Cholera
Àìsàn Kọ́lẹ́rà tabí Àìsàn onígbáméjì ( /ˈkɒlərə/) jẹ́ àrùn tàbí àìsàn tí ó ma ń ràn tí ó lè kọlu ènìyàn nígbà tí kòkòrò àrùn baktéríà kan tí wọ́n ń pè ní Vibrio cholerae bá kọlu ìfun kékeré tí ó ń gba Oúnjẹ dúró lára ènìyàn.[1][2] Àìsàn yí lè tètè farahàn lára eni tí ó bá mú tàbí kí ìfarahàn rẹ̀ mọ níwọ̀nba, bákan náà sì ni ìfarahàn àìsàn náà lè mú ọwọ́ èle pẹ̀lú.[3] Àmọ́, bí àìsàn yí bá mọ́wọ́ èle, aláàrẹ̀ náà yóò ma yàgbẹ́ gbuuru fún ọjọ́ mélòó kan. Bákan náà ni onítọ̀hún tún lè má a bì tí gbogbo inú rẹ̀ yóò sì má a lọ́ ọ jáì jáí.[3] Bí èébì tàbí ìgbẹ́ aláàrẹ̀ náà báwá pọ̀ lápọ̀jù, èyí lè mú kí ipò tí omi wà nínú àgọ́ ara rẹ̀ ó dínkù kọjá ààlà, okun inú rẹ̀ kò sì ní gbé kánkán mọ́ láàrín wákàtí péréte tí ó fi ń bì tàbí ṣègbọ̀nsẹ̀. Ìgbọ̀nsẹ̀ gbuuru yíyà yí lè mú kí ojú aláàrẹ́ náà ó jìn wọnú láìpẹ́. Òtútù àbaadì lè ma mú u pẹ̀lú, iṣan ara rẹ̀ yóò ma lẹ, bákan náà ni àwọ̀ ara rẹ̀ yóò ma hunjọ pẹ̀lú. [4] Àìtó omi ara aláàrẹ̀ mọ́ yìí lè mú kí àwọ̀ rẹ̀ yí padà sí àwọ̀ búlúù.[5] Lọ́pọ̀ ìgbà tí àìsàn yí bá kọlu ènìyàn, ó ma ń to wákàtí méjì sí ọjọ́ márùn ún kí àpẹẹrẹ rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ sí í farahàn lára ènìyàn. [6]
Oríṣiríṣi Kòkòrò àìfojúrí tí wọ́n n pé ní Vibrio cholerae ni ó lè fa àìsàn kọ́lẹ́rà tí wọ̀n sì lágbára ju ara wọn lọ. [7] Àmọ́, pàtó ohun tí ó ǹ fa àìsàn onígbaméjì ni kòkòrò àìfojúrí tí ó ń tinú omi tí kò mọ́ tábí oúnjẹ tí a kò pèsè lọ́nà tí ó mọ́ gaara, tàbí oúnjẹ tí ìgbẹ́ tí kòkòrò bakitéríà Vibrio cholerae ti dàpọ̀ mọ́ .[7] Bákan náà ni àwọn ẹran-omi oníkarahun tì a kò bá sè jiná dáa dáa náà lè fa àìsàn onígbàméjì fún ènìyàn. [8] Inú imí ènìyàn nìkan ni kòkòrò tí ò n fa àìsàn onígbáméjì sábà ma ń wà.[7] Àwọn ohun mìíràn tí ó tún lè fa ìbùrẹ́kẹ́ àìsàn yí ni àìní ìmọ́tótó tí ó péye, mímu omi tí kò mọ́ kangá, àti òṣì tàbí ìṣẹ́ tí ó lè múni láti má nìí àǹfàní sí àwon ohun tí a ti kà sókè lọ́nà tò péye.[7] Wọ́n lè ṣàyẹ̀wò àìsàn onígbáméjì lára ènìyàn nígbà tí wọ́n bá ṣe àyẹ̀wò sí ìgbẹ́ tí aláàárẹ̀ náà bá ń yà, [7] tàbí kì wọ̀n lo ìlànà àyẹ̀wo dipstick test bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìlànà yí kìí fi bẹ́ẹ̀ mú èsì pípé jáde.[9]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Finkelstein, Richard A. (1996). "Cholera, Vibrio cholerae O1 and O139, and Other Pathogenic Vibrios". In Baron, Samuel. Medical Microbiology (4th ed.). University of Texas Medical Branch at Galveston. ISBN 978-0-9631172-1-2. PMID 21413330. Àdàkọ:NCBIBook2.
- ↑ "Cholera – Vibrio cholerae infection Information for Public Health & Medical Professionals". Centers for Disease Control and Prevention. January 6, 2015. Archived from the original on 20 March 2015. Retrieved 17 March 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ 3.0 3.1 "Cholera – Vibrio cholerae infection Information for Public Health & Medical Professionals". Centers for Disease Control and Prevention. January 6, 2015. Archived from the original on 20 March 2015. Retrieved 17 March 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Cholera". Lancet 379 (9835): 2466–2476. June 2012. doi:10.1016/s0140-6736(12)60436-x. PMC 3761070. PMID 22748592. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3761070.
- ↑ Bailey, Diane (2011). Cholera (1st ed.). New York: Rosen Pub.. p. 7. ISBN 978-1-4358-9437-2. https://books.google.com/books?id=7rvLPx33GPgC&pg=PA7.
- ↑ "Cholera – Vibrio cholerae infection Information for Public Health & Medical Professionals". Centers for Disease Control and Prevention. January 6, 2015. Archived from the original on 20 March 2015. Retrieved 17 March 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ 7.0 7.1 7.2 7.3 7.4 "Cholera vaccines: WHO position paper". Weekly Epidemiological Record 85 (13): 117–28. March 2010. PMID 20349546. https://www.who.int/wer/2010/wer8513.pdf.
- ↑ "Sources of Infection & Risk Factors". Centers for Disease Control and Prevention. November 7, 2014. Archived from the original on 12 March 2015. Retrieved 17 March 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Diagnosis and Detection". Centers for Disease Control and Prevention. February 10, 2015. Archived from the original on 15 March 2015. Retrieved 17 March 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)