Lateef Adedimeji

(Àtúnjúwe láti Lateef Adédiméjì)

Lateef Adedimeji (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kìíní oṣù kejì ọdún 1986) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré, oǹkọ̀tàn àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ògùn ṣùgbọ́n tí wọ́n bí sí ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Lọ́dún 2013 ni ìràwọ̀ rẹ̀ gbòde kan lẹ́yìn látàrí ipa tí ó kó nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Kudi Klepto", tí Yéwándé Adékọ̀yà ṣe agbátẹrù rẹ̀. Lateef Adedimeji tí kópa nínú sinimá àgbéléwò tí ó ti ju ọgọ́rùn-ún lọ lẹ́yìn tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn. Ó gbajúmọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ilé iṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ Airtel fi fi í ṣe aṣojú wọn.[1] [2]

Lateef Adedimeji
Ọjọ́ìbíAbdullateef Adedimeji
(1986-02-01)1 Oṣù Kejì 1986
Oshodi, Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Orúkọ míràn"Crying Machine"
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iléẹ̀kọ́ gígaYunifásítì Olabisi Onabanjo
Iṣẹ́
  • Actor
  • Filmmaker
  • Scriptwriter
  • Director
  • Producer
Ìgbà iṣẹ́2007- Present
Olólùfẹ́Oyebade Adebimpe

Ìgbé-ayé àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, wọ́n bí Lateef Adédiméjì ní Ọjọ́ kìíní oṣù kejì ọdún 1986 ni ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ṣùgbọ́n ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ògùn ni.[3] O kàwé gboyè dìgírì nínú ìmọ̀ ìwé ìròyìn, ni ifáfitì Yunifásítì Olabisi Onabanjo.[4]


Ìgbé ayé tí ara ẹni àtúnṣe

Ni ọjọ kejidinlogun oṣù Kejìlá ọdún, 2021, Adedimeji fẹ afesona re , Oyebade Adebimpe ni ìgbéyàwó tí ọ l'arin rìn.[5]


Iṣẹ àtúnṣe

Lateef Adedimeji bẹrẹ sí ní se ere ori itage ni ọdún 2007,o sí bẹrẹ ìjọ pẹlu ,[6] a gba sí ilé ìwé ìjọ. Lateef Adedimeji jẹ Actor and Screenwriter. Lateef Adedimeji o ti farahàn ni orisiirisii èrè ori itage lati ọmọ ọdún mẹdogun sùgbón o bẹrẹ èrè ni ọdún 2007 nígbàtí o fara hàn lori ero amohun maworan Orisun TV. O bẹrẹ èrè ori itage lati ile iwe akọbẹrẹ started a Yàn láti sójú NGO gẹgẹ bí olufihan àrùn kogboogun HIV/AIDS campaign. Ipá rẹ ní lati sọ nípa àìsàn tí ọ bẹ ninu ìbálòpọ̀ human rights làti má ṣe àwòrán. Awọn ololufẹ rẹ mọ gẹgẹ bí ẹni tó mú iṣẹ rẹ ní okunkundun. O ti ṣe àfihàn pẹlu oríṣiríṣi awọn àgba òṣèré. Ni ọdún 2016, o gba àmì ẹ̀yẹ 2016 Best of Nollywood Awards fun eléré ti ọ da yangan julọ (Yoruba).[7] ni ọdún 2015,a ka mo ará awọn ti ọ yẹ ki o gba àmì ẹ̀yẹ City People Entertainment Awards fún eléré ọdún 2015. Lateef jẹ ẹni tí a má n gbe Gbagi fún Odunlade Adekola nitori won jọ ará wọn àti ìwùwà. O ni anfààní lati ṣiṣẹ pẹlú UNICEF nítori ìwé kíkọ .[8] a fún ní àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí ojú nollywood Nollywood male[9]during the ENigeria Newspaper Night of Honour on 30 October 2021.

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "lateef adedimeji". Google Search. Retrieved 2019-12-07. 
  2. "I was once paid N4,000 for lead role - Lateef Adedimeji » Tribune Online". Tribune Online. 2019-09-08. Retrieved 2019-12-07. 
  3. "Lateef Adedimeji Biography and Net Worth 2019". Archived from the original on 2019-10-06. Retrieved 2019-12-07. 
  4. "7 emerging Yoruba movie stars you need to know". Pulse.ng. 
  5. "See photos from actor Lateef Adedimeji wedding wit colleague Adebimpe Oyebade". 18 December 2021. 
  6. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :1
  7. "Lateef Adedimeji Biography". quopedia.blogspot.com. 
  8. "Lateef Adedimeji Biography and Network 2019". theinfopro.com. Archived from the original on 2019-10-06. Retrieved 2019-12-07. 
  9. "Premium Times – Nigeria leading newspaper for news, investigations" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 20 November 2021.