Boitumelo Thulo (bíi ni ọjọ́ kejìdínlógbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 1990) tí orúkọ inagi rẹ jẹ Boity jẹ́ òṣèré, olórin, oníṣòwò àti mọ́dẹ́lì lórílẹ̀ èdè South Áfríkà.

Boity Thulo
Ọjọ́ìbíBoitumelo Thulo
Oṣù Kẹrin 28, 1990 (1990-04-28) (ọmọ ọdún 33)
Potchefstroom, North West
Ẹ̀kọ́Monash University
Iṣẹ́
Ìgbà iṣẹ́
  • Television personality:
    2011–present
  • Rapper:
    2017–present
WebsiteOfficial site
Musical career
Irú orinHip hop
InstrumentsVocals
Associated actsNasty C

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Thulo sì ìlú Potchefstroom, ìyá mama rẹ sì ló tọ dàgbà.[1] Òun nìkan ni ọmọ ìyá rẹ bí. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Monyash University níbi tí ó tí kọ́ ẹ̀kọ́ Psychology and Criminology, ṣùgbọ́n kò parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nítorí pé kò rí owó ilé ẹ̀kọ́ na ṣan.[2]

Iṣẹ́ àtúnṣe

Thulo bẹ̀rẹ̀ sì ní ṣe atọkun ètò pẹlu Crib Note ni ọdún 2011. Òun àti Stevie French jọ ṣe atọkun fun ètò The Media Career Guide Show lórí SABC.[3][4] Ó ti ṣe atọkun fun oríṣiríṣi ètò bíi SkyRoom Live, Ridiculousness Africa, Club 808, Zoned, Change Down, àti Big Brother Africa.[5] Ní ọdún 2012, ó kópa nínú eré Rock ville.[6] Ní ọdún 2014, ó farahàn gẹ́gẹ́ bíi Betty nínú eré Dear Betty.[7] Ó kọ ipa ránpé nínú eré Mrs Right Guy ni ọdún 2016.[8] Thulo kọ́kọ́ farahàn gẹ́gẹ́ bí olórin níbi ayẹyẹ Migos Culture Tour ni ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹwàá ọdún 2017[9]. Ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 2018, ó gbé orín tí ó pè àkọlé rẹ̀ ni Wuz Dat,[10] orin náà sì gba àmì ẹ̀yẹ Best Collabo láti ọ̀dọ̀ South African Hip-Hop Awards ni odun 2018[11]. Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kejì ọdún 2019, ó gbé orin rẹ kejì jáde ti àkòrí rẹ jẹ Bakae.[12]

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Boity Thulo - Age, House, Engaged, Biography...". Marathi TV. 
  2. "Boity Thulo: I also had to drop out of university". Channel24. 
  3. "GFC Launches Media Career Guide". Gauteng Film Commission. Archived from the original on 2019-02-03. Retrieved 2020-02-17. 
  4. "SABC 1's new Media TV Show". YoMZansi. 
  5. "Boity Thulo". TVSA. 
  6. "Boity Article". Press Reader. 
  7. "Boity Thulo". IMDb. 
  8. "Mrs Right Guy". IMDb. 
  9. "HUH? Is Boity Thulo A Rapper Now?". People Magazine. Archived from the original on 2019-05-11. Retrieved 2020-10-28. 
  10. "Listen: Boity drops new song 'Wuz Dat' ft. Nasty C". EastCoastRadio. 
  11. "Boity gets her first ever nod at the #SAHHA2018". Times LIVE. 
  12. "LISTEN: BOITY'S 2ND SINGLE 'BAKAE' IS A BANGER!". Daily Sun.