2015 Trafficking in Person Prohibition and Enforcement Act

2015 Trafficking in Person Prohibition and Enforcement Act jẹ́ àbádòfin ti wọ́n ṣe lọ́dún 2015 láti dẹ́kun ọ̀ràn kíkó ọmọ ènìyàn ròkè òkun lọ́nà àìtọ́ pẹ̀lú èròǹgbà láti rẹ́ wọn jẹ́ nínú òógùn-iṣẹ́ wọn.[1]

Ìpìlẹ̀ṣẹ̀

àtúnṣe

Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kò sí òfin kan gbòógì tí wọ́n fi ń dẹ́kun ọ̀ràn kíkó ọmọ ènìyàn ròkè òkun lọ́nà àìtọ́ pẹ̀lú èròǹgbà láti rẹ́ wọn jẹ́ nínú òógùn-iṣẹ́ wọn, àbádòfin, Criminal Code Act àti Penal Code Act ní wọ́n fi ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ yìí lápá ìlà-oòrùn àti Gúsù kí ó tó di ọdún 2003, tí wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àbádòfin ti tí wọ́n lè fi dènà kíkó ọmọ ènìyàn ròkè òkun lọ́nà àìtọ́ l'órílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lọ́dún 2005, wọ́n ṣe àtúnṣe sí àbádòfin yìí. Bí wọ́n ti ṣe òfin yìí tó lọ́dún 2003, ìwà kíkó ọmọ ènìyàn ròkè òkun lọ́nà àìtọ́ túnbọ̀ ń gbilẹ̀ sí i nítorí pé òfin náà kò kúnjú ìwọ̀n tó.

Nígbà tó di ọdún 2015, àwọn aṣòfin ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ṣe àgbékalẹ̀ àbádòfin lórí kíkó ọmọ ènìyàn ròkè òkun lọ́nà àìtọ́. Èyí jẹ́ òfin tó kúnjúwọ̀n ju àwọn tí àtẹ̀yìnwá lọ.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe