Tẹlifóònù: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
No edit summary
No edit summary
Ìlà 1:
[[Fáìlì:WTel 01 LX.jpg|thumb|200px|Ẹ̀rọ tẹlifóònù]]
'''Tẹlifóònù''' ni ẹ̀rọ [[telecommunication|ìbánisọ̀rọ̀-wáyàjíjìnnà]] kan tó úngba àwọn olùṣeúnkan méjì tàbí púpọ̀ ní àyè láti [[conversation|sọ̀rọ̀]] sí ara wọn tààrà nígbà tí wọ́n bá jìnnà sí ara wọn. Tẹlifóònù únsiṣẹ́ nípa yíyí [[sound|ohùn]], àgàgà [[human voice|ohùn ènìyàn]], sí [[Signal|àwọn àmì]] ìṣiṣẹ́ ẹ̀rọ-oníná tí wọ́n ṣe é gbé pẹ̀lú [[Electrical cable|wáyà]], àti àwọn ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ míràn, lọ sí orí tẹlifóònù míràn tí yíò ṣe àtúngbéjáde ohùn náà fún ẹni tó úngbọ́ọ nìbòmíràn. Ìtumọ̀ tẹlifóònù jáde láti {{lang-el|τῆλε}} (''tẹli'', ''ọ̀ọ́kán'') àti φωνή (''fóònù'', ''ohùn''), lápapọ̀ tí wọ́n túmọ̀ sí ''ohùn ọ̀ọ́kán'' (''distant voice''). A tún le pèé lásán ní '''fóònù'''.
 
Ní ọdún 1876, [[Alexander Graham Bell]] ló kọ́kọ́ gba [[patent|ìwé àṣẹ ìdọ́gbọ́n]] ní [[United States|Amẹ́ríkà]] fún ẹ̀rọ kan tó gbé ohùn ènìyàn jáde kedere. Ẹ̀rọ yìí gba àtúnṣe lọ́wọ́ àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn míràn, nítorí bẹ́ẹ̀ ó di ohun ìlò dandan fún [[business|ìkòwò]], [[government|ìjọba]], àti àwọn [[Household|agbolé]].