Kabirah Kafidipe jẹ́ òṣèré ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí Araparegangan fún ipa tí ó kó nínú eré Saworoide ní ọdún 1999 èyí tí Tunde Kelani gbé jáde.[1][2]

Kabirah Kafidipe
Ọjọ́ìbíAbeokuta, Ogun State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́
  • actress
  • producer
  • director
Ìgbà iṣẹ́1996–present
Gbajúmọ̀ fúnDazzling Mirage
The Narrow Path
Iwalewa
The White Handkerchief

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Kafidipe ní ọjọ́ kọkàndínlógbọ̀n oṣù keje. Ó jẹ́ ọmọ ìlú Ikereku ní Abẹ́òkúta. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Abeokuta Grammar School kí ó tó tẹ̀ síwájú sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Olabisi Onabanjo University níbi tí ó tí gboyè nínú ìmò Mass Communication.[3]

Iṣẹ́ àtúnṣe

Kabirah bẹ̀rẹ́ eré ṣíṣe pèlú eré The White Handkerchief. Ó gbajúmọ̀ nígbà tí ó kópa nínú eré Saworoide ní ọdún 1999 pẹ̀lú àwọn òṣèré gbajúmọ̀ bíi Kunle Afolayan, Peter Fatomilola, Kola Oyewo, Yemi Shodimu[4]. Ní ọdún 2004, ó kópa nínú eré The Campus Queen. [5]Ipa tí ó kó nínú eré Iwalewa ni ó jẹ́ kí ó gba àmì ẹ̀yẹ òṣèré bìnrin to dára jù lọ láti ọ̀dọ̀ Africa Movie Academy Award.[6][7] Ní ọdún 2014, ó kópa nínú eré dírámà Dazzling Mirage.[8][9] Ó gbé eré ti rẹ̀ jáde ní ọdún 2015, ó sì pe àkòrí rẹ ní Bintu.[10]

Àwọn Ìtọ́kàsi àtúnṣe

  1. Latestnigeriannews. "Why Khabirat Kafidipe is scared of Nigerian men". Latest Nigerian News. 
  2. "Ayo Mogaji, Kafidipe for Awoyes Premiere". Modern Ghana. 
  3. "Nigerian men scare me –Khabirat Kafidipe". The Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 2015-04-11.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "MEN IN NIGERIA ARE OPPORTUNISTS----KABIRAT KAFIDIPE". nigeriafilms.com. Archived from the original on 2015-04-18.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. agboola. "When pages flip to inhabit screens". Weekly Trust. 
  6. Coker, Onikepo (4 May 2007). "Africa Celebrates Film Industry at AMAA 2007". Mshale Newspaper (Minneapolis, USA: Mshale Communications). Archived from the original on 3 March 2012. https://web.archive.org/web/20120303204433/http://www.mshale.com/article.cfm?articleID=1407. Retrieved 5 April 2015. 
  7. "AMAA Awards and Nominees 2007". African Movie Academy Award. Archived from the original on 12 October 2010. Retrieved 5 April 2015. 
  8. Victor Akande. "Tunde Kelani’s Dazzling Mirage premieres today". The Nation. 
  9. Daily Times Nigeria. "Daily Times Nigeria". Archived from the original on 8 November 2014. Retrieved 5 November 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  10. "We will celebrate Bintu home and abroad –Kabirah". The Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 2015-04-08.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)