Legit.ng (èyí tí wọ́n ń pè ní Naij.com tẹ́lẹ̀), tí a sì tún mọ̀ sì Legit News jẹ́ ilé iṣẹ́ agbéròhìnjáde ti orílè èdè Nàìjíríà èyí tí Naij.com Media Limited ń ṣe agbátẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì wà lára Legit (ex-GMEM).[1][2]

A kà á gẹ́gẹ́ bí àkọ́kọ́ nínú àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn àti ìdánilárayá, bákan náà, a tún kà á gẹ́gẹ́ bí ayélujára keje ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà èyí tí àwọn ènìyàn bẹ̀wò jùlọ láti ọwọ́ Alexa ní ọdún 2018.[3][4] Legit.ng is the biggest publisher on Facebook by the audience in 'Media' category.[5]

Wọ́n da sílẹ̀ ni ọdún 2012, olúlú Legit.ng wà ní Ikeja, Èkó, Nigeria, wọ́n sì dà ẹ̀ka kan sílẹ̀ fún iṣẹ́ olóòtú ni olú-ìlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Abuja, ní oṣù karùn-ún, 2015. Legit.ng jẹ́ alábàṣiṣẹ́pọ̀ Legit (ex-GMEM), ilé iṣẹ́ àtẹ̀ròyìn tí ó wà káàkiri àgbáyé, èyí tí ó ń bá ilé iṣẹ́ Tuko.co.ke ní orílẹ̀ èdè Kenya, Yen.com.gh ní orílẹ̀ èdè Ghana , Briefly News ní orílẹ̀ èdè South Africa àti Sports Brief ṣiṣẹ́ pọ̀ (káàkiri àgbáyé).[6]

Ní oṣù karùn-ún, ọdún 2014, Legit.ng gbé ohun èlò fún ẹ̀rọ ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀ jáde.[7]. Kò pé tí ohun èlò náà fi di àkọ́kọ́ ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí àwọn ilé iṣẹ́ Google Play Market si gbe jáde. Ohun èlò náà rí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta ìfi sórí ẹ̀rọ ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀ láàárín oṣù mẹ́wàá.[8]. Iye ìfi sórí èrò ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀ ti ju mílíọ̀nù márùn-ún lọ.[citation needed]

Ní oṣù kẹfà, ọdún 2015, Legit.ng para pọ̀ mọ́ àwọn tí ń ṣe ẹ̀rọ aṣàwákiri ẹ̀yà àìrídìmú Opera Software àti àwọn òmìràn tẹlifóònù MTN Group láti ṣètò "lílọ ayélujára lọ́fẹ̀ fún mílíọ̀nù ọjọ́ sí Nàìjíríà".[9]

Ní oṣù keje, ọdún 2015, àwọn ọlọ́ṣà ojúlé wẹ́ẹ̀bù gba wẹ́ẹ̀bù wọn.[10]

Ní oṣù kẹjọ, ọdún 2015, wọ́n bẹ̀rẹ̀ abala ìròyìn ní èdè Haúsá Hausa [11].[12]

Ní oṣù kejì, ọdún 2016, Legit.ng wà lára àwọn àkọ́kọ́ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ṣe àtẹ́jáde átíkù lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lórí Facebook.[13][14]. Ní ọdún 2017, Facebook ṣe ìwádìí lórí àtẹ́jáde yìí pẹ̀lú Legit.ng, wọ́n sì gbé ìròyìn náà jáde lórí Facebook Audience Network.[15]

Ní oṣù kẹta, ọdún 2017, Legit.ng bẹ̀rẹ̀ ètò iṣẹ́ ìròhìn àgbègbè láti ṣe ìsopọ̀ gbogbo àwọn oníròhìn tí ń ṣe aṣojú àwọn Ìpínlẹ̀ mẹ́rindínlógójì àti olú ìlú Nàìjíríà.[16]. Ní àkókò kan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ètò àti ṣe àwárí àwọn ẹni tó ti sọnù,[17] èyí tí ó ran àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́wọ́, ní ọjọ́ iwájú, láti ṣe àwárí àwọn ẹbí wọn tí ó sọnù kí wọ́n si mú wọn padà wá sílé.[18]

