James Franklin Baskett (ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kejì ọdún 1904 – ọjọ́ kẹsàn-án oṣù keje ọdún 1948) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Òṣèré oní tíátà àti olórin ni pẹ̀lú. Ó kópa nínú eré Song of the South tí Disney ṣe àgbéjáde rẹ̀ ní ọdún 1946 gẹ́gẹ́ bíi Ọńkúú Remus tó kọ orin "Zip-a-Dee-Doo-Dah".

Fún ìdánimọ̀ lórí ipa tí ó kó gẹ́gẹ́ bíi Remus, ó gba àmì ẹ̀yẹ ní ọdún 1948, èyí tí ó sọ ó di òṣèré ọkùnrin-adúláwọ̀ tí ó kọ́kọ́ gba irú àmì ẹ̀yẹ báyìí.

Iṣẹ́ àtúnṣe

Ọ̀gbẹ́ni Baskett kẹ́kọ̀ọ́ famakọ́lọ́jì fún ìgbà díẹ̀ ní ìgbà ọ̀dọ́ ayé rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀ láti lépa iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré oní tíátà. Ó kó lọ sí New York, láti pàdé Bill 'Mr. Bojangles' Robinson. Ní ọdún 1941, ó fi ohùn rẹ̀ ṣe Fats Crows nínú fíìmù àwọn ọmọdé tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Dumbo, ó sì tún kọ́pa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ B movies, bíi Revenge of the Zombies ní ọdún 1943, The Heavenly Body ní ọdún 1944, àti eré tí wọ́n ti lo èdè ìbílẹ̀ ti Orbon, tí àkọ́lé rè ń jẹ́ Jungle Queen ní 1945.[1][2]Làti ọdún 1944 títí dé ọdún1948, ó kópa pẹ̀lú àwọn mìíràn nínú ètò orí rédíò tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Amos 'n' Andy Show gẹ́gẹ́ bíi agbẹjórò Gabby Gibson.Ní 1945,ó lọ fún ìdánwò-ìgbanisiṣẹ́ ti fíìmù titun Disney Song of the South (1946), tí ó dá lórí àwọn ìtàn Uncle Remus tí Joel Chandler Harris kọ. Lọ́gán ni Walt Disney rí ẹ̀bùn Baskett ó sì gbéṣẹ́ nàà fun-un lójú ẹsẹ̀.

Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀ àtúnṣe

Ọdún Àkọ́lé Ipa Ìsọníṣókí
1932 Harlem Is Heaven Money Johnson Film debut; credited as Jimmy Baskette
1933 20,000 Cheers for the Chain Gang Vocalist Uncredited
1938 Gone Harlem unknown Credited as Jimmie Baskette
1938 Policy Man unknown Credited as Jimmie Baskette
1939 Straight to Heaven First Detective
1940 Comes Midnight unknown
1941 Dumbo Fats Crow (voice) Uncredited
1943 Revenge of the Zombies Lazarus Alternative title: The Corpse Vanished
1944 The Heavenly Body Porter Uncredited
1945 Jungle Queen Orbon Credited as Jim Basquette
1946 Song of the South
  • Uncle Remus
  • Ohùn Br'er Fox
(final film roles)

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Movies till Dawn: Almost Weirder Than Now". April 7, 2020. 
  2. "Jungle Queen". April 16, 2015.