Ilera Eko ni ètò ìlera tí ìjọba Èkó gbé kalẹ̀ lábẹ́ ilé-iṣẹ́ Lagos State Health Management Agency (LASHMA) láti lè jẹ́ kí tẹrú-tọmọ, tólówó ti mẹ̀kúnù lẹ́sẹ̀ kùkú ó jẹ mùkútùn ètò ìlera tó péye pẹ̀lú owó pọ́ọ́kú. Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó tún gbé ìgbésẹ̀ láti ṣí ẹ̀ka ètò ìlera yí káàkiri gbogbo agbègbè Ìpínlẹ̀ Èkó.[1]


Iṣẹ́ àjọ Ìlera Èkó àtúnṣe

Àwọn iṣẹ́ tí àjọ ìlera Èkó gbá ń mójútó pọ̀, lára rẹ̀ ni ìpèsè ìléra lórí ìtọ́jú awọn àìsàn pẹ́pẹ̀pẹ́ bí àìsàn ibà, àìsàn ikọ́ fére, HIV. Bákan náà ni wọ́n ń ṣètọ́jú àwọn àìsàn tí kò mú iṣẹ́ abẹ rẹpẹtẹ lọ́wọ́ bíi: àìsàn làkúrègbé, àìsàn ìtọ̀-ṣúgà, àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ojúṣe wọn sì ún ni láti ṣiṣẹ́ gbógun ti ìtàkánlẹ̀ ajàkálẹ̀ arùn ní ìpínlẹ̀ náà. [2]

Àwọn ará ìlú yóò ma jẹ̀gbádùn ètò ìlera olówó pọ́ọ́kú yí nígbà tí eọ́n bá ti forúkọ sílẹ̀ sábẹ́ ilé-iṣẹ́ ọ̀hún pẹ̀lú owó péréte. Wọn yóò láànfàní sí ètò ayẹ̀wò ìlera ọ̀fẹ́, oògùn ọ̀fẹ́ ati bí wọn yóò ṣe lòó.

Ètò Ìforúkọsílẹ̀ àtúnṣe

Àwọn ènìyàn yóò ma lánfaní sí oògùn ọ̀fẹ́, àyẹ̀wò ọ̀fẹ́, lórí mọ̀lèbí ẹlẹ́ni mẹ́fà. Ìyẹn (Bàbá, Ìyá, àti ọmọ mẹ́rin) pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (#40.000.00), fún odidi ọdún kan gbáko.

Agbékalẹ̀ rẹ̀ àtúnṣe

Àjọ tó ń rí sí agbékalẹ̀ òfin ati àlàkalẹ̀ iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó buwọ́ lu State Health Scheme Law ní inú oṣù Karùn-ún ọdún 2015 èyí tí ó ṣe ìfilọ́ọ́lẹ̀ , LASHMA lábẹ́ Lagos State Health Scheme (LSHS) ati the Lagos State Health Fund (LSHF).[3]

Àwọn ìtọ́ka sí àtúnṣe

  1. "As Lagos spreads the good news of 'Ilera Eko' - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2021-09-15. Retrieved 2022-02-10. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  2. "Ilera Eko". The Nation Newspaper. 2021-11-03. Retrieved 2022-02-10. 
  3. "Health insurance: Lagos takes “Ilera Eko” to communities". Vanguard News. 2021-12-08. Retrieved 2022-02-10.