní ìwé ẹ̀rí ẹ̀kọ́ gíga nípa ìbáraẹnisọ̀rọ̀, tí ó ṣe pàtàkì ní ìbásepọ̀ gbogbo gbò láti Kenya College of Communication and Technology èyítí a ṣọ di MultiMedia University of Kenya .

Kamau ni asojú àmì [1] fún ilé-isẹ́ Harpic ti orílẹ̀ ède Kenya.

Iṣẹ́ àtúnṣe

Kamau kó ipa Selina (tàbí Celina) ìyàwó Charlie ( Patrick Oketch ) lórí eré Citizen TVMother-in-Law èyítí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2006. Lẹ́yìn náà, ó kúrò ní ìfihàn eré náà lọ sí TV ède Swahili Sue Na Jonnie, èyítí ó kó ipa ti Sue.

Ó borí asíwájú òṣèré tí ó dára jùlọ ní ẹ̀ka TV Drama Series ní Kalasha Awards ní ọdún 2017 tí ó sì tún gba yíyàn ní ọdún 2018, fún ipa rẹ̀ nínú “ Sue Na Jonnie ”. wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí Òṣèré alátìlẹyín tí ó dára jùlọ ní ẹ̀ka eré oníse ti Kenya Film Commission Kalasha Awards 2018 fún ipa rẹ̀ nínú eré Disconnect.

Ó kó ipa Joyce nínú eré aláwàdà ìfẹ́ ní ọdún 2019, " Plan B ", tí Sarah Hassan ṣe tí òṣèré orílẹ̀ ède Nàìjíríà Dolápò Adélékè (Lowladee) se olùdarí. Fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Joyce, wọ́n tún yàn án lẹ́ẹ̀kan sí fún Òṣèré alátìlẹyìn tí ó dára jùlọ ní ẹ̀ka eré oníse ní ẹ̀dà kẹ̀sán ti Kenya Film Commission Kalasha Awards 2019.

Catherine Kamau tún sẹ̀sẹ̀ ṣe ìfihàn láìpẹ́ nínú àwọn eré oníse méjì The Grand Little Lie (GLL) gẹ́gẹ́ bí apákan ti òṣèré àkọ́kọ́. Eré náà di àfihàn ní ọjọ́ kínní Oṣù Kẹ̀wá ọdún 2021 Archived 2021-11-05 at the Wayback Machine. . Phil It Productions, ilé-isẹ́ ọkọ rẹ̀ Philip Karanja ni ó se àgbékalẹ̀ eré yìí. Eré mìiŕàn tí ó ṣe ni Nafsi, tí ó jẹ́ eré Multan Production Limited tí Reuben Odanga se olùdarí rẹ̀.

Ó tún jẹ́ olùdá akoonu àti YouTuber kan. Lórí ìkànnì YouTube rẹ̀, ó sọ̀rọ̀ lórí oge síse, àṣà, , ìṣeré, ìgbésí ayé àti jíjẹ́ ìyá. Ó ní ìtara lórí ọ̀ràn tí oyún ọ̀dọ́. Tí ó ti fi ìgbà kan jẹ́ ọ̀dọ́ tí ó lóyún, tí ó sì ní gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí a pè ní 'Queens must wait', nínú èyítí ó gba àwọn ọmọbìrin níyànjú láti kọ́kọ́ dúró ní ṣaájú kí wọ́n tó pinnu láti jẹ́ ìyá.

Ìgbésí ayé rẹ̀ àtúnṣe

Kamau ti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Phillip Karanja TÍ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Phil tàbi Melvin, olùdarí eré oníse àti òṣèré gíga Tahidi tẹ́lẹ̀ láti ọjọ́ kẹtàdínlógún Oṣù kọkànlá, ọdún 2017. Wọ́n ṣe ayẹyẹ ìjẹfàájì tọkọtaya ní Seychelles . Nínú ìbásepọ̀ ìṣaájú làkókò tí ó wà ní Kampala International University ní Uganda, ní ọmọ ọdún mọ́kàndílógún, ó bí ọmọkùnrin àkọ́kọ́ rẹ̀, Leon Karanja, ní ọdún 2006 ẹnití Phillip gbà tọ́. Ní Oṣù Kẹ̀sán ọdún 2019, ó jẹ́ ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ media gbé jáde wípé òhun àti ọkọ rẹ̀ ń retí àkọ́bí wọn. Wọ́n ní òsèrébìrin náà tún ti gbàlejò ayẹyẹ ìrètí ọmọ tuntun ní osù kejìlá ọdún náà láti se ayeye oyún náà eléyìí tí wọ́n sọ pé ọmọbìnrin ni yóò jẹ́. Wọ́n lọ se ayẹyẹ ìjẹfàájì ọmọ ní Maldives . Ó sàlàyé bí ó se fẹ́rẹ̀ sọ ìrètí nù láti lóyún lẹ́ẹ̀kansí. Lẹ́yìnnáà, ó ṣàfihàn ní ọjọ́ kẹèdógún Oṣù kejìlá ọdún 2019, pé ọmọ àkọ́kọ́ tí ó ní pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ jẹ́ ọmọbìrin Njeri (“Baby K”).

Eré tí ó ti kópa àtúnṣe

Odun Akọle Ipa Awọn akọsilẹ
2019 Plan B Joyce Oṣere atilẹyin
2018 Disconnect TK
Ọdun 2017-2019 Sue ni Jonnie Sue Ere Telifisonu
2006 - ọjọ Mother-in-Law Selina (Celina) Ere Telifisonu

Ààmì Ẹ̀yẹ àti yíyàn àtúnṣe

Odun Eye Akọle Ipa Awọn akọsilẹ
2019 Kalasha Awards Sue ni Jonnie Sue Oṣere Atilẹyin ti o dara julọ
2017 Kalasha Awards Sue ni Jonnie Sue Oṣere TV Drama ti o dara julọ

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe