Success Chioma Wogu (tí wọ́n bí ní 28 January 1999) jẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó ń gbá bọ́ọ̀lù fún ẹgbẹ́ Yanga Princess ní Tanzanian Women's Premier League.[2] Ó fìgbà kan gbá bọ́ọ̀lù fún ẹgbẹ́ FC Minsk ní Belarusian Premier League. Bákan náà ni ó farahàn ní Nigeria women's national football team ní ìdíje gbogboogbò. Ó ṣe ìfarahàn àkọ́kọ́ ní Africa Women Cup of Nations, nígbà tó wà lọ́mọdún mẹ́tàdínlógún (17).[3]

Success Chioma Wogu
Personal information
OrúkọSuccess Chioma Wogu
Ọjọ́ ìbí28 Oṣù Kínní 1999 (1999-01-28) (ọmọ ọdún 25)
Ibi ọjọ́ibíIbadan, Nigeria
Playing positionForward
Club information
Current clubYanga Princess
Senior career*
YearsTeamApps(Gls)
Confluence Queens(6)
2016–2020Rivers Angels[1]
2020–2022FC Minsk8(4)
2022Yanga Princess
National team
2016-Nigeria1(0)
* Senior club appearances and goals counted for the domestic league only.

† Appearances (Goals).

‡ National team caps and goals correct as of 13:20, 13 June 2019 (UTC)

Iṣẹ́ tó yàn láàyò àtúnṣe

Wogu jẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó ju ọ̀pọ̀ bọ́ọ̀lù wọlé fún Confluence Queens ní 2014 Nigeria Women Premier League, èyí tó jé ìgbà àkókó rẹ̀ nínú eré náà.[4] Ní àsìkò ìdíje 2017 Nigeria Women Premier League láàárín ẹgbẹ́ Rivers Angels àti Heartland Queens, Wogu gbá bọ́ọ̀lù kan wọlé, èyí tó sì mú kí ẹgbẹ́ rẹ̀ gba ipò kìíní.[5][6]

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà lára àwọn tó pegedé fún eré Nàìjíríà fún 2014 African Women's Championship, àkọ́nimọ̀ọ́gbá wọn, ìyẹn Edwin Okon yọ Wogu kúrò nínú ìdíje àṣekágbá.[7] Àmọ́ ní ọdún 2016, ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà, ó sì bá wọn gbá bọ́ọ̀lù ní ìtako pẹ̀lú Mali.[3]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Rivers Angels set to unveil new recruits". National Daily NG. 4 February 2016. https://nationaldailyng.com/rivers-angels-set-to-unveil-new-recruits/. Retrieved 23 December 2018. 
  2. "Tanzania Side unveil three Nigeria Players". 2022-09-05. Archived from the original on 2022-10-01. Retrieved 2024-03-28. 
  3. 3.0 3.1 "Super Falcons will not underrate Ghana, says Chioma Wogu". Goal.com. Archived from the original on 25 November 2016. Retrieved 2017-08-08.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "Chioma Wogu Targets Success With Super Falcons". All Nigeria Soccer. March 2015. Retrieved 2017-08-08. 
  5. "Wogu And Aku Shoot Angels Back On Top". Ladies March. 2017. Retrieved 2017-08-08. 
  6. "IBOM Angels end Rivers 100% home run". 2017. Retrieved 2017-08-08. 
  7. "SL10 Chats To Chioma Wogu". sl10.ng. November 2014. Archived from the original on 17 August 2017. Retrieved 2017-08-08.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)