Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò "Hassan Ahmad Zaruq"

3 bytes removed ,  11:18, 25 Oṣù Kẹjọ 2020
section headings: fix format; Reflist template
(section headings: fix format; Reflist template)
'''Shaikh Hassan Ahmad Zaruq''' (Pàkátà) jẹ́ afáà àgbà, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ̀sìn Mùsùlùmí, ọmọ bìbí ìlú [[Ìlọrin]]. Wọ́n bí ní agbolé Oníkanún ní àdúgbò Pàkátà ní ìlú [[Ìlọrin]] ní [[Kwara state|Ìpínlẹ̀ Kwara]] ní (18th August 1957). <ref name="DARUSSALAM ILORIN 1957">{{cite web | title=biography of sheikh | website=DARUSSALAM ILORIN | date=1957-08-18 | url=http://darussalamglobal.jimdofree.com/home/sheikh-s-profile/biography-of-sheikh/ | access-date=2020-08-24}}</ref>
 
===Àwọn òbí rẹ̀===
Orúkọ bàbá rẹ̀ ni Alhaji Ahmad Zaruq tí orúkọ ìyá rẹ̀ sì ń jẹ́ Hajia Asmah. Bàbá rẹ̀ jẹ́ [[Muslim|Mùsùlùmí]] tí ó sì nífẹ̀ẹ́ sí gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́ onímọ̀, yàlà nínú ẹ̀sìn ni tàbí ìmọ̀ tó ṣe pàtàkì mìíràn, tí ó sì ma ń sapá rẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà gbogbo pẹ̀lú owó àti ìgbìyànjú rẹ̀. Bákan náà, Alhaji Ahmad Zaruq tún jẹ́ oníṣòwò tí ó lààmì-laka nínú iṣẹ́ aṣọ ìbílẹ̀ Aṣọ Òfì tàbí [[Aṣọ Òkè]]. Wọ́n fi Alhaji Ahmad Zaruq joyè Bàbá Àdínì àkọ́kọ́ ní mọ́sálásí Bàbà Pupa ní àdúgbò pàkátà ní ìlú [[Ilọrin]]. Nígbà tí ìyá rẹ́ Hajia Asmah náà jẹ́ gbajúmọ̀ nípa kí á bọ̀wọ̀ fún ọkọ nílé àti nìta.
 
===Ètò Ẹ̀kọ́ rẹ̀===
Shaikh Hassan Zaruq bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Lárúbáwá (Arabic School) nínú ẹ̀sìn [[Muslim|Músùlùmí]] ní ilé-kéwú ọ̀dọ̀ àbúrò bàná rẹ̀ ní Pàkátà ìyẹn Shaikh Suleiman ẹni tí ó kọ ní kìkà [[Quran|Alùkùránì]] ṣájú kí ó tó lọ sílé ẹ̀kọ́ Lárúbáwá (Shuban Arabic School),ní Pàkátà. Lẹ́yìn tí ó parí nílé-ẹ̀kọ́ yí, bàba rẹ̀ mu lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Markazu Ta'liimil 'arabi al-Islami, ilé-ẹ̀kọ́ tí ó jẹ́ àgbọ́n-ọgbẹ ilé ìmọ̀ ẹ̀sìn Mùsùlùmí ní ìlú [[Agége]] lábẹ́ àkóso Afáà àgbà [[Sheik Adam Abdullah Al-Ilory]] fún ìtẹ̀síwájú ẹ̀kọ́. Shaikh Hassan Zaruq jẹ́ olólùfẹ́ ìmọ̀, tí ó sì ma ń wá ìmọ̀ níbi tí ó bá ti ri, gẹ̀gẹ́ bí àṣẹ òjíṣẹ́ Ọlọ́run [[Prophet Muhammad| ànọ́bì Muhammad]] tí ó nì: "Ibikíbi tí ẹ bá ti rí ìmọ̀ ni kí ẹ ti kọ́ọ, nítorí ìmọ̀ ti sọnù lọ́jọ́ tó ti pẹ́". Látàrív ìdí èyí, ó kópa nínú ìdániẹ́kọ̀ọ́ tí Fásitì Madinah, ẹ̀ka ti [[Kano|ìpínlẹ̀ Kánò]] gbé kalẹ̀ ní àsìkò ọdún1990s.
 