Ní oṣù kẹjọ, ọdún 2018, Naij.com yí orúkọ rẹ̀ sí Legit.ng.[19]

Ní oṣù kejì, ọdún 2019, Legit.ng wà lára àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ẹ̀tadínláàádọ́rùn èyí tí wọ́n yàn káàkiri orílẹ̀ èdè méjìdínlọ́gbọ̀n láti gba owó Google News Initiative.[20]

Ní oṣù kẹjọ, ọdún 2019, Legit.ng gba àmì ẹ̀yẹ fún Migration Reporting láti ọwọ́ UNESCO fún àwọn ìròyìn ìṣílọ tí wọ́n gbé jáde.[21]

Ní oṣù keje, ọdún 2019, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn Suncity ṣe ìdámọ̀ fún Legit.ng gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Aṣíwájú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fún Ìjọba tiwantiwan àti Ìdàgbàsókè ti ọdún 2019. Ìdánimọ̀ yìí wáyé ní ìpàdé àmì ẹ̀yẹ ti Suncity fún àwọn Aṣíwájú ti Ìjọba tiwantiwan àti Ìdàgbàsókè tí wọn ṣe ni Abuja.[22]

Abala ìròyìn mìíràn, àǹfààní ènìyàn, ni wọ́n fi lọ́lẹ̀ ni oṣù kejì, ọdún 2020 láti lè sọ ìtàn púpọ̀ sí nípa àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà èyí tó tayọ nílé àti lókè òkun. Ní oṣù kẹta, ọdún 2020, Legit.ng di ọmọ ẹgbẹ́ United Nations SDG Media Compact [23]

Ní oṣù kẹwàá, ọdún 2020, Legit.ng gbé ìdíje Big Naija Independence kalẹ̀. Ìdíje náà ni wọ́n fi ṣe àjayọ̀ àjọ̀dún pé òmìnira Nàìjíríà ti pé ọgọ́ta ọdún. Ó gbìyànjú láti ṣàwárí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ èyí tí ó ní ẹ̀bùn àti ìtara fún ìròyìn àti ìwé kíkọ, ó sì tún fún àwọn ọ̀dọ́ láàyè láti sọ ìtàn tiwọn èyí tí ó jẹ́ mo òmìnira orílẹ̀ èdè.[24][25]

Ní oṣù kejì, ọdún 2021, Legit.ng bẹ̀rẹ̀ ètò Patreon charity. Láti ìgbà náà, ilé iṣẹ́ Oníròyìn náà ti rí owó gbà fún ìpolongo irànlọ́wọ́ mẹ́fà.[26] Ní oṣù keje, ọdún 2021, Legit.ng ni ó gba owó ìranlọ́wọ́ ti Google News Initiative fún ṣíṣe ètò ìgbàníyànjú (ReCo) èyí tó ṣàtúnṣe ìrírí àwọn olùmúlò ayélujára wọn.[27]

Ní oṣù keje, ọdún 2021, a dá orúkọ Legit.ng fún "Ayélujára ti ìròyìn èyí tó da jù ní Áfíríkà" ní Ìpàdé Àmì Ẹ̀yẹ ti WAN-IFRA Africa Digital Media ní ọdún 2021.[28] Ní oṣù kan náà, Facebook ṣe àfihàn Legit.ng nínú iṣẹ́ ìwádìí kan gẹ́gẹ́ bí ilé iṣẹ́ fún ìròyìn àti ìdánilárayá ti ilẹ̀ Áfíríkà. [28]

Ní oṣù kẹfà, ọdún 2022, Legit.ng para pọ̀ mọ́ NGO tí ó kó ga ja jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà - WARIF, láti ṣe ìrunisókè àti owó gbígbà lórí ìpolongo ìwà ipá ti abo (GBV) àkọ́kọ́.[29]

