Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Muṣin: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
 
Ìlà 3:
 
==Ètò ọrọ̀-ajé ati ààtò ìlú ==
Lẹ́yìn tí ìjọba àwọn Gẹ̀ẹ́sì wó ní orílẹ̀-èdè [[Nàìjíríà]], oríṣiríṣi ìdàgbà-sókè ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ń de bá agbègbè Muṣin. Lára rẹ̀.ni bí àwọn ènìyàn ṣe ń kúrò ní abúlé tí wọ́n sì ń kò lọ sí àárín ìgboro [[Èkó]], pàá pàá jùlọ agbègbè Muṣ. Látàrí àpọ̀jù èrò yí, [[ilé]] gbígbé ati iṣẹ́ ṣíṣe le koko. Amọ́ sa,ìlú Muṣin tún ní ànfaní láti ní àwọn ilé-iṣẹ́ oríṣiríṣi. Lára àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó ti wà níbẹ̀ ni ilé-iṣẹ́ [[aṣọ]] àti [[òwú]], ilé-iṣẹ́ [[bàtà]], ilé-iṣẹ́ tí ó ń pèsè kẹ̀kẹ́ ológere ati [[kẹ̀kẹ́Kẹ̀kẹ́ alùpùpùAlùpùpù]] àti ilé-iṣẹ́ tí ó ń pèsè [[mílíkì]]
 
Ìlú Muṣin ní àwọn ohun amáyéderùn bíi ilé ìwòsàn àti ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀ tí tí dé ilé ẹẹ̀kọ́ girama pẹ̀lú ohun èlò tìgbà lo de fún àwon akẹ́ẹ̀kọ́. Ìlú Muṣin tún ní àwọn ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí a lè gbà wọ inú ìlú yìí, àwọn ọ̀nà náà ni, ọ̀nà Èkó, Ṣómólú àti Ìkẹjà. Àwọn ẹ̀yà Yorùbá ni ó pọ̀jù nínú àwọn olùgbé agbègbè yí, tí ó sì jẹ́ èdè abínibí Yorùbá ni wọ́n ń sọ jù níbẹ̀