Raila Odinga: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
New page: Raila Odinga A bí i ní Maseno, Kizumu District, Nyanza Prorince ní January 1946. Ó rí èkó-òfé ní 1965 èyí tí ó fi lo kàwé ní Technical University of...
(Kò ní yàtọ̀)

Àtúnyẹ̀wò ní 12:20, 8 Oṣù Kejì 2008

Raila Odinga


A bí i ní Maseno, Kizumu District, Nyanza Prorince ní January 1946. Ó rí èkó-òfé ní 1965 èyí tí ó fi lo kàwé ní Technical University of Magdeburg (tí ó jé ara Otto von Gueriche University of Magdeburg) ní East Germany. Ní odún 1970, ó jáde ó si gba oyè lórí Mechanical Engineening. Nígbà tí ó dé Kenya, ó se olùkó ní University of Naírobì kí ó tó lo máa se òsèlú. Ní odún 1975, wón so ó di Deputy Director of the Kenya Burean of Standards isé tí ó se títí tí wón fi so ó sí ìhámó ní 1982. Wón fi i sílè ní osù kefà 1988, wón tún tún un mú ní osù kéjo. Wón fi sílè ní ojó kejìlá osù kéfà 1989 wón tún mú un padà ní ojó karùn-ún osù kéje odún 1990 pèlú Keneth Matiba àti Charles Rubia. Bí wó se dá a sílè ní ojó kokàndínlógún osù kefà odún 1991, nse ni ó sá gba Norway lo Ó ní wón fé pa òun. Ó padà sí Kenya ní 1992, ó dara pò mó egbé òsèlú FORD eyí tí baba re, Jaramongi Oginga Odinga n darí. Nígbà tí bàbá rè kú ní osù kìíní odún 1994 tí Michacl Waimalwa kijana di olórí egbé náà Raila ta kò ó sùgbón ó fidí remi èyí ló mu un (Raila) kúrò nínú egbé náà tí ó sì lo dara pò mó National Development Party (NDP).