Ní oṣù kẹwàá, ọdún 2022, Legit.ng di ilé iṣẹ́ àtẹ́ròyìn jáde àkọ́kọ́ lórí Facebook láti ọwọ́ NewsWhip Ranking.[30]

Ni oṣù kọkànlá, ọdún 2022, wọ́n gbé ìpolongo fún ìmọ̀ ilé iṣẹ́ Oníròyìn ti Legit.ng kalẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni gbajúmọ̀ láwùjọ Nàìjíríà bíi, Aproko Doctor, Teminikan, Tochi Oke, Tega Dominic, Chizzy Official, Kayvee, àti àwọn mìíràn.[31]

Ní oṣù kẹrin, ọdún 2023, ayélujára ti Legit.ng ni ó gbé gba orókè ní abala ti ‘Best Trust Initiative’ ni Ìpàdé Àmì Ẹ̀yẹ Digital Media Áfíríkà ní ọdún 2023 fún ìpolongo lórí níní ìmọ̀ ìròyìn tí wọ́n gbé kalẹ̀.[32]

Ní oṣù kẹfà, ọdún 2023, wọ́n ṣe ìdánimọ̀ fún Legit.ng gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn tí ń gbé ìròyìn jáde lórí afẹ́fẹ́ tó gbajúmọ̀ jùlọ nípasẹ̀ bí ìròyìn ọ̀sẹ̀ kan ṣe tán kalẹ̀ tó ní Nàìjíríà, nínú Digital News Report ti ọdún 2023 èyí tí Reuters Institute of Journalism tẹ̀ jáde. [33][34]

Ní oṣù kan náà, Legit.ng di ọmọ ẹgbẹ́ International News Media Association (INMA) bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n di ọmọ ẹgbẹ́ New York Times.

Ní oṣù keje, ọdún 2023, wọ́n ṣe ìdánimọ̀ fún Legit.ng gẹ́gẹ́ bí Ètò tó ṣe gbára lé jùlọ ni gbogbo àgbáyé ni Ìpàdé Àmì Ẹ̀yẹ WAN-IFRA Digital Media Awards Worldwide fún ìpolongo ìmọ̀ ìròyìn (Media Literacy Campaign).[35]

Ní oṣù kẹjọ, ọdún 2023, Legit.ng dára pọ̀ mọ́ LEAP Áfríkà láti mú kí ìmọ̀ nípa iṣẹ́ ìròyìn tẹ̀síwájú si gẹ́gẹ́ bí ohun èlò fún ìyípadà ni àwùjọ, fún àṣekágbá ètò ti Youth Day of Service (YDOS) fún ọdún 2023.[36][37]

Ní oṣù kẹwàá, ọdún 2023, Legit.ng gba oyè àmì ẹ̀yẹ Best Online News Medium ti ọdún náà ni abala ìròyìn ní Nigeria Media Nite-out Award ní ọdún 2023. Lára àmì ẹ̀yẹ náà, Ọ̀gá abala Ọ̀rọ̀ tí ń lọ nílùú àti òṣèlú ni Legit.ng, Nurudeen Lawal náà gba àmì ẹ̀yẹ fún ‘Political Desk Head of the Year’.[38]

Ní oṣù kọ̀kánlá, ọdún 2023, Legit.ng wà nínú ìròyìn tó wá láti ọwọ́ Squirrel Media Technologies fún Q3, ọdún 2023, níbi tí wọ́n ti dárúkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ayélujára tí àwọn ènìyàn bẹ̀wò jùlọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[39]

Gbajúgbajà

àtúnṣe

Ní oṣù keje, ọdún 2015, Legit.ng ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́tàlá òǹkàwé ní òṣùṣù, wọ́n sì ti kà á gẹ́gẹ́ bí ayélujára keje èyí tí àwọn ènìyàn bẹ̀wò jùlọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti lára àwọn àtẹ̀ròyìn jáde àkọ́kọ́ láti ọwọ́ Alexa.[4] Currently, the website's Facebook page has over 7.5 million members.[40] Legit.ng is the biggest publisher on Facebook by the audience in ‘Media’ category.[5]

