Samantha Wynne Vice (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹta ọdún 1973) jẹ́ South African oníwòye ọmọ ìlú South Africa. Ó sì tún jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní University of the Witwatersrand (Wits). Ẹ̀ka iṣẹ́ rẹ̀ ni ethics àti ìwòye agbègbè, ní báyìí ó ti gbajúmọ̀ fún àwọn iṣẹ́ rẹ̀ lórí àwọn ìwòye tó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ àti ìwòye ajẹmọ́wà àti ẹ̀dá ènìyàn.

Samantha Vice
Born12 Oṣù Kẹta 1973 (1973-03-12) (ọmọ ọdún 51)
CitizenshipSouth Africa
InstitutionsRhodes University, University of the Witwatersrand
Doctoral advisorJohn Cottingham
Notable awardsCommonwealth Scholarship (1999)

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti àwọn ipò tí ó dìmú àtúnṣe

Orílẹ̀-èdè South Africa ni wọ́n bí Vice sí, ó sì gboyè bachelor's àti master's ní Rhodes University. Ní ọdún 2003, ó gboyè PhD nínú ẹ̀kọ́ ìwòye ní University of Reading, èyí tí ó lọ látàrí ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tí ó gbà lọ́wọ́ Commonwealth.[1] Lẹ́yìn náà, ó dára pọ̀ mọ́ philosophy faculty ní ilé-ẹ̀kọ́ Rhodes,[1] tó sì pàpà di olórí ẹ̀ka náà.[2] Ní ọdún 2011, ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti Rhodes Vice-Chancellor's Distinguished Research Award, èyí tí wọ́n pèsè sílẹ̀ fún àwọn olórí ẹ̀ka ẹ̀kọ́ tí ó jẹ́ ọmọ ogójì ọdún àti sílẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́-ìwádìí.[3]

Ní oṣù kìíní ọdún 2015, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bíi ọ̀jọ̀gbọ́n ní Wits, níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìwòye àti ní Wits Centre for Ethics.[2] Wọ́n gbà á sí Academy of Science of South Africa ní oṣù kẹwàá ọdún 2021.[4]

Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtúnṣe

Iṣẹ́ Vice tí ó dára jù lọ nípa ẹ̀yà ni 'white privilege' àti 'white guilt'. Àyọkà rẹ̀ ti ọdún 2010 tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "'How Do I Live in This Strange Place?'", tí ó tẹ̀ jáde ní Journal of Social Philosophy lásìkò tí ó wà ní Rhodes, ni ó ti sọ̀rọ̀ nípa ìtìjú àti ìdálẹ́bi tí ó jẹ́ ìrírí àwọn ará Òyìnbó ní ilẹ̀ South Africa. [5] Lẹ́yìn tí Eusebius McKaiser ṣe àtẹ̀jáde àfikún rẹ̀ sí àyọkà náà,[6] àríyànjiyàn rẹ̀ di debate ìta gbangba;[7] èyí tí Mail & Guardian tẹ̀ jáde tí wọ́n sì ṣe àfikún tiwọn [8] èyí tí ó sì mú kí Wits Centre for Ethics ṣètò àpéjọ kan lórí àyọkà náà, tí àwọn ènìyàn bíi Vice, McKaiser, Pierre de Vos, àti oníwòye Ward Jones àti David Benatar jẹ́ sọ̀rọ̀-sọ̀rọ̀ níbẹ̀.[9]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. 1.0 1.1 "Wits celebrates research excellence". Wits University (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022. Retrieved 2023-05-27. 
  2. 2.0 2.1 "Race and whiteness in a post-apartheid SA". Wits University. 15 December 2015. Retrieved 2023-05-27. 
  3. "Vice-Chancellor's Distinguished Research Award". Rhodes University (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-02-12. Retrieved 2023-05-27. 
  4. "Top Scholars in South Africa Honoured". ASSAf (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 21 October 2021. Retrieved 2023-05-27. 
  5. Vice, Samantha (2010-09-07). ""How Do I Live in This Strange Place?"" (in en). Journal of Social Philosophy 41 (3): 323–342. doi:10.1111/j.1467-9833.2010.01496.x. https://onlinelibrary.wiley.com/doi/10.1111/j.1467-9833.2010.01496.x. 
  6. McKaiser, Eusebius (2011-07-01). "Confronting whiteness". The Mail & Guardian (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-05-27. 
  7. Steward, Dave (2011-07-21). "Stop feeling guilty". Witness (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-05-27. 
  8. "Samantha Vice". The Mail & Guardian (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-05-27. 
  9. "White fear, white shame". The Mail & Guardian (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2011-10-18. Retrieved 2023-05-27.