Ìgbéyàwó: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
format section heading; Reflist template
Ìlà 11:
==Àwọn Ìgbésẹ̀ Àṣà Ìgbéyàwó Láyé Àtijọ́==
 
===Ìfojúsóde===
'''Ìfojúsóde:''' Èyí ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tí àwọn òbí ọmọkùnrin tó bá ti bàlágà máa ń gbé láti ṣe àwárí omidan tó bá yáyì tí wọ́n yóò fi ṣaya fún ọmọ wọn. Láyé àtijó, ọmọkùnrin kì í kọnu sí omidan tó bá wù ú. Lẹ́yìn tí àwọn òbí bá ti fojú sóde, tí wọ́n sì ti rí omidan tí wọ́n fẹ́ kí ọmọkùnrin wọn fẹ́ ní ìyàwó, ìgbésẹ̀ tó kàn ní ìwádìí.
 
===Ìwádìí===
'''Ìwádìí:''' Èyí ni ìgbésẹ̀ kejì nínú àṣà ìgbéyàwó nílẹ̀ Yorùbá láyé àtijó. Ẹbí ọkùnrin yóò ṣe ìwádìí ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ nípa ọlọ́mọge tí wọ́n tí yàn láàyò láti fẹ́ fún ọmọkùnrin wọn. Wọ́n máa ń ṣe ìwádìí irú ìdílé tí omidan náà tí wá. Ṣé ìdílé tó dára ní tàbí tí kò dára?, wọ́n a ṣe ìwádìí bóyá ìdílé náà ní àrùn tàbí àìsàn kan tí ó máa ń ṣe wọ́n. Bí ìdílé bá yege nínú àwọn ìwádìí yìí, àsìkò yìí ni wọn yóò tó pinnu láti fẹ́ omidan náà fún ọmọkùnrin wọn.
 
===Alárenà===
'''Alárenà:''' Lẹ́yìn ìwádìí, yínyan Alárenà ni ìgbésẹ̀ tó kàn láṣà ìgbéyàwó láyé àtijó. Alárenà ni yínyan ẹnìkan tí ó lè ṣe agbódegbà fún ọkọ àti ìyàwó-ojú ọ̀nà. Ẹni bẹ́ẹ̀ sáà máa ń jẹ́ ọ̀rẹ́ ọkàn nínú àwọn tọkọ-taya-ojúọ̀nà. Òun ni àwọn méjèèjì maa rán níṣẹ́ ìfẹ́ títí títí ọkọ àti ìyàwó yóò fi mójú ara wọn. Ìdí nìyí tí Yòóbá fi máa ń paá lówe pé "bí ọkọ àti ìyàwó bá mọjú ara wọn tán, alárenà á yẹ̀ a"
 
===Ìjọhẹn===
'''Ìjọhẹn:''' Èyí ni ìgbésẹ̀ tí ẹbí ọkọ ìyàwó-ojúọ̀nà máa ń gbé láti ríi pé àwọn ẹbí ìyàwó-ojúọ̀nà gba láti fi ọmọbìnrin wọn fọ́kọ tí ó wá tọrọ rẹ̀. Ó dàbí ètò mọ̀mínmọ̀ọ́.
 
===Ìdána===
'''Ìdána:''' Lẹ́yìn Ìjọ́hẹn, ìdána ni ètò tó kàn nínú ayẹyẹ àṣà ìgbéyàwó láyé àtijó. Ìdána ni sísan àwọn ẹrù àti owó-orí tí ẹbí ìyàwó-ojúọ̀nà bá kà fún ọkọ-ojú ọ̀nà láti san.<ref name="Pulse Nigeria 2014">{{cite web | title=How It's Done In Yoruba Land | website=Pulse Nigeria | date=2014-10-02 | url=https://www.pulse.ng/traditional-marriage-rites-how-its-done-in-yoruba-land/6jk1dc0 | access-date=2019-11-14}}</ref> <ref name="Stella Dimoko Korkus.com">{{cite web | title=Asa Igbeyawo Ati Oju Ise Alarina Laye Atijo | website=Stella Dimoko Korkus.com | url=https://www.stelladimokokorkus.com/2018/08/asa-igbeyawo-ati-oju-ise-alarina-laye.html | language=ca | access-date=2019-11-14}}</ref>
 
===Ẹkún-Ìyàwó===
'''Ẹkún-Ìyàwó:''' Èyí ni ayẹyẹ ìkẹyìn tí ìdílé ìyàwó máa ń ṣe fún omidan tí ó ṣetàn láti ṣe ìgbéyàwó kí ó tó forí lé ilé ọkọ rẹ. Omidan tí ó fẹ́ lọ ilé ọkọ ni ó máa ń sun ẹkùn ìyàwó. Omidan yìí a máa sún ẹkùn yìí láti dárò bí ó ṣe fẹ́ fi ilé bàbá rẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ilé ọkọ. Ẹkún ayọ̀ ni èyí ẹkún ìyàwó máa ń jẹ́.
 
===Ìgbéyàwó Gangan===
'''Ìgbéyàwó Gangan:''' Èyí ni ayẹyẹ tó kẹ́yìn láṣà ìgbéyàwó nílẹ̀ Yorùbá láyé àtijó. Ó máa ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọkọ-ojúọnà bá ti san gbogbo ẹrù ìdána. Àwọn ìdílé ìyàwó-ojú ọnà yóò wa sètò láti sìn ìyàwó lọ ilé ọkọ rẹ. Ọ̀kan-ọ̀-jọ̀kan àwọn ẹbí ìyàwó àti ọkọ á máa wúre fún ìyàwó àti ọkọ rẹ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó. Jíjẹ àti mímu máa ń pọ̀ lọ́pọ̀ yanturu.
 
http://edeyorubarewa.com/a%E1%B9%A3a-igbeyawo/