Mo'Hits Records ( tí ó gbajúgbajà gẹ́gẹ́ bí i Mo'Hits) jẹ́ ilé-iṣẹ́ agbórin-jáde ní orílèdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, tí ń ṣe ti D'banj àti Don Jazzy.[1] Gẹ́gẹ́ bí i àjọ tó ń rí sí gbígba orúkọ àwọn ilé-iṣẹ́ sílẹ̀(CAC),ilé-iṣẹ́ Mo'Hits jẹ́ èyí tí wọ́n dálẹ̀ ní 2006, tí D'banj jẹ́ olórin àkọ́kọ́ ti ilé-iṣẹ́ náà ní. Don Jazzy jẹ́ olùdarí ilé-iṣẹ́ náà, tí D'banj síì jẹ́ alábásepọ̀ rẹ̀. Ilé-iṣé náà gba àwọn olórin mìíràn wọlé, àwọn ni Wande Coal, Dr SID, D'Prince, àti K-Switch.- Oríṣi-orin tí ó kan ilé-iṣẹ́ náà ni Afrobeat.


Awo-orin àkọ́kọ́ láti ilé-iṣẹ́ náà ni ti D'banj No Long Thing ní 2005. Àwọn awo-orin mìíràn ni Rundown & The Entertainer (D'banj), Mushin2Mohits (Wande Coal) & Turning Point (Dr SID). Atòjọ awo-orin láti Ilé-iṣẹ́ náà ni Mo'Hits All Stars. Don Jazzy ti gba àwọn ìyìn lóríṣiŕṣi tí wọ́n pẹ̀lú Nigeria Music Awards (NMA), agbórin-jáde ti ọdún 2006, àti Nigeria Entertainment Awards. Agbórin-jáde ti ọdún 2007.


Ìfàmọ́ra láti àwọn ìṣe òkèèrè bí i Kanye West àti Jay-Z wọle kan ilé-iṣẹ́ náà àti pé D'banj di gbígbà wolé Kanye's GOOD Music.


Òpin dé bá ilé-iṣẹ́ náà nígbà tí Don Jazzy tẹ̀ síwájú láti lọ ṣẹ̀dá Mavins Record tí D'banj náà bẹ̀rẹ̀ DB record label.

Àwọn Itọ́kasí àtúnṣe

  1. "D'Banj And Don Jazzy Who Is Richer/Older? | Constative.com". Constative - News, Celebrity Lifestyle, Facts And References (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-10-02. Retrieved 2016-05-13.