Àkíyèsí pàtàkì àtúnṣe

Ẹnlẹ́ níbẹ̀un oo Akintundedaniel, ẹ kú déédé àsìkò yí. Mo ṣàkíyèsí àwọn akitiyan àti ìlàkàkà yín láti ma ṣe àfikún sí Wikipedia èdè Yorùbá, inú wa sì dùn láti ri wípé ẹ ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá, àwọn àkíyèsí mi nípa àwọn àfikún yín rèé:

  1. Àwọn àyọkà yín ti ẹ kọ kò gún régé.
  2. Àgbékalẹ̀ àyọkà yín kò bá agbékalẹ̀ èdè Yorùbá mu látàrí ìlò irinṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánikọ̀wé.

Ẹ wo àyọkà ònkọ̀wé aláfikún tí èdè Yorùbá wọn mú yányán láti fi kọ́ bí a ṣe ń kọ èdè Yorùbá sílẹ̀ sórí Wikipedia èdè Yorùbá. wọ́n ṣe ṣe agbékalẹ̀ wọn fún itọ́ni yín bí a ṣe ń kọ èdè Yorùbá. Fúndí èyí, mo ma rọ̀ yín kí ẹ lọ ṣe àtúnṣe tí ó yẹ sí àwọn àyọkà yín tí ẹ ti ṣ'ẹ̀dá bíí Cross River State Library àti Ilé-ìkàwé Yunifásítì ti Ìpínlè kwara. dára dára kí wọ́n lè mọ̀yán lórí jù báyìí lọ. Mo ti ń gbìyànjú láti báa yín tún àyọkà èyí Simeon Adebo Library ṣe láti ọwọ́ ara mi, ṣùgbọ́n ó ń làmí lóòógùn nítorí wípé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń tunkọ láti ìbẹ̀rẹ̀ ni. Láfikún, mo ma gbà yín níyànjú kí ẹ ma kọ àwọn àyọkà yín síbìkan kí ẹ sì ma yẹ̀ wọ́n wò dára dára kí ẹ tó ṣẹ̀dá wọn sórí Wikipedia èdè Yorùbá. Èyí yóò jẹ́ kí ẹ mọ àwọn kùdìẹ̀ kudiẹ tí ó wà nínú wọn lásìkò, èyí kò sì ní ma là yín lóòógùn. Wikipedia èdè Yorùbá kò fàyè gba ìkọkúkọ tàbí Google translator bí ó ti wulẹ̀ kí ó mọ Mo fẹ́ kí ẹ tètè ṣe ìgbésẹ̀ lórí àkíyèsí mi yí ní kánmọ́ kánmọ́. Bí ọjọ́ mẹ́ta bá kọjá lẹ́yìn akíyèsí yìí tí n kò sì rí àtúnṣe lórí wọn, n ó dárúkọ àwọn àyọkà náà fún ìparẹ́.

Ẹ kúuṣẹ́Agbalagba (ọ̀rọ̀) 19:25, 7 Oṣù Kàrún 2024 (UTC)