Kim Hunter (tí a bí Janet Cole; Oṣù kọkànlá ọjọ́ kejìlá ọdún 1922 sí Oṣù kẹsán-án ọjọ́ kọkànlá, ọdún 2002) jẹ́ òṣèré ìtàgé, fíìmù, àti tẹlifísàn. Ó ṣe àṣeyọrí fún ìṣàfihàn Stella Kowalski nínú ìṣelọ́pọ̀ àtilébá ti A Streetcar Named Desire ti Tennessee Williams èyí tí ó àtúnwí fún àṣàmúdọ́gba fíìmù ọdún 1951 tí ó sì gba ẹ̀bùn Akádẹ́mì àti Golden Globe Award fún òṣèré àtìlẹ́yìn obìnrin tí ó dára jùlọ

Kim Hunter
Ọjọ́ìbíJanet Cole
(1922-11-12)Oṣù Kọkànlá 12, 1922
Detroit, Michigan, U.S.
AláìsíSeptember 11, 2002(2002-09-11) (ọmọ ọdún 79)
New York City, U.S.
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́1943–2001
Olólùfẹ́
William Baldwin
(m. 1944; div. 1946)

Robert Emmett
(m. 1951; his death 2000)
Àwọn ọmọ2

Lẹ́hìn ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n yàn-án fún Daytime Emmy Award kan fún iṣẹ́ rẹ̀ lórí eré járá kan "The Edge of Night".[1] Ó tún ṣàfihàn Chimpanzee Zira ní Planet of the Apes (ọdún 1968), àti apá yòókù tí ó tẹ̀lé "Beneath the Planet of the Apes (ọdún 1970) àti Escape from the Planet of the Apes (ọdún 1971).

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Hunter ní Detroit, Michigan, ọmọ obìnrin ti Grace Lind, tí ó kẹ́kọ̀ọ́ bí(concert pianist), àti Donald Cole, ẹ̀lẹ́rọ firiji.[2] Ó jẹ́ ọmọ Gẹ̀ẹ́sì àti ti ìran Welsh.[3] Hunter lọ sí Miami Beach High School.[4]

Ìgbésí Ayé Ti Rẹ̀ àtúnṣe

Hunter ti ṣe ìgbéyàwó ní ẹ̀mejì, àkọ́kọ́ ni sí William Baldwin, Marine Corps pilot kan ní ọdún 1944. Tọkọ àti ìyàwó jọ ní ọmọ obìnrin pọ̀, èyí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kathryn Deirdre, kí wọ́n tó kọ ara wọn lẹ́hìn ọdún méjì. Ó ṣe ìgbéyàwó sí Robert Emmett ní ọdún 1951.[5] Hunter àti Emmett ní ìgbà sí ìgbà máa ń ṣe eré papọ̀ lórí eré ìtàgé; Emmett kú ní ọdún 2000.[6]

Hunter jẹ́ Democrat tó ní ìlọsíwájú ti ẹ̀mí.[7] Ó kú ní ilẹ̀ New York ní oṣù kẹ̀sán-án ọjọ́ kọkànlá, ọdún 2002, nípa ìkọlù ọkàn ní ọmọ ọdún ọ̀kàn-dín-lọ́gọ́run.[5][6][8] A fi eérú rè fún ọmọ obìnrin rẹ̀ – àgbẹjọ́rọ̀ kan, olórí ìlú, àti adájọ́ ti tẹ́lẹ̀ ní Connecticut[9] — lẹ́hín sísùn.[10]

Ogún Rẹ̀ àtúnṣe

Hunter gba àwọn ìràwọ̀ méjì lórí Hollywood Walk of Fame, ọ̀kan fún àwòrán isípòpadà ní 1615 Vibe Street àti ìṣéjú kan fún tẹlifísàn ní 1715 Vine Street.

Àwọn Ìtọ́ka Sí àtúnṣe

  1. "1980 Emmy Winners & Nominees". Soap Opera Digest. Archived from the original on August 18, 2004. https://web.archive.org/web/20040818104130/http://www.soapoperadigest.com/emmys/winners1980/. Retrieved June 28, 2013. 
  2. Ross, Lillian; Ross, Helen (April 8, 1961). The Player A Profile Of An Art. Simon And Schuster. p. 320. https://archive.org/details/playeraprofileof002609mbp/page/n319/mode/2up?q=donald+cole. Retrieved October 29, 2021. 
  3. Collura, Joe (October 23, 2009). "Kim Hunter". Classic Images. Archived from the original on September 24, 2019. https://web.archive.org/web/20190924210411/https://www.classicimages.com/people/article_6caaaef5-251f-526c-a92f-e616a26e3a42.html. 
  4. "Kim Hunter". Hollywood Walk of Fame. Retrieved December 20, 2018. 
  5. 5.0 5.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named guardian
  6. 6.0 6.1 "Kim Hunter". The Daily Telegraph (London). September 12, 2002. https://www.telegraph.co.uk/news/obituaries/1407005/Kim-Hunter.html. 
  7. Lyman, Rick (September 12, 2002). "Kim Hunter, 79, an Actress Lauded as Stella in 'Streetcar'". The New York Times. https://www.nytimes.com/2002/09/12/arts/kim-hunter-79-an-actress-lauded-as-stella-in-streetcar.html. 
  8. "Kim Hunter Obituary". Legacy. Archived from the original on 2017-02-05. Retrieved 2017-02-05.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  9. "Kathryn Emmett". Franklin Street Works. Retrieved 12 February 2022. 
  10. Wilson, Scott (September 16, 2016). Resting Places: The Burial Sites of More Than 14,000 Famous Persons (3d ed.). McFarland. ISBN 978-1-4766-2599-7. https://books.google.com/books?id=FOHgDAAAQBAJ&q=Kim+Hunter+burial+cremated&pg=PA362.