Ní oṣù kẹwàá, ọdún 2018, iye àwọn tí wo ìkànnì Legit [41] lórí YouTube, àwọn alábáápín ìkànnì náà ti lé ní ẹgbẹ̀rún ọgọ́rùn-ún, a sì fi òǹtẹ̀ lu ìkànnì náà láti ọwọ́ nẹ́tíwọ́kì. Wọ́n ti kà á mọ́ àwọn ìkànnì àádọ́ta àkọ́kọ́ lórí YouTube ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ọwọ́ vidooly.[42]

Ìtọ́kási

àtúnṣe
  1. "[Latest Top 21 Blogs In Nigeria 2018 Popular Nigeria Blogs"] (in en-US). 2017-08-29. https://www.oasdom.com/top-21-popular-blogs-nigeria-2017/. 
  2. Okuku, Mitchelle (2018-10-24). "NAIJ.com upgrades to Legit.ng" (in en-US). Legit.ng. Archived from the original on 2018-11-05. https://web.archive.org/web/20181105012558/https://www.legit.ng/1198754-naij-upgrades-legitng.html. 
  3. "Top Sites in Nigeria". Alexa Internet. Archived from the original on 2020-04-25. Retrieved 2018-11-20.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. 4.0 4.1 "Legit.ng Traffic, Demographics and Competitors". Alexa Internet. Archived from the original on 2018-11-20. Retrieved 2018-11-20.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. 5.0 5.1 "Facebook stats of popular Media pages in Nigeria". Socialbakers.com. Retrieved 2018-11-09. 
  6. "Почему украинские медийщики решили, что проще зарабатывать деньги в Африке и на Филиппинах → Roem.ru" (in ru-RU). 2017-07-19. https://roem.ru/19-07-2017/255239/ukrane-africa/. 
  7. "NAIJ Legit.ng: Nigeria News Breaking & Trending - Apps on Google Play". play.google.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-11-13. 
  8. Ukwu, Jerrywright (2015-03-30). "History! Naij.com Is The First Nigerian App To Reach 500,000 Downloads" (in en-US). Legit.ng - Nigeria news.. https://www.legit.ng/400385-history-naij-com-is-the-first-nigerian-app-to-reach-500000-downloads.html#400385. 
  9. Anozim (2015-06-26). "MTN, Opera Software Partner to Improve Internet Access | The Guardian Nigeria". Ngrguardiannews.com. Retrieved 2015-07-28. 
  10. "Internet Vulnerability: Cyber attacks on Naij.com To Boko Haram Cyber Terrorism | WAKAPOST". Wakapost. 2015-07-16. Archived from the original on 2015-07-25. Retrieved 2015-07-24. 
  11. "Hausa Daily News | Labaran Hausa - LEGIT.NG". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Hausa). Retrieved 2018-11-14. 
  12. "Naij.com Launches Hausa News Portal - Nigerian Bulletin - Trending News". Nigerian Bulletin - Trending News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-11-14. 
  13. "Facebook Extends Instant Articles to All Android Users – Adweek". www.adweek.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 16 December 2015. Retrieved 2018-11-19. 
  14. "Instant Articles Launches to Everyone on Android, with More Than 350 Publications Globally | Facebook Media" (in en). Archived from the original on 2018-11-21. https://web.archive.org/web/20181121184608/https://media.fb.com/2015/12/16/instant-articles-launches-to-android/. 
  15. "Naij.com success story". Facebook. Retrieved 2017-11-15. 
  16. Ikeke, Nkem (2017-03-09). "NAIJ.com is looking for local reporters to take part in brand new Local Journalism Project" (in en-US). Legit.ng - Nigeria news.. https://www.legit.ng/1092806-naij-local-reporters-part-brand-local-journalism-project.html#1092806. 
  17. Ejiofor, Clement (2017-07-23). "Raise alarm about missing person or case of kidnapping in Nigeria via Legit.ng" (in en-US). Legit.ng - Nigeria news.. https://www.legit.ng/1094328-your-friend-loved-missing-kidnapped-send-alert-millions-naijcom.html. 
  18. Odejobi, Micheal (2017-09-01). "Nigerian boy goes missing on his way to church (photo)" (in en-US). Legit.ng - Nigeria news.. https://www.legit.ng/1122732-nigerian-boy-missing-church-anambra-state-photo.html#1122732. 
