Benito Mussolini: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
New page: MUSSOLINI BENITO Wón bí Benito ní 1883. Ó kú ní 1945. Òun ni ó dá egbé òsèlú Fascist sílè ní Italy. Òun ni ó darí Italy ní 1922 sí 1943. Agbára n...
(Kò ní yàtọ̀)

Àtúnyẹ̀wò ní 09:17, 16 Oṣù Kẹta 2008

MUSSOLINI BENITO

Wón bí Benito ní 1883. Ó kú ní 1945. Òun ni ó dá egbé òsèlú Fascist sílè ní Italy. Òun ni ó darí Italy ní 1922 sí 1943. Agbára ni ó fi n darí ilè náà (a dictator). It Duce tí ó dúró fún olórí (the leader) ni àwon èyìn rè máa n pè é. Mussolini àti ìgbìmò Fascist Party ni won jo n darí Italy. Won kò gba alátakò kankan láyè.

Gégé bí ajàfún-mèkúnnù (socialist) ni Mussohni se wo òsèlú. Ó jé olóòtu ìwé-ìróyìn kan tí ó n jé ní Avanti sùgbón ní 1914, ó dá ìwé-ìroyìn tirè sílè. Ó pè é ní IL Popolo d’Italia. Ní odún 1921 ni ó dá egbé òsèlú Fascist sile. Èrò tí ó ní nípa dídá egbé òsèlú yìí sílè ni láti lè tún Italy kó kí ó sì so ó di ìlú tí ó lágbára. Léyìn ìgbà tí àwon Fascist rìn lo sí Róòmù ní 1922 (‘Fascist March on Rome’), Oba Victor Emmanuel III pe Mussoline láti wá gbé ìjoba tirè kalè. Kò pé tí àwon Fascist bèrè síí darí ilè Italy.

Àwon omo ogun Mussoline kolu Ethopia ní 1905 wón sì ségun ibè léyìn òpòlopò ìjà tí ó gbóná. Kò pé tí Mussolini ní kí àwon omo ogun òun lo ran General Franco lówó nínú ogun abélé ilè Spain. Ní 1940, Italy bèrè síí kópa nínú ogun àgbáyé kejì. Italy dúró gbá gbá gba ti Germany sùgbón wón ségun Italy. Won di ebi ifidíremi Italy yìí ru Mussolini. Wón gba ìjoba lówó rè wón sì so ó sí èwòn. Àwon German gba á sílè ó wa di olórí ìjobá tí kò fesè múlè kan. Ní odún 1945, àwon tí ó n jà rí i mú, wón sì pa á.