Omi: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

12 bytes added ,  16 Oṣù Kẹrin 2021
=== Ìgbàgbọ́ àti Ẹ̀sìn nípa omi ===
[[Fáìlì:River-SideShrineAndSacredGroveOfOsun.jpg|thumb|228x228px|Ojúbọ Ọ̀ṣun létí Odò Ọ̀ṣun ]]
Nínú ẹ̀sìn púpọ̀, wọ́n ka omi sí ohun mímọ́. Lílo omi fún ìmọ́ra wà nínú àwọn ẹ̀sìn mélòó kan, bí àpẹẹrẹ: [[Ìmàle|Ẹ̀sìn Ìmàle]], [[Ẹ̀sìn Krístì|Ẹ̀sìn Kírísítì]], [[Ìsìn Júù]], [[Ìṣẹ̀ṣe]], [[Ẹ̀sìn Híńdù]] àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ẹ̀sìn Kírísítì, wọ́n máa ń ṣe ''ìrìbọmi'' gẹ́gẹ́ bíi ''ìyàsímímọ́''. Ẹ̀sìn Ìmàle ń ṣe ''ghusl'' kí wọ́n tó gbàdúrà. <ref name="Odozor 2019">{{cite web | last=Odozor | first=Paulinus Ikechukwu | title=The Essence of African Traditional Religion | website=Church Life Journal | date=2019-02-21 | url=https://churchlifejournal.nd.edu/articles/the-essence-of-african-traditional-religion/ | access-date=2021-04-10}}</ref>
 
Ní Ìṣẹ̀ṣe, àwọn [[òrìṣà]] olómi wà. Àwọn tí wọ́n ń sìn wọ́pọ̀ jù lọ jẹ́: [[Ọ̀ṣun]], [[Yemọja]] àti [[Olókun]]. Òrìṣà Ọ̀ṣun àti Yemọja jẹ́ obìnrin, ṣùgbọ́n Olókun ò jẹ́ obìnrin tàbí ọkùnrin. Orúkọ ''Odò Ọ̀ṣun'' tó wà ní [[Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun]] ni wọ́n fàyọ láti orúkọ òrìṣà yẹn. Odò Ọ̀ṣun ni àwọn olùjọ̀sìn Ọ̀ṣun máa ń ṣayẹyẹ Ọ̀ṣun Òṣogbo lọ́dọọdún.
 
{{ekunrere}}