Ibadan Peoples Party (IPP): Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
Ṣ'èdá ojúewé pẹ̀lú "Ẹgbẹ́ ìṣèlú'''Ibadan Peoples Party''' (IPP) ni àwọn lààmì-laaka ọmọ bíbí ilẹ̀ Ìbàdàn tí wọ́n tako bí nkan ṣe ń lọ ní apá..."
 
kNo edit summary
Ìlà 1:
Ẹgbẹ́ ìṣèlú'''Ibadan Peoples Party''' (IPP) ni àwọn lààmì-laaka ọmọ bíbí ilẹ̀ [[Ìbàdàn]] tí wọ́n tako bí nkan ṣe ń lọ ní apá ìjọba ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ [[Yorùbá]] ṣe ń lọ sí. Wọ́n da ẹgbẹ́ ìṣèlú yí sílẹ̀ ní ọdún 1950s. Àwọn tí wọ́n jẹ́ abẹnugan inú ẹgbẹ́ náà ni [[Augustus Akinloye]] tí ó jẹ́ alága, nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà jẹ́: [[Adegoke Adelabu]], Olóyè Kola Balogun, Olóyè [[T. O. S. Benson]], Olóyè [[Adeniran Ogunsanya]] àti [[H. O. Davies]]. Lara àwọn tí.wọ́n tún jẹ́ àgbà-gbà nínú ẹgbẹ́ náà ni: Olóyè S. A. Akinyemi, Olóyè S. O. Lanlehin, Olóyè Moyo Aboderin, Olóyè Samuel Lana, Olóyè D. T. Akinbiyi, Olóyè S. Ajunwon, Olóyè S. Aderonmu, Olóyè R. S. Baoku, Olóyè Akin Allen àti Olóyè Akinniyi Olunloyo.
 
==Ipa tí ẹgbẹ́ ìṣèlú náà kò nínú ìdìbò ọdún 1951==
Ní àsìkò ìdìbò sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti apá ilẹ̀ [[Yorùbá]] ní apá Ìwọ̀ Oòrùn ti wá sópin ní ọdún 1951, ó jẹ́ ohun tí ó ya púpọ̀ọ̀ nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìṣèlú [[Action Group]] (AG) lẹ́nu wípé iye awọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn tí wọ́n wọlé sílé aṣòfin kò ju mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) lọ nínú àádọ́rin ayé tí ó ṣófo. Ba kan náà ni ẹgbẹ́ AG pàdánù pátá pátá ní ilú Ìbàdàn ati ní ìlú [[Èkó]] tí ó jẹ́ ola ìlú fún orílẹ̀-èdè [[Nàìjíríà]] nígbà náà. Èrò ẹgbẹ́ ìṣèlú AG ni wípé àwọn yóò ní ìbò tó pọ̀ jaburata nígbà tí ó jẹ́ wípé àwọn ni àyò àwọn ọmọ Yorùbá; ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ ìṣèlú IPP pèsè àwọn ọmọ oyè mẹ́fà ní Ìbàdàn, nígbà tí 3gbẹ́ ìṣèlú NCNC kó gbogbo àyè márùn a tó kú níléẹ̀ ní ìlú [[Èkó]].
Bí ìtàn náà ṣe lọ ni wípé: Ọ̀gbẹ́ni Harold Cooper, tí ó jẹ́ aṣojú ìjọba nígbà náà ní kí gbogbo ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan ó ṣe akọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọ oyè wọn kí ó Ma báà sí ìdàrú-dàpọ̀ níbi ètò ìdìbò lọ́dún náà. Ẹgbẹ́ Action Group nìkan ni ó tẹ̀lé àlàkalẹ̀ yí, àwọn ọmọ oyè ìdíje dupò lábẹ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú wọn sì ni: [[Obafemi Awolowo]] àti M.S. Sowole láti ẹkùn Ìjẹ̀bú Rẹ́mọ; S.O. Awokoya láti ẹkùn Ijẹ̀bú Òde, Rev. S.A. Banjo ati V.D. Phillips; Láti ẹkùn [[Ọ̀yọ́]]- Chief Bode Thomas, Abiodun Akerele, A.B.P. Martins, T.A. Amao ati SB Eyitayo; láti ẹkùn [[Ọ̀ṣun]]– SL Akintola, JO Adigun, JO Oroge, S.I. Ogunwale, I.A. Adejare, J.A. Ogunmuyiwa àti S.O. Ola; Láti ẹkùn [[Òndó]] – P.A. Ladapo ati G.A. Deko; Ẹkùn [[Òkìtìpupa]] – Dr. L.B. Lebi, CA Tewe àti SO Tubo; láti ẹkùn [[Ẹ̀pẹ́]] – SL Edu, AB Gbajumo, Obafemi Ajayi ati C.A. Williams; láti ẹkùn [[Ìkẹjà]]- O. Akeredolu-Ale, SO Gbadamosi ati FO Okuntola; Bẹkùn [[Agbádárìgì]] – Chief CD Akran, Akinyemi Amosu ati Rev. GM Fisher; Ekùn [[Ẹ̀gbá]] – [[J.F. Odunjo]], Alhaji A.T. Ahmed, CPA Cole, Rev S.A. Daramola, Akintoye Tejuoso, SB Sobande, IO Delano àti A Adedamola.
Lára wọn náà tún ni : ẹkùn ti [[Ẹ̀gbádò]] – J.A.O. Odebiyi, D.A. Fafunmi, Adebiyi Adejumo, A. Akin Illo àti P.O. Otegbeye; ẹkùn Ifẹ́ – Rev S.A. Adeyefa, D.A. Ademiluyi, J.O. Opadina, ati S.O. Olagbaju; ẹkùn [[Èkìtì]] – E.A. Babalola, Rev. J Ade Ajayi, S.K. Familoni, S.A. Okeya ati D Atolagbe; ẹkùn [[Ọ̀wọ̀]] – [[Michael Adekunle Ajasin]], A.O. Ogedengbe, JA Agunloye, LO Omojola àti R.A. Olusa; ẹkùn Ìwọ̀ Oòrùn [[Ijaw]] – Pere EH Sapre-Obi ati MF Agidee; láti ẹkùn [[Ishan]]] – [[Anthony Enahoro]]; láti ẹkùn [[Urhobo]] – WE Mowarin, J.B. Ohwinbiri àti JD Ifode; láti ẹkùn [[Warri]] – Arthur Prest àti O. Otere, àti [[Kukuruku Division]] – D.J.I. Igenuma.
==Àwọn ìtọ́ka sí==