Ìgbéyàwó: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
Àwọn àlẹ̀mọ́: Àtúnṣe ojú fóónù Àtúnṣe ojú fóónù
No edit summary
Àwọn àlẹ̀mọ́: Àtúnṣe ojú fóónù Àtúnṣe ojú fóónù
Ìlà 23:
'''Ẹkún-Ìyàwó:''' Èyí ni ayẹyẹ ìkẹyìn tí ìdílé ìyàwó máa ń ṣe fún omidan tí ó ṣetàn láti ṣe ìgbéyàwó kí ó tó forí lé ilé ọkọ rẹ. Omidan tí ó fẹ́ lọ ilé ọkọ ni ó máa ń sun ẹkùn ìyàwó. Omidan yìí a máa sún ẹkùn yìí láti dárò bí ó ṣe fẹ́ fi ilé bàbá rẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ilé ọkọ. Ẹkún ayọ̀ ni èyí ẹkún ìyàwó máa ń jẹ́.
 
'''Ìgbéyàwó Gangan:''' Èyí ni ayẹyẹ tó kẹ́yìn láṣà ìgbéyàwó nílẹ̀ Yorùbá láyé àtijó. Ó máa ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọkọ-ojúọnà bá ti san gbogbo ẹrù ìdána. Àwọn ìdílé ìyàwó-ojú ọnà yóò wa sètò láti sìn ìyàwó lọ ilé ọkọ rẹ. Ọ̀kan-ọ̀-jọ̀kan àwọn ẹbí ìyàwó àti ọkọ á máa wúre fún ìyàwó àti ọkọ rẹ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó. Jíjẹ àti mímu máa ń pọ̀ lọ́pọ̀ yanturu.
 
==Pàtàkì Ìbálé Nínú Àṣà Ìgbéyàwó Láyé Àtijọ́==
 
Ìbálé ni bíbá ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀ gbé nílé láì tí bá ọkùnrin kankan sùn rí kí ó tó lọ ilé ọkọ. Ó jẹ́ àṣà tí ó gbajúmọ̀ tí ó sìn máa ń buyì kún ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀gbé. Ìwúrí ni ó máa ń jẹ́ fún ọkọ ìyàwó tí ó bá bá ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀gbé nílé. Ohun ìtìjú àti ìbànújẹ́ ni ó máa ń jẹ́ fún ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀gbé tí ọkọ rẹ̀ kò bá bá nílé àti ìdílé rẹ̀. Kódà, ònínàbì àti òníranù ni Yòóbá máa ń ka irú ìyàwó-aṣẹ̀ṣẹ̀gbé bẹ́ẹ̀ sì.
 
À ń tẹ síwájú sìi lórí ọ̀rọ̀ yìí