Muṣin ni ó jẹ́ ìlú olókìkí ati Agbègbè Ìjọba ìbílẹ̀ kan ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[1] Musin ni ó wà ní apá 10 km àríwá Ìpínlẹ̀ Èkó, àti gẹ̀rẹ́-gẹ̀rẹ́ àríwá Ìpínlẹ̀ Èkó ojú-ọ̀nà tí ó lọ sí Ikeja, Muṣin sì wà lara àwọn agbègbè tí èrò pọ̀ sí jùlọ ní Ìpínlẹ̀ Èkó pẹ̀lú àwọn ilé olówó pọ́ọ́kú, bákan náà ni ètò ìmọ́-tótó agbègbè náà kò fi bẹ́ẹ̀ ja gaara. Àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ olùgbé ibẹ̀ ní àsìkò ètò ìkànìyàn ti ọdún 2006 ṣe fi múlẹ̀ jẹ́ 633,009.

Location of Mushin within Lagos Metropolitan Area
Ọjà ni Mushin
Mushin Post Office
Post Office Ti Mushin Àkọ́kọ́

Apèjúwe Muṣin àti àwọn ohun amáyé-derùn tó wà níbẹ̀

àtúnṣe

Lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gbòmìnira ní ọdún 1960 kúrò lọ́wọ́ ìjọba àmúnisìn Britain, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ni wọ́n fi àwọn ìlú ìgbèríko wọn sílẹ̀ láti wá ma gbé tàbí ṣiṣẹ́ ní àwọn ìlú ọláọ́làjú bíi Muṣin ní àsìkò náà, èyí sì mú kí apáọ̀jù èrò ó mú kí ìdọ̀tí ó pọ̀ láàrín ìlú, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ilé Ìgbé kò fi bẹ́ẹ̀ tó àwọn olùgbé àwọn agbègbè yí mọ́. Ẹ̀wẹ̀, bí ọ̀làjú àti ìmọ̀ ṣe ń gorí ara wọn náà ni àwọn ilé-iṣẹ́ náà ń pọ̀ si, pàá pàá jùlọ ní Ìpínlẹ̀ Èkó àti agbègbè Muṣin, àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó ń pèsè nkan bíi: aṣọ híhun, bàtà ṣíṣe, ìpèsè kẹ̀kẹ́ ológeere àti ọ̀kadà, ba kan náà ni ilé-iṣẹ́ tí ó pèsè mílíkì oníyẹ̀fun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ wà ní Muṣin, èyí mú kí àwọn ènìyàn ó pọ̀ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní agbègbè náà. Láfikún, àwọn ilé-ẹ̀kọ́ jànkàn-jànkàn ati ilé ìwòsàn tí ó fi mọ́ ilé-ẹ̀kọ́ oríṣiríṣi ni wọ́n wà ní Muṣin. Púpọ̀ nínú àwọn olùgbé Mú sì ń ni wọ́n jẹ́ ọmọ ati elédè Yorùbá gẹ́gẹ́ bí èdè tí wọ́n ń sọ jùlọ. Àwọn ọ̀nà tí ó ń bọ̀ láti Èkó, Shomolu ati Ikeja ni wọ́n wọ inú Muṣin. [2]

Àlà Muṣin

àtúnṣe

Muṣin wà ní apá ará wà ní ojú títì márosẹ̀ Oshodi/Apapa tí ó lọ sí orí afárá Oshodi, tí ó fi de Agege ní apá gúsù. Muṣin pààlà pẹ̀lú ìjọba ìbílẹ̀ Surulere ati Agége.


Àwọn itọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "Mushin". NigeriaCongress.org. Retrieved 2007-04-08. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  2. "Mushin | Nigeria". Retrieved 2015-05-22. 

Ìjásóde

àtúnṣe