  19. "The biggest Nigeria publisher NAIJ.com upgrades to Legit.ng" (in en-GB). Tribune. 2018-10-18. Archived from the original on 2018-11-10. https://web.archive.org/web/20181110000050/https://www.tribuneonlineng.com/169489/. 
  20. "Case study - Legit" (PDF). Google News Initiative. Retrieved 15 March 2021. 
  21. Legit tv correspondent wins big at UNESCO national contest | Legit tv correspondent, Damilare Okunola, was a top three finalist at the recent national contest for investigative journalism organized by UNESCO. He... | By Legit.ng | Facebook (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì), retrieved 2023-12-18 
  22. "SUNCITY NEWS to honour eminent Nigerians for contribution to nation building". Premium Times. 9 July 2019. 
  23. Lawal, Nurudeen (2021-03-01). "Legit.ng becomes member of United Nation's SDG Media Compact". Legit.ng - Nigeria news (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-18. 
  24. Ogar, Jude (5 November 2020). "Legit Big Naija Independence Contest 2020 (up to 200k in prizes)". Opportunity Desk. 
  25. "Big Naija Independence: Prominent Students Contest". www.specials.legit.ng. Retrieved 2020-10-21. 
  26. "Legit.ng". Patreon. Retrieved 2023-12-18. 
  27. Lawal, Nurudeen (2021-07-29). "Legit.ng wins Google News Initiative grant". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-18. 
  28. 28.0 28.1 MENAFN. "2021 Africa Digital Media Awards: Nigerian Legit.ng emerges as best news website". menafn.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-18. 
  29. "WARIF and Legit.ng Charity on a mission to support 100 Survivors – Prevent Rape and Sexual Violence" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 15 June 2022. Retrieved 2023-12-18. 
  30. Nicholson, Benedict (2022-11-10). "Legit surges to the top of our Facebook publisher rankings in October 2022". Newswhip (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-18. 
  31. "Bust Fake News with Legit.ng". specials.legit.ng. Retrieved 2023-12-18. 
  32. Oyenuga, Kikelomo (2023-06-27). "Legit.ng recognised as "Best Trust Initiative" award winner by WAN-IFRA 2023 digital media awards". The Industry (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2023-12-18. Retrieved 2023-12-18. 
  33. Spur, Brand (2023-06-27). "Legit.ng Emerged Top Weekly Online Reach Survey" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-18. 
  34. "Digital News Report 2023". Reuters Institute for the Study of Journalism (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-18. 
  35. Herger, Christin (2023-06-28). "WAN-IFRA honours the world's top digital media projects". WAN-IFRA (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-18. 
  36. Olugbade, Tolulope (2023-09-24). "Fake news: Youths urged to subject information sources to proper scrutiny". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-18. 
  37. "LEAP Africa – Raising Leaders, Transforming Africa" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2023-11-16. Retrieved 2023-12-18. 
  38. Tomosori, Oluwaseyi (2023-10-30). ""We won't stop": Legit.ng clinches awards at Nigeria Media Nite-Out". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-18. 
  39. squirrelPR. "Nigeria's Top 10 Online News Platforms Generate 250 Million Impressions in Q3". www.squirrelpr.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-12-18. 
  40. "Naij.com". Facebook. Retrieved 2015-07-24. 
  41. "Legit TV". YouTube (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-11-20. 
  42. "Top 50 YouTube channels in Nigeria | Most Subscribed Youtube Channel - Vidooly" Check |url= value (help). vidooly. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-11-20.