Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò "Adegoke Adelabu"

9 bytes added ,  07:48, 28 Oṣù Kẹ̀wá 2021
k
Adélabú tí a bí sínú ẹbí ọ̀gbẹ́ni Sanusi Aṣiyanbí ati abilékọ Awujola Adélabú.{{sfn|Post|Jenkins|1973|p=33}} ní ọdún 1915. Ìyá Adélabú ni ó jẹ́ ìyàwó kejì nílé ọmọ rẹ̀ tí ó sì ṣílẹ̀ wọ̀ lẹ́yìn ìgbà diẹ̀ tí ó bí Adégòkè tan, èyí ni ó mú kí ẹ̀gbọ́n Ìyá rẹ̀ ó gbà á tọ́. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alàkalẹ̀ọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti [[Church Mission Society|C.M.S.]] ní Kúdẹtì nígboro ìlú Ìbàdàn láàrín ọdún 1925-1929, tí ó sì kàwé gba ''Standard IV àti V'' ní C.M.S. Central school, Mapo. Lóòtọ́ Musulumi ni oun àti ẹbí rẹ̀, amọ́ ọ̀dọ̀ Àbúrò bàbá rẹ̀ tí ó gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ mu lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ tí ó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹ́sì Kìrìstẹ́nì ní ìlú [[Ìbàdàn]], tí ó sì gba ìwé-ẹ̀rí ilé-ẹ̀kó náà tí fi lè wọ ilé-ẹ̀kọ́ CMS. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Government College ti ìlú [[Ìbàdàn]] láàrín ọdún {{sfn|Post|Jenkins|1973|p=36}} 1931 sí ọdún 1936 gẹ́gẹ́ bí aṣojú akẹ́kọ̀ọ́ inú ọgbà. Ní ọdún 1936, Adélabú wọ ilé-ẹ̀kọ́ [[Yaba Higher College]], lẹ́yìn èyí, ó rí ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ gbà lọ́wọ́ ilé-iṣẹ́ [[United Africa Company|UAC]] láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa imọ̀ okòwò.{{sfn|Post|Jenkins|1973|p=37}} Láìpẹ́, Adélabú kúrò nílé ẹ̀kọ́ lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí wọ́n fun ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́. Ọkàn nínú àwọn akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ tí ó ti mọ̀ ri ní ilé-iṣẹ́ [[kòkó]] tí ó tún jẹ́ ọ̀gá àgbà ní ilé-iṣẹ́ UAC fun ní iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ adarí àgbà ilé-iṣẹ́ wọn ní ìlú Ìbàdàn . Lẹ́yìn tí ó de ibẹ̀, Adélabú gbé ìgbésẹ̀ bí ilé-iṣẹ́ ṣe lè máa to kókó lọ́nà ará ọ̀tọ̀, ìgbésẹ̀ yí sì ni ó jẹ́ kí ó ri ìgbéga sípò igbákejì adarí lẹ́ka ìtajà. Adélabú kúrò ní ilé-iṣẹ́ UAC ní ọdún 1937 láti dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ owó kòkó títà fúnra rẹ̀, láìpẹ́, ó di lààmì-laaka nínú iṣẹ́ òwò kòkó rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó di gbajúmọ̀ níbi iṣẹ́ rẹ̀ tán ni ó bẹ̀rẹ̀ ní ń wá iṣẹ́ ìjọba. {{sfn|Post|Jenkins|1973|p=46}} Ó di olùbẹ̀wò agbà fún ohun ọ̀gbìn ní ọsún 1939. Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ UAC títí di ọdún 1945, Adélabú sì kúrò ní ilé-iṣẹ́ náà nígbà tí Richardson kúrò ní ilé-iṣẹ́ UAC. {{sfn|Post|Jenkins|1973|p=51}}. Lẹ́yìn èyí, Adélabú pa gbogbo [[owó]] tí ó ti rí kó jọ ní ó papọ̀ tí ó fi da òwò òwú sílẹ̀ pẹ̀lú ''Levantine'' ní ilẹ̀ Ìbàdàn.
 
=== Ọdún 1954–1958===
Ní àárín ọdún yí, Adélabú àti àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ̀ tako ẹgbẹ́ IPU àti [[Action Group|AG]] tí wọ́n pọ̀ ju ní ni inú ìgbìmọ̀ Ilé-Aṣòfin. Ó sì fi àtìlẹyìn rẹ̀ hàn sí [[àṣà]] àti ìṣe nípa wípé kí àwọn lọ́ba lọ́ba nípa pe kí wọ́n Ma ṣe san owó-orí.{{sfn|Onabanjo|1984|p=357}}Ní àsìkò ìdìbò abẹ́lé ní ọdún 1954, ẹgbẹ́ òṣèlú Alliance ni ó wọlé jùlọ sí àwọn àga ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀ Ìbàdàn, èyí ni ó sọ Adélabú di Alága gbogbo gbò fún ẹkùn náà.{{sfn|Sklar|p=297}} Adélabú borí nínú ìdìbò sílé aṣojú-ṣòfin àgbà ní ọdún 1954. Lẹ́yìn èyí, ó di igbá kejì Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú NCNC akọ́kọ́ tí wọ́n sì tún yàn án sípò Mínísítà fún iṣẹ́ òde tí ó sì tún dipò yí mú gẹ́gẹ́ bí Alàgbà ẹkùn Ìbàdàn láti inú oṣù kíní ọdún 1955 sí oṣù kíní ọdún 1956.