Colleen Higgs (ni a bí ní ọdún 1962 ní Kimberley, Gúúsù Áfíríkà) ó jẹ́ òǹkọ̀wé àti atẹ̀wéjáde ti Gúúsù Áfíríkà. Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé, ó ti ṣe Àtẹ̀jáde ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé ewì àti ìtàn kékéèké nínú ìwé àtìgbàdégbà ní Gúúsù Áfríkà bẹ̀rẹ̀ láti bí ọdún 1990. Gẹ́gẹ́ bí atẹ̀wéjáde, ó jẹ́ gbajúgbajà àti ẹni-ọ̀wọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ ìtẹ̀wéjáde "independent publishing house, Modjaji Books".

Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ àtúnṣe

Higgs lọ ìgbà ọmọdé rẹ̀ ní ìlú Lesotho, ìgbà èwe àti ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀ ló lò ní ìlú Johannesburg, ní lọ́ọ́lọ́ yìí ni ó lò ọdún márùn-ún ní ìlú Grahamstown. Ní ìlú Cape Town ni ó ń gbé báyìí. Ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, Ẹni tó ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn olùkọ́, òǹkọ̀wé àti olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga amẹ́kọ̀ọ́gbòòrò àti olùdarí ètò ilé-iṣẹ́ "The Centre for the Book" . Ó jẹ́ olùdásílẹ̀ àti atẹ̀wéjáde ní ilé-iṣẹ́ ìtẹ̀wéjáde "Modjaji Books", ilé-iṣé ìtẹ̀wéjáde tó dá dúró tí ó sì wà ní ìlú Cape Town, èyí tó ń tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé tí àwọn obìnrin ń kọ jáde. Ní báyìí àwọn ìtàn kékéèké, ìwé ìtàn-ara-ẹni, ìtàn, ìwé-ewì àti ìtàn-abójú-ayé-mu tí ilé-iṣẹ́ ìtẹ̀wéjáde tí tẹ̀ jáde: Whiplash by Tracey Farren ni a kà mọ́ àwọn ìwé ìtàn a bójú-ayé-mú fún àmì-ẹ̀yẹ Times Fiction award.[1]

Higgs tún jẹ́ akéwì, tí a sì ti ń tẹ ewì rẹ̀ jáde nínú ìwé-àtìgbàdégbà láti nǹkan bí ọdún 1990. Ìwé àkójọpọ̀ ewì rẹ̀ àkọ́kọ́ction, Halfborn Woni a tẹ̀ jáde ní ọdún 2004.[2]

Ìkànnì ayélujára rẹ̀ (on BooksLive) ni à ń ṣe àfikún láti ìgbàdégbà pẹ̀lú àwọn àkòónú àtúngbéyẹ̀wò, ìròyìn, àwọn àpilẹ̀kọ àti ojú-àmúwayé lórí ìtẹ̀wéjáde Gúúsù Áfíríkà.[3] Ní ọdún 2020 ni a tẹ ìwé ìtàn nípa ara-ẹni rẹ̀ My Mother, My Madness jáde.[4]

Àwọn Iṣẹ́ Rẹ̀ àtúnṣe

  • Halfborn Woman (2004), Hands-On Books collection of poems
  • A Rough Guide to Small-scale and Self-publishing (2005), Centre for the Book
  • South African Small Publishers' Catalogue (editor with Maire Fisher) (2006), Centre for the Book
  • Small Publishers' Catalogue - Africa, 2010 (2010) (editor with Bontle Senne)
  • Lava Lamp Poems (2011), Hands-On Books, collection of poems
  • Looking for Trouble: mostly Yeoville stories (2012), Hands-On Books, collection of stories
  • Small Publishers' Catalogue - Africa, 2013 (2013)
  • My Mother, My Madness (2020), Deep South

Àwọn Ìwé Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. Colleen Higgs on Modjaji Books Archived 31 January 2010 at the Wayback Machine.. Retrieved 28 October 2009.
  2. Roll Over, Gutenberg! Interview with Colleen Higgs Archived 12 May 2008 at the Wayback Machine., Absolut Write. Retrieved 7 February 2008.
  3. Colleen Higgs' Bookslive Blog Archived 2012-03-13 at the Wayback Machine.. Retrieved 28 October 2009.
  4. "Founder of Modjaji Books Publishes New Memoir on Her Mother’s Final Years". 31 July 2020. https://brittlepaper.com/2020/07/founder-of-modjaji-books-publishes-new-memoir-on-motherhood/. 

Àdàkọ:Authority control