Orúkọ Àdúgbò ní Àkùngbá-Àkókó, Ìpínlẹ̀ Òndó, Nàìjíríà
Awon itumo awon oruko awon adugbo ilu Akungba-Akoko, ni Ipinle Ondo, Naijiria.
ÀKÙNGBÁ-ÀKÓKÓ
àtúnṣeÀKÚNMI : ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó mú ìpayà wa ṣẹ̀lẹ̀ ní àdúgbò yí tí ó mú kí ìpàdé pàjáwìrì wáyé nílé Ọba. Nígbà tí onísé yóò jíṣẹ́ fún ọba ohun tí ó kọ́ sọ ni pé àkún mi èyí tí ó túmò sí pé Àkùn ni àdápè Àkùngbá ṣùgbọ́n nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yíì mi gbogbo Àkùngbá ni wọ́n fi ń sọ pé Àkùn mi tí wọ́n sì wá sọ àdúgbò náà ní Àkùnmi láti ìgbà náà ní wọ́n ti ń jẹ olóyè tí a ń pè ní Alákúnmù. ÒKELÈ : Àwon jà-ǹ-dù-kú ènìyàn ni wọ́n teẹ àdúgbò yìí dó; Àwọn alọ-kólóhun-kígbe, olè ati ìgárá. Ibi ti wọ́n sì tẹ̀dó sí jẹ́ ibi tí ó ga sókè. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ lọ sí àdúgbò yí wọ́n á ní kó lọ òkè olè. Òkè olè ni wọ́n sọ di òkelè di òní-olónìí.
AKÙWÀ: Ìgbàgbó àwọn ènìyàn nipé àwọn tó wà ní àdúgbò yí jẹ́ ọ̀dàlẹ̀, a tán-ní-jẹ, Àgàbàgebè ènìyàn ni wọ́n. Èdè Àkùngbá ni Akuwa èyí tí ó túmọ̀ sí pé ìwà ìkà ni ó kún ọwọ́ wọn.
.
ÙBÈRÈ: Eni ti o kókó kó ilé ni ilú Àkùngbá Ùbèrè ni o ko o sí. Ibè ni àwon ènìyàn sì gbàgbó pe Àkùngbá ti se wá Ibè ni olóyè àkókó ti je. Idi niyi tí wón fi ń pè é ni Ubere-ibi ti nǹkan ti bèrè tàbí sè.
OKÙSÀ: Orúko eni tí o kókó kó ilé ni àdúgbò yí ni a fi n pèé. Òhun ni won n pè ni Okusa. Ìdílé re ni won ti n je oye olókùsà.
ÌBÀKÁ: Òbe ìrelé ti bàbá àgbà kan lo lati ségun àwon òtá ni àwon omo-omo rè ri ni òkè àjà ti won n pe ni ìká ni àkùngba. Lati igba yen ni won ti n pe àdúgbò náà ni ìbàká.
ÒDODÒ: Àgbàrá san gba èhìnkùlé àdúgbò yi kojá. Gbogbo Ilé ti o wa ní àdúgbò yi ni won si n pè ni òdodò eyí tí o túmò si ode (ile)-odo Òde-ode tasí Ododo.
ÒLÁLÈ: Oloye ti o koko je ni àdúgbò yi ni o létòó lati máa pín ilè fún àwon ènìyàn. Ilè ni Akungba n pè ni alè. Ìdí nìyí tí won fi n pea won to leto lati tai le tabi latí pín ìlè ni alale ti adugbo won sì n jé Olale. Ni adugbo bi ni won sit i n je oba titi ji oni-Oloni eyi wá wà ni ìbámu pèla òrò Yorùba tó so pé Oba ló nile.
AROKUNPANLE : Oke pupo wa ni adugbo yi to béè gee bi ènìyàn ko ba jeun kánú dáadáa yoo maa fidi wo kó tó wolé míràn ni. Itumo arokunpanle ni afìdímólè.
APOLE: Eni ti o koko te àdúgbò yi do maa n mo ògiri yi àwon ilé ibè po. Awon ilé tí a bá sì mo ògiri yip o ni a n pè ní apolé lati ìgbà náà ni wón ti ń pe àdúgbò yìí ní apolé.
ÀLÙJÙ: Ni àràárò ni baba arúgbò kan máa n fi ìlù ji awon ara adugbo yòókù. Nigba ti won bi baba yi léèrè èrèdí to fi n lu ilu o ni o n mu oun larada ni. Lati igba naa ni won ti n pe àdúgbò yìí ni àlùjù.
OKOGBO: Inú igbó ni bàbá àgbàlagbà ti o te àdúgbò yi do ń gbé kí àwon ènìyàn to de ba a nibe ìdí nìyí ti awon ènìyàn fi n pe àdúgbò náà ni okogbó.
ODÈÈGBÒ: Àwon to kókó te àdúgbò yí dó máa n da agbàdo sise sinu omi to n sàn to wà níbè. Àgbàdo yìí ni won n pè ni ègbo tì won sì ń pe odò yìí ní odo-egbo ti wón sì so àdúgbò yin i odèègbo.
ÒNÀKÈ: Ile pupa àti òpòlopò òkìtì-ògán wa ni adugbo yìí. Òpòlopo ona ni o sì já si ìlú yìí. Ona ti o wà ni ese òkè yi ni eni ti o te e dó ń gbé ìdí nìyí ti won fi n pe àdúgbò yí ní ònàkè.