Abrahamu: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
New page: Abraham ==Abraham == Eni tí ó dá ilè àwon Júù sílè. Wón bí i ní Ur. Omo Terah ni Abram. Ó sí ló sí Haran ní gusu Mesopotama pèlú bàbá rè...
(Kò ní yàtọ̀)

Àtúnyẹ̀wò ní 15:28, 15 Oṣù Kejì 2008

Abraham

Abraham

Eni tí ó dá ilè àwon Júù sílè. Wón bí i ní Ur. Omo Terah ni Abram. Ó sí ló sí Haran ní gusu Mesopotama pèlú bàbá rè, Ìyàwó rè Sarah àti Lot tó jé ‘nephew’ rè Nígbà tí ó lo sí Kénáànì, ó gbó ìpè Jehovah pé ibè ni ilè ìlérí fún àwon ènìyàn rè. Ó gba ìlérí Olórun yìí. Léyìn ìgbà tí ó ti gbé Egypt ní àsìkò ìyàn tí òun àti Lóòtì sì ti pínyà ní Bethon, ó lo dó sí Hebrian. Nígbà tí Jehovah yí orúko rè sí Abraham èyí tí i se baba orílè èdè púpò, Jehovah se ìlérí fún un pé òun yóò fún ní omo tí yóò jogún rè. Jehovah dán an wò pé kí ó pa Isaac omo rè fún ìrúbo. Bí ó ti féé se é ni Jehovah fi òdó àgùntan kan rópò omo yìí. Láti òdò ìyàwó rè Ikejì, Keturah, ó bí omokùnrin méfà. Wón sin ín síu iho (cave) Machpelah.


Abomey

Abomey

Ìlú kan nì yí ní ilè Benin (Dahomey) ní ìwò-oòrùn Aáfíríkà. Okò ojú omi máa n dó sí ìlú yìí. Nígbà kan, òun ni olú ìlú Benin. Wón mo odi oníyèpè yí ìlú yìí ká ní ayé àtijó. Ní 1953, àwon ènìyàn tí ó n gbé ìlú yìí jé 18,900.

Aborigine

Aborigines

Àwon ènìyàn kan tí ó máa n jé pé àwon ni ó kókó dé orílè-èdè kan ní àsìkò tí a kò lè fojú dá. A ti wá n lo òrò yìí ní ìsìnsìnyí fún àwon tí ó n gbé ibi tí àwon Òyìnbó dó sí ní pàtàkì Australia.


Abery'stwyth

Abery’stwyth

Ibi ìgbafé ni ìlú yìí Yunifásítì sì wà ní ibè. Ní Cardiganshire ní wales lénu odò Ystwyth ni ó wà. Ibi odi kan tí Edward 1 kó ni ìlú náà ti bèrè síí dìde ní odún 1227. Wón dá University College of Wales sílè ní 1872 wón sì n tójú Welsh Plant Breeding Station. Ní etí odi Abery’stwyth ni National Library wà ti Wales wà. Wón n pa aso láró ní ìlú náà. Ní 1961, àwon tí ó n gbé ìlú náà jé 10,418.