Ìgbéyàwó: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
Àwọn àlẹ̀mọ́: Àtúnṣe ojú fóónù Àtúnṣe ojú fóónù
Àwọn àlẹ̀mọ́: Àtúnṣe ojú fóónù Àtúnṣe ojú fóónù
Ìlà 14:
'''Ìwádìí:''' Èyí ni ìgbésẹ̀ kejì nínú àṣà ìgbéyàwó nílẹ̀ Yorùbá láyé àtijó. Ẹbí ọkùnrin yóò ṣe ìwádìí ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ nípa ọlọ́mọge tí wọ́n tí yàn láàyò láti fẹ́ fún ọmọkùnrin wọn. Wọ́n máa ń ṣe ìwádìí irú ìdílé tí omidan náà tí wá. Ṣé ìdílé tó dára ní tàbí tí kò dára?, wọ́n a ṣe ìwádìí bóyá ìdílé náà ní àrùn tàbí àìsàn kan tí ó máa ń ṣe wọ́n. Bí ìdílé bá yege nínú àwọn ìwádìí yìí, àsìkò yìí ni wọn yóò tó pinnu láti fẹ́ omidan náà fún ọmọkùnrin wọn.
 
'''Alárenà:''' Lẹ́yìn ìwádìí, yínyan Alárenà ni ìgbésẹ̀ tó kàn láṣà ìgbéyàwó láyé àtijó. Alárenà ni yínyan ẹnìkan tí ó lè ṣe agbódegbà fún ọkọ àti ìyàwó-ojú ọ̀nà. Ẹni bẹ́ẹ̀ sáà máa ń jẹ́ ọ̀rẹ́ ọkàn nínú àwọn tọkọ-taya-ojúọ̀nà. Òun ni àwọn méjèèjì mama rán níṣẹ́ ìfẹ́ títí títí ọkọ àti ìyàwó yóò fi mójú ara wọn. Ìdí nìyí tí Yòóbá fi máa ń paá lówe pé "bí ọkọ àti ìyàwó bá mọjú ara wọn tán, alárenà á yẹ̀ a"
 
'''Ìjọhẹn:''' Èyí ni ìgbésẹ̀ tí ẹbí ọkọ ìyàwó-ojúọ̀nà máa ń gbé láti ríi pé àwọn ẹbí ìyàwó-ojúọ̀nà gba láti fi ọmọbìnrin wọn fọ́kọ tí ó wá tọrọ rẹ̀. Ó dàbí ètò mọ̀mínmọ̀ọ́.
 
'''Ìdána:''' Lẹ́yìn Ìjọ́hẹn, ìdána ni ètò tó kàn nínú ayẹyẹ àṣà ìgbéyàwó láyé àtijó. Ìdána ni sísan àwọn ẹrù àti owó tí ẹbí ìyàwó-ojúọ̀nà bá kà fún oko-ojúọ̀nà
 
À ń tẹ síwájú sìi lórí ọ̀rọ̀ yìí