===Ìkẹ́kọ̀ọ́ Súúfi àti àṣeyọrí rẹ̀===
Shaikh Hassan Ahmad Zaruq kẹ́kọ̀ọ́ nípa Súfí lójú ọ̀nà [[Tijaniyyah]], láti ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹni oríṣà tí wọ́n lààmì laaka láàrín àwọn Àfáà Mùsùlùmí. Lára wọn ni [[Sheikh Abubakr Sidiq Agbarigidoma]], [[Sheikh Muhammad Tukur bn Amiinullah]]. Ìlànà ṣíṣe Súúfí rẹ̀ ni ó ràn-án lọ́wọ́ jùlọ láti lo òfin àti ìlànà ẹ̀sin Mùsùlùmí láì yan ìkan ní pọ̀sìn. Ó dá agbo Súúfí tirẹ̀ náà sílẹ̀ tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní "Zawiyyah Daru Salam" ní [[Ajélógo]] [[Kétu]] Mile2 ní 1980s,àti [[Láborà]] ní ọdún 1999 ní ìpínlẹ̀ [[Èkó]], tí ó sì tún fi lọ́lẹ̀ ní [[Modinatu Daru Salam]] [[Okolówó]] níbọdún 2006. Záwiyyah yí sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Mukadam láti ìgbà náà títí di óní tí wọ́n dipọ́ pàtàkì mú nínú agbo [[Tijaniyya]].
 
===Àwọn Ọ̀rẹ rẹ̀===
Shaikh Hassan ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ látàrí ìwà ìkóni mọ́ra rẹ̀ àti ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán pẹ̀lú ìtẹríba rẹ̀ fún tọmọdé tàgbà láì wontẹ̀sìn tàbí ẹ̀yà kan kan. Látàrí àwọn ìwà ọmọlúàbí rẹ̀ yí ni ó ṣe di ọ̀rẹ́ pẹ̀lú [[Sheikh Nurullah Hakiim]], [[Sharif Muhammad Kabir b. Muhammad]], ọ̀kan lára àwọn àrọ́mọdọ́mọ [[Prophet Muhammad|ànọ̀bí Muhammad]](SAW).Ẹ̀wẹ̀, lórípa ìlànà [[Tijaniyyah]], Sheik Ahmad Hassan Zaruq dé ipò ''QUTBUL AQTAAB'' tí ó túmọ̀ sí (CUSTODIAN OF THE LUMINOUS THRONE), ní èyí tí ó jẹ́ ipò tí ó ga jùlọ ní ojú ọ̀nà náà, tí ó sì tún wà ní ipò ''BAQIYYATULLAH'' tí ó túmọ̀ sí (THE POSSESSOR OF THE IMAMSHIP). Àwọn ipò wọ̀yí ó dú ró fún pàpin ìmọ̀ àti ìlànà fún káti darí ẹ̀sìn pẹ̀lú ìmọ̀nà rẹ̀.
 
==Dídá ilé-ẹ̀kọ́ rẹ̀ kalẹ===
Shaikh Hassan Ahmad Zaruq Pakata dá ilé-ẹ̀kọ́ Lárúbáwá tirẹ̀ tí ó pè ní ''MARKAZ DARUS SALAM ARABIC ISLAMIC SHOOL, MARKAZ DARUS SALAM LITA'ALIMIL 'ARABI AL-ISLAMI'' ní ọdún 1982. Iké-ẹ̀kọ́ yìí ti kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Afáà kànkà-kànkà jáde láti ìpele àárin "Idadiyyah" (intermediate level), ìpele àṣekágbá "thanawiyyah" (Secondary level) láti ọdun 1990.
<ref name="Ibrahim 2015">{{cite web | last=Ibrahim | first=Sulaiman Algamawi | title=SHORT BIOGRAPHY OF SHAIKH HASSAN AHMAD ZARUQ PAKATA | website=Academia.edu | date=2015-08-03 | url=https://www.academia.edu/4771539/SHORT_BIOGRAPHY_OF_SHAIKH_HASSAN_AHMAD_ZARUQ_PAKATA | access-date=2019-05-12}}</ref>
 
===Àwọn ìwé rẹ̀ tí ó ti kọ===
Pẹ̀lú ìyọ̀nda [[God|Ọlọ́hun]],kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ẹ̀sìn àti ewì Lárúbáwá wọ̀nyí:
'Mukhtasar ibn Zaruq fil aofaw,
'jiimaytul madih (walaetaki ya lailah), Allahu Akbar fi samahi iraan, Al-Kaokabul wahaji fi soibilisrahi walimi'raji, Qosidatu bisimililahikhaliqlibarayah,Qosidatu astagfirllah' àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
 
===Àwọn ìpàdé ìmọ̀ àti ẹ̀sìn tó ti kópa===
Shaikh Hassan Ahmad Zaruq darapọ̀ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ̀ rẹ̀ ní: Islamic conferences ní Fez, Morocco,
Shaotta, Madinatul Kaolakhi, Senegal àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀.
 
{{ẹ̀kúnrẹ́rẹ́}}
===Àwọn ìtọ́ka sí===
{{Reflist}}