Tomi Adeyemi (tí wọ́n bí ní August 1, 1993) jẹ́ ònkọ̀wé àti olùkọ́ àkọsílẹ̀ àtinúdá ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ilẹ̀ America. Ó gbajúmọ̀ fún ìwé ìtàn-àròsọ rẹ̀ Children of Blood and Bone, èyí tó jẹ́ àkọ́kọ́ nínú ìtàn Legacy of Orïsha trilogy, tí Henry Holt Books for Young Readers ṣá̀tẹ̀jáde rẹ̀.[1] Ìwé yìí gba àmì-ẹ̀yẹ ti Andre Norton ní ọdún 2018 fún Young Adult Science Fiction and Fantasy,[2] bákan náà ni ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti Waterstones Book Prize ọdún 2019, àti àmì-ẹ̀yẹ ti Hugo Lodestar Award for Best Young Adult Book, ní ọdún 2019.[3] Ní ọdún 2019, ìwé-ìròyìn Forbes kọ orúkọ rẹ̀ sínú àkójọ 30 Under 30. Ní ọdún 2020, ìwé-ìròyìn TIME náà to orúkọ rẹ̀ pọ̀ mọ́ 100 Most Influential People of 2020.[4]

Tomi Adeyemi
Adeyemi in 2022
Ọjọ́ ìbíOṣù Kẹjọ 1, 1993 (1993-08-01) (ọmọ ọdún 30)
Iṣẹ́Writer, Creative Director
Alma materHarvard University
Genre
Notable works
Notable awards
Website
tomiadeyemi.com

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Tomi Adeyemi ní August 1, 1993[5][6] ní United States sí àwọn òbí tó kó kúrò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Bàmí rẹ̀ jẹ́ dọ́kítà ní Nàìjíríà, ó sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i awakọ̀ kí ó tó ríṣẹ́ lókè òkun. Ìyá rẹ̀ sì jẹ́ afọlẹ̀. Ìlú Chicago ni Tomi dàgbà sí, wọn ò sí mu mọ àṣà Yorùbá; àwọn òbí rè sì pinnu láti má kọ́ òun àti àwọn àbúrò rẹ̀ ní èdè abínibí wọn. Àmọ́ ìgbà tó ṣẹ̀ dàgbà ló kọ́ èdè Yorùbá. Ó sì ṣàpèjúwe ọ̀kan lára àwọn ìwé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i lẹ́tà sí èdè rẹ̀[6]

Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtúnṣe

Legacy of Orïsha trilogy àtúnṣe

  • Children of Blood and Bone (March 6, 2018)
  • Children of Virtue and Vengeance (December 3, 2019)
  • Children of Anguish and Anarchy (June 25, 2024)

Companion books

  • Awaken the Magic (journal) (April 7, 2020)

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe