Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
k mo tún àmì ohùn ṣe
kNo edit summary
Ìlà 28:
== Ìṣèlú ==
[[File:Obafemi Awolowo Entrance.jpg|thumb|left| Ẹnu ọ̀nà ilé Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀]]
Ní ọdún 1944 ó lọ sí ìlú [[London|Lọ́ńdọ́nù]] láki kọ́ ẹ̀kọ́ nínú [[imo ofinÒfin|ìmọ̀ òfin]] bẹ́ẹ̀ ni ó sì dá [[Egbe Omo Oduduwa|Ẹgbẹ́ Ọmọ Odùduwà]] sílẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ọdún 1947 ó darí padà wálé láti wá di agbẹjọ́rò àti akọ̀wé àgbà fún Ọmọ Ẹgbẹ́ Odùduwà. Lẹ́yìn ọdún méjì, Awólọ́wọ̀ àti àwọn aṣíwájú Yorùbá yòókù dá ẹgbẹ́ òṣèlú [[Action Group]] sílẹ̀, èyí tí ó borí nínú [[ibo|ìbò]] ọdún 1951 ní Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ Nàìjíríà. Láàárín ọdún 1951-54 Awólọ́wọ̀ jẹ́ Alákòóso Fún Iṣẹ́ Ìjọba àti Ìjọba Ìbílẹ̀, ó sì di Olórí Ìjọba Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọdún 1954 lẹ́yìn àtúnkọ Ìwé Ìgbépapọ̀ Àti Òfin (constitution).Gẹ́gẹ́ bí Olórí Ìjọba Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ Nàìjíríà, Awólọ́wọ̀ dá ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ sílẹ̀ fún gbogbo ọ̀dọ́ láti rí i pé mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà gba le ka.
 
=== Jàgídíjàgan ní apá ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà ===
[[File:Obafemi Awolowo Mausoleum.jpg|thumb|left|Ilé ọnà Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀]]
Nígbà tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gbòmìnira ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹwàá ọdún 1960, Awólọ́wọ̀ di Olórí Ẹgbẹ́ Alátakò (Opposition Leader) sí ìjọba [[Abubakar Tafawa Balewa]] àti Ààrẹ [[Nnamdi Azikiwe]] ní [[Èkó|Ìlú Èkó]]. Àìṣọ̀kan tó wà láàárín òun àti [[Samuel Ládòkè Akíntọ́lá]] tó dípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí fìdí hẹ Olórí Ìjọba ní [[Agbègbè Apáìwọ̀òrùn Nàìjíríà|Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn]] mú ni ó dá fàá ká ja tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1962. Ní oṣù kọkànlá ọdún yìí, [[Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà|Ìjọba Àpapọ̀]] ilẹ̀ Nàìjíríà fi ẹ̀sùn kan Awólọ́wọ̀ wí pé ó dìtẹ̀ láti dojú ìjọba bolẹ̀. Lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ ó tó oṣù mọ́kànlá, ilé-ẹjọ́ dá Awólọ́wọ̀ àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n lẹ́bi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀, wọ́n sì rán wọn lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá. Ọdún mẹ́ta péré ni ó lo ní ẹ̀wọ̀n ní ìlú [[Calabar|Kàlàbá]] tí ìjọba ológun [[Yakubu Gowon]] fi dá sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹjọ ọdún 1966. Lẹ́yìn èyí Awólọ́wọ̀ di Alákòóso Ìjọba Àpapọ̀ fún Ọrọ̀ Okòwò. Ní ọdún 1979 Awólọ́wọ̀ dá ẹgbẹ́ òṣèlú kan, [[Ẹgbẹ́ Òṣèlú Ìmọ́lẹ̀]], sílẹ̀.
 
== Aláìsí ==