Emmanuel Ifeajuna: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
Mo se afikun imo oju ewe yi
Ìlà 1:
'''Emmanuel Arinze Ifeajuna''' (ọdun 1935 si ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹsán ọdun 1967)<ref>"Emmaunel Ifeajuna". Brinkster. Retrieved 2014-07-13.</ref> jẹ ọmọ ológun ni orilẹ-ede [[Nàìjíríà]] ati elere idaraya ni ẹka ifo fifo. Òun ni ọmọ adulawọ akọkọ ti o gba àmì ẹ̀yẹ wura nibi idije agbaaye ni ibi ere idaraya ti Ijọba Gẹẹsi gbe kalẹ ni ọdun 1954. Iwon ifo ti o mu gba ami ẹyẹ wura ni iwon ẹsẹ bata mefa o le ipin mẹjọ (6&nbsp;ft 8) ninueyini iwon mita meji o le meta (2.03&nbsp;m) eleyi si jẹ ìgbà akọkọ ti ẹnikẹni yoo fo iru iwọn yii.
 
Ọmọ bibi ilu Onitsha ni ẹya ibo lati orilẹ-ede Naijiria ni i ṣe, o si kẹkọ gboye ninu imoijinlẹ sayẹnsi lati ile-iwe giga ti Yunifasiti Ibadan. O dara pọ mo oṣelu, lẹyin eyi ni o tun gba iṣẹ ologun. O ko ipa pataki ninu ifipa gba ijọba lowo oloselu ti o waye ni orilẹ-ede Naijiria ni ọdun 1966.
Ìlà 6:
 
==== Eré ìdárayá ìfò fífò ====
Ọmọ bíbí ìlú [[Onitsha]]<ref name="MS1">Siollun, Max (2005-10-30). "The Inside Story Of Nigeria’s First Military Coup (I)". ''Nigeria Matters''. Retrieved on 2014-07-13.</ref> ni, ó lọ sí Ilé-ìwé Girama Dennis Memorial ni ilu abinibi rẹ o si fi awọn abuda ti yoo sọ ipa ti igbesi aye rẹ tọ han nigba naa. Olùkọ́ eré ìdárayá ni ile-iwe girama rẹ ni o kọ ọ ni ere idaraya ifo fifo<ref name=":0">Oliver, Brian (2014-07-13). "Emmanuel Ifeajuna: Commonwealth Games gold to facing a firing squad". ''The Guardian''. Retrieved 2014-07-13.</ref>. Bakanna ni o wa lara awon ti o fi ehonu han eleyi ti o mu ki won gbe ile-ẹkọ giga re fun saa ẹkọ kan. O jade ile-iwe girama ni ọdun 1951<ref>Onyema, Henry (2013-10-23). "EMMANUEL IFEAJUNA – The Man Called Emma Vancouver". Naija Stories. Retrieved 2014-07-13.</ref> Ile-iwe Girama ti Ilesa naa le ka a kun awon akeko ti o jade nibe, biotilejepe awon ariyanjiyan kan jeyo ninu iroyin yi, sugbon o daju wipe o ṣe ile ẹkọ fun saa akoko oorun nigba kan ri nibe.<ref>Major Emmanuel Ifeajuna Archived 14 July 2014 at the Wayback Machine. Ilesa Grammar School. Retrieved 2014-07-13.</ref>
 
Ní idije ere idaraya ni ọdun 1954 ni Vancouver, o dije pẹlu bata ẹsẹ kan, ẹsẹ osi, sibẹsibẹ, o bori nipa fifo ifo iwon ẹsẹ bata mẹfa o le mẹjo (mita 2.03), eleyi ti o ta yọ ohun ti ẹnikẹni ti fo ri boya ni ti ere idije ni tabi ni ti orilẹ-ede Gẹẹsi. Ami ẹyẹ wura ti o gba nidi eyi jẹ igba akọkọ ti alawọ dudu yoo gba nibi idije to laami laaka lagbaye. Idije ifo fifo yii gbajugbaja ni odun naa fun awon alawọ dudu nitoripe Patrick Etolu ti o jẹ ọmọ orilẹ-ede Uganda naa se ipo keji tẹle Ifeajuna tí Osagie, ti o je ọmọ orilẹ-ede Naijiria si ṣe ipo kẹta. T'iIu t'ifọn ni wọn fi ki Ifeajuna kaabọ nigba ti o pada de ilu Eko, ijo ati ayọ ni wọn fi gbe yipo ilu Eko kí o to dari si ibi a wẹjẹ-wẹmu kan nibi ti o ti sọ̀rọ̀. Aworan rẹ̀ si di ohun ti a ya si ẹyin iwe ajakọ ti awọn ọmọ ile-iwe alakọbẹrẹ ati girama n lo ni orilẹ-ede Naijiria<ref name=":0" />.
 
== Àwọn ìtọ́kasí ==