Ìlú Òbè-nlá: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
New page: ==ÌTÀN ÌSÈDÁLÈ ÌLÚ ÒBÈ-NLÁ== Olúbákin ni orúko eni àkókó tí ó je Olúbo ní òde Ugbo. Ìtàn so pé àtomodómo Sèpèl...
(Kò ní yàtọ̀)

Àtúnyẹ̀wò ní 12:47, 15 Oṣù Kejì 2008

ÌTÀN ÌSÈDÁLÈ ÌLÚ ÒBÈ-NLÁ

Olúbákin ni orúko eni àkókó tí ó je Olúbo ní òde Ugbo. Ìtàn so pé àtomodómo Sèpèlúwà tí ó jé Awùjalè ìkejìdínlógún ti ilè Ìjèbú ni Olúbákin jé. Olúbákin àti àbúrò rè tí wón jo jé omo bàbá ni wón jo dunpò Awùjalè ìketàdínlógójì ti ilè Ìjèbú léyìn tí Oba Morógbèsò, Awùjalè ìkejìlélogojì. Òródùdùjoyè ni orùko àbúrò olúbákin tí wón jo du oyè náà. Yorùbá bò, wón ní, “Ohun gbogbo lówó orí, orí la fi n mú eran láwo” Òródùdùjoyè tí ó jé àbúro ni àwon afobaje yàn dípò Olúbákin tí ó jé ègbón gégé bí i Àwùjalè tuntun ti ilè Ìjèbú. Bí àbúrò Olúbákin se gun orí oyè kò sàìdá hóùhóù àti yànponyánrin sílè láàárin àwon méjèèjì.

Olúbákin gbé egbé omo ogun olòtè dìde sí àbúrò rè pèlú èrò àti gba ìjoba padà sówó araarè gégé bí eni ti oyè náà tó sí. Àsèyìnwá-àsèyìnbò, ìsebo-ìsoògùn, bí a ti lá á rì í láyé. Àwon omo ogun olote tí Olúbákin gbé díde kò lè ségun ti àbúrò rè Òródùdùjoyè. Látàrí èyí, ó pinnu láti fi ìlú sílè fún àbúrò rè. Kàkà kí kìnnìún se akápò ekùn kálukú á máa dóde se.

Gbogbo ìsapá àti akitiyan Òródùdùjoyè láti tu ègbón rè lójú já sí pàbó léyìn tí ó rò pé ó sàn kí wón yanjú òràn náà ní ìtùnbí-ìnùbí. Ibùdó àkókó tí Olùbákin tèdó sí léyìn tí ó kúrò ní Ìjèbú ni wón n pè ní Èhì títí di òní yìí. Léyìn tí ó kúrò níbè, ó forí lé ìha ìlà-oòrùn Ugbò, ó sì tèdó sí ibi tí wón n pè ní ode-Sèpèlúwà léyìn ìgbà tí wón tèdó tán. Ògangan ibí yìí ni òkan lára àwon omo Olúbákin ti a mò sì Òrótó ti papòdà. Ó seni láàánú pé Òròtò kò bí omo kankan sáyé kí ó tó re ibi àgbà n rè. Nítorí náà bàbá rè pinnu láti yí orúko òde-sèpèlúwa padà sí ti omo rè ti ó kú síbè. Láti ìgbà náà wà ni wón ti n pe ibè ní Òde-Òrótò títí o fi di òní yìí.

Olúmòdàn tí òun náà jé omo Olúbákín ni ó salábápàdé omobìnrin kan létí òkun níbi tí wón ti lo máa n se ohun kan tí wón n pè ní ‘ìpé’ lóko. Ìsèlè yìí gan-an ni ó padà wá yorí sí bí Olúbákin àti Òrónmàkin se gbà láti jo máa se ìjoba pò ní Ugbo níbi tí Oranmàkin ti wà sáájú kí Olúbákin tó dé sí àgbègbè náà, gégé bí Olájà Ugbò. Ó jé ìyàlénu fún Olúmòdàn omo Olúbákin pé àwon kan tún wà ní tosí, tí àwon tí ó wà ní Òde-Òrótò kò mò nípa won télè. Ojàludé ni orúko omobìnrin ti Olúmòdàn bá pàdé n jé. Omo Olúgbò tí a pè ní Òrónmakin léèkan ni. Àwon méjèèjì bèrè sí yan ara àwon lórèé sùgbón kò sí omo láti inú ìbásepò won jálè gbogbo odún tí àwon méjèèjì fi wà lórí erùpè. Ìbásepò Olúmodàn àti Ojàludé ni ó mú àjosepo tí ó wà láàárín Olúbákín àti Òrónmakin wáyé. Wón kó ijoba pò, nitori pé kò fi béè sí èrò púpò ní àgbègbè náà nígbà yen. Nígbà tí Olúbákin je Olubo ní Òde Ugbò, àwon omo rè kan àti lára àwon tí ó tèlé e wá láti Èhin kò kúrò ní Òde-Òrótò. Léyìn ikú Olúbákin, Olúmòdàn omo rè ni ó je Olúbo tèlé e. Òpòlopò odún kojá léyìn náà, òkan lára àwon àtomodómo Olúbákin tí wón wà ní Òrótò pinnu láti wásé eja pípa síwájú ìhà-ila-oòrùn òde-òrótò ìgbàyen, látàrí àkíyèsí rè pé àwon eye nlá-nlá máa ti apá ìhà ibè yen wá. Á ní láti jé pé omi nlá kan wà lápá ibè ti eja pò sí, nítorí àwon eye máa n dode eja ní irú àgbègbè béè. Akíkanjú okùnrin ni kúlájolú jé. Ó kó àwon kan móra wón sì bè rè ìrìn-àjò si apá ìlà-oòrún òde-òrótò. Nígbèyìn wón sàwárí omi náà tí ó kún fún ògìdigbo eja nlánlá. ‘Agbárà’ tàbí ‘orà’ nlá ti àwon eja wo sí yìí ni wón n pè ni “ebe” láàárín àwon Ìlàje ìgbà yen. Kúlájolú tèdó sí ibi tuntun yìí ti wón fi ìrísí so lórúko. Láti inú ‘ebè-nlá’ ni Òbè-nlá ti súyo léyìn òpòlopò odún.

Bí ibùdó àwon àtomodómo Olúbákin ti n gbòrègèjigè sí i, wón yàn láti fi òpin sí ìjoba alájùmòse tí Olùbákin dá sílè pèlú Olúgbo, wón kórajo sí Òbe-nlá, wón sì so ibè di ibùdo Olúbo gégé bí i oba aládé.

Iwe ti a yewo

ÀGBÉYÈWÒ ORÍKÌ OLÚBO ÒBÈ-NLÁ NÍ ILÈ ÌLÀJE

APÁ KAN NÍNÚ ÀSEKÁGBÁ OYÈ

B.A (HONS.) YORÙBÁ

YUNIFÁSÍTÌ OBÁFÉMI AWÓLÓWÒ

ILÉ-IFÈ, NIGERIA

LÁTI OWÓ

OWÓYELÉ OYÈKÀNMÍ KEEN

OSÙ ÒPÈ, 2007