Tariro Mnangagwa: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
Created by translating the page "Tariro Mnangagwa"
 
Afikun ikọ
Ìlà 2:
{{Infobox person|name=Tariro Mnangagwa|residence=|footnotes=|website=|signature=|relatives=|mother=Jayne Matarise|father=[[Emmerson Mnangagwa]]|awards=|children=|spouse=|party=|years_active=2018–present|height=|alma_mater=[[Cape Peninsula University of Technology]]|other_names=|nationality=[[Zimbabwe]]an|resting_place_coordinates=<!-- {{coord|LAT|LONG|display=inline,title}} -->|resting_place=|death_place=|death_date=|birth_place=[[Zambia]]|birth_name=Tariro Washe Mnangagwa|birth_date=1986|caption=|alt=|image_size=|image=|occupation=Actress, film producer, social activist}}
'''Tariro Washe Mnangagwa''' (tí wọ́n bí ní ọdún 1986) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè [[Sìmbábúè]].<ref>{{cite web|url=https://iharare.com/meet-tariro-mnangagwa/|title=Like Father Like Daughter……Meet ED's Youngest Daughter|publisher=iharare|accessdate=19 October 2020}}</ref> Ó gbajúmọ̀ jùlọ fún ipa rẹ̀ tí ó kó nínu eré kan ti ọdún 2020 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ ''Gonarezhou''. Ó jẹ́ ọ̀kan nínu àwọn ọmọ obìnrin Ààrẹ orílẹ̀-èdè Sìmbábúè lọ́wọ́lọ́wọ́ ti orúkọ rẹ̀ n ṣe [[Emmerson Mnangagwa]].
 
== Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀ ==
Wọ́n bí Tariro ní ọdún 1986 ní orílẹ̀-èdè [[Sámbíà]]. Òun ni ọmọ obìnrin àbígbẹ̀yìn nínu àwọn ọmọ mẹ́fà ti àwọn òbí rẹ̀. Bàbá rẹ̀ ni Ààrẹ orílẹ̀-èdè Sìmbábúè lọ́wọ́lọ́wọ́. Ìyá rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Jayne Matarise di olóògbè ní 31 Oṣù Kínní, Ọdún 2002 látàrí ààrùn jẹjẹrẹ kan. Tariro ní àwọn ọmọìyá márùn-ún tí wọ́n ṣe: Farai, Tasiwa, Vimbayi, Tapiwa, àti Emmerson Tanaka. Lẹ́hìnwá ikú ìyá rẹ̀, bàbá rẹ̀ fẹ́ [[Auxillia Mnangagwa|Auxillia Kutyauripo]] tí òun náà síì ti ní ọmọ mẹ́ta: Emmerson Jr. àti àwọn ìbejì tí wọ́n ṣe Sean àti Collins.<ref>{{Cite web|url=https://nehandaradio.com/2018/03/23/mnangagwa-family-disclosures-raise-eyebrows/|title=Mnangagwa family disclosures raise eyebrows|last=Phiri|first=Gift|date=2018-03-23|website=Nehanda Radio|language=en-US|access-date=2020-04-03}}</ref>
 
== Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀ ==
Tariro gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ fọ́tòyíyà láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga kan tí ó wà ní ìlú [[Cape Town]]. Ó tún gba oyè-ẹ̀kọ́ míràn nínu ìmọ̀ ìṣàkóṣo eré ìdárayá láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga[[Cape Peninsula University of Technology]]. Lẹ́hìn tí ó padà sí orílẹ̀-èdè Sìmbábúè, Tariro darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Akashinga, ẹgbẹ́ kan tí ó n rí sí dídáàbò bo àwọn ẹranko orí-ilẹ̀ àti inú-omi àti láti tako dídẹdẹ àwọn ẹranko náà lọ́nà àìtọ́. Ó padà tún darapọ̀ mọ́ irúfẹ̀ ẹgbẹ́ náà ti àgbáyé, èyí tí wọ́n pè ní International Anti-Poaching Foundation.<ref>{{cite web|url=https://www.theguardian.com/world/gallery/2017/dec/17/all-female-anti-poaching-combat-unit-in-pictures|title=All female anti-poaching combat unit|publisher=theguardian|accessdate=19 October 2020}}</ref><ref>{{cite web|url=https://allafrica.com/stories/201712181000.html|title=Zimbabwe: Mnangagwa Daughter Joins Elite Anti-Poaching Unit|publisher=allafrica|accessdate=19 October 2020}}</ref>
 
Láìpẹ́ jọjọ sí dídarapọ̀ rẹ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àgbáyẹ́ náà, wọ́n pèé láti wá kópa nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ ''Gonarezhou'', èyí tí olùdarí eré [[Sydney Taivavashe]] ṣe,<ref>{{cite web|url=https://news.pindula.co.zw/2018/10/02/president-emmerson-mnangagwas-daughter-tariro-to-feature-in-an-anti-poaching-film/|title=President Emmerson Mnangagwa's Daughter Tariro To Feature In An Anti-Poaching Film|publisher=pindula|accessdate=19 October 2020}}</ref> tí Ààjọ ''Zimbabwe Parks and Wildlife Management Authority'' síì ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀.<ref>{{Cite web|url=https://www.dailynews.co.zw/articles/2018/10/02/ed-s-daughter-in-anti-poaching-film|title=ED's daughter in anti-poaching film|last=comments|first=Blessing Masakadza • 2 October 2018 1:59PM • 0|website=DailyNews Live|access-date=2019-03-27}}</ref> Tariro kópa gẹ́gẹ́ bi 'Sergeant Onai' nínu eré náà.<ref>{{Cite web|url=https://bulawayo24.com/index-id-news-sc-national-byo-146675.html|title=Mnangagwa's daughter in anti-poaching film|website=Bulawayo24 News|access-date=2019-03-27}}</ref>
 
== Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀ ==
{| class="wikitable"
!ọdún
!Àkọ́lé eré
!Ipa
!Irúfẹ̀
!Ìtọ́kasí
|-
|2020
|''Gonarezhou''
|Sergeant Onai
|Fiimu
|
|}
 
== Àwọn ìtọ́kasí ==