Zosso: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
New page: ‘ZOSSO’ ‘Zosso’ je Òrìsà àdáyé bá, tó je pé tí wón bá tí bí omo Àjara-Topá, ìyá omo náà kò ní je iyò títí osù ...
(Kò ní yàtọ̀)

Àtúnyẹ̀wò ní 06:33, 4 Oṣù Kejì 2007

‘ZOSSO’


‘Zosso’ je Òrìsà àdáyé bá, tó je pé tí wón bá tí bí omo Àjara-Topá, ìyá omo náà kò ní je iyò títí osù afi yo lókè. Tí osù yìí bá ti yo, won á gbé omo náa bó sí ìta láti fi osù han omo náà wí pé kí omo náà wo osù tí ó wá sáyé. Ní ojó náà ìyá omo náà yòó gbé omo náà bó sí ìta láìwo aso àti omo náà pàápàá tí òun àti omo rè yóò sì je iyò pèlú eja, won yóò sì tún fó èkùró sórí èwà láti fún ìyá omo náà je nígbà méje tó bájé obìnrin, èmésàn-án to ba je okùnrin. Léyìn tí wón bá ti se èyí tán, ìyá omo yóò gbé omo rè lo sí ìdí Òrìsà ‘Zosso’ láìwo aso ní ojó kejì, tí yóò sì ra otí dání láti sure fún omo náà gégé bí àsà. Won á sì padà sílé.

Nígbà tí ìyá omo náà bá dé ilé yoò fá irun orí omo rè, yóò sì lo ra igbá àti ìkòkò tuntun. Igbá yìí ni yóò fi bo ìkòkò náà lo sí odò ‘Zosso’. Omi odò yìí ni ìyá àti omo yóò fi wè títí omi yóò fi tàn. Òrìsà yìí máà n dáàbò bo àwon omode lówó aburú.