Lateef Adedimeji: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
New Page
Àwọn àlẹ̀mọ́: Àtúnṣe ojú fóónù Àtúnṣe ojú fóónù Advanced mobile edit
 
Àwọn àlẹ̀mọ́: Àtúnṣe ojú fóónù Àtúnṣe ojú fóónù Advanced mobile edit
Ìlà 1:
'''{{PAGENAME}}''' (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kìíní oṣù kejì ọdún 1986) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré, oǹkọ̀tàn àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí [[ìpínlẹ̀ Ògùn]] ṣùgbọ́n tí wọ́n bí sí [[ìpínlẹ̀ Èkó]] lórílẹ̀ èdè [[Nàìjíríà]]. Lọ́dún 2013 ni ìràwọ̀ rẹ̀ gbòde kan lẹ́yìn látàrí ipa tí ó kó nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Kudi Klepto", tí Yéwándé Adékọ̀yà ṣe agbátẹrù rẹ̀. {{PAGENAME}} tí kópa nínú sinimá àgbéléwò tí ó ti ju ọgọ́rùn-ún lọ lẹ́yìn tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn. Ó gbajúmọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ilé iṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ Airtel fi fi í ṣe aṣojú wọn.
 
==Ìgbé-ayé àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀==
 
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, wọ́n bí Lateef Adédiméjì ní Ọjọ́ kìíní oṣù kejì ọdún 1986 ni ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ṣùgbọ́n ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ògùn ni.<ref name="theinfopro.com.ng">{{cite web|url=https://theinfopro.com.ng/lateef-adedimeji-biography-net-worth-wikipedia/|title=Lateef Adedimeji Biography and Net Worth 2019}}</ref> O kàwé gboyè dìgírì nínú ìmọ̀ ìwé ìròyìn, ni ifáfitì [[Olabisi Onabanjo University]].<ref>{{cite web|url=https://www.pulse.ng/entertainment/movies/7-emerging-yoruba-movie-stars-you-need-to-know/vtfplhw|title=7 emerging Yoruba movie stars you need to know|work=Pulse.ng}}</ref>