ÀÀLỌ́ AJÁ ÀTI IJAPA
Ààlọ́ ooo
Ààlọ ọọọ
Àlọ́ yìí dá fìrìgbagbò
Ó dá lórí Ìjàpá ìrókò ọkọYánníbo àti Ajá[1]
Ní ìlú kan ni ayé àtijó, àwọn ẹranko méjì kan wà tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Àwọn ọ̀rẹ́ méjì náà ni Ìjàpátìrókò ọkọ Yánníbo àti Ajá. Iyàn mú púpọ̀ ní ìlú yìí débi wípé gbogbo igi wọ́wé tán, àgbàdo kọ̀ kò gbó, àwọn ọlọ́mọge lóyún, oyún gbẹ mọ́ wọn lára. Gbogbo akérémọdò wọ ẹ̀wù ìràwé. Iyàn náà mú gan-an ni. Ṣùgbọ́n bí Iyàn tí mú tóo, Ajá kò mọ Iyàn kankan, ṣe ni ara rẹ̀ ń dán yọ̀ọ̀. Bí Ajá ṣe ń dán tí ó tún sanra nínú Iyàn yìí ń kọ Ìjàpá lóminù. Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí ro ohun tí yíò ṣe.
Nígbà tí ó ṣe Ìjàpá tọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ Ajá lọ. Ó bẹ̀ẹ́ pé kí ó dákun ṣàánú òun kí ebi má lu òun àti àwọn ẹbí òun pa. Ajá sọ fún Ìjàpá pé kò wu òun náà kí ebi máa paa ṣùgbọ́n ìwà àgàbàgebè rẹ̀ ni kó jẹ́ kí òun sọ àṣírí ibi tí òun ti ń rí oúnjẹ jẹ. Ìjàpá bẹ Ajá pé òun kò ní dá'lẹ̀, àti pé òun yíò fi ọwọ́ sí ibi tí ọwọ́ gbé.
Nígbà tí ẹ̀bẹ̀ pọ̀, Ajá gbà láti mú Ìjàpá lọ. Ajá mú Ìjàpá lọ sí oko iṣu kan tí a kò mọ ẹni tí ó ni oko náà. Bí wọ́n ṣe dé'bẹ̀ ni Ajá wa iṣu tí ó lerù, ó sì ti múra láti padà sílé. Ṣùgbọ́n ní ti Ìjàpá, ó wa iṣu títí ilẹ̀ fi kún. Nígbà tí ó dìí, ó rí wípé òun kò le gbé, ó ti pọ̀ jù èyí tí òun lè gbé lọ. Ajá bẹ̀rẹ̀ sí pariwo kí ó yára ṣùgbọ́n ọ̀kánjúà ojú rẹ̀ kò jẹ́ kí ó gbọ́ igbe Ajá. Ajá bá bẹ̀rẹ̀ si kọ orin:[2]
ORIN ÀÀLỌ́
àtúnṣeAjá:_________ Ìjàpá dì mọ ń bá
Agbeorin:____ Teremọ́bá-teremọ̀bà tere
Ajá:________ bí ó bá dì mọ́ n ba; Ma súré sẹ́sẹ́ p'oloko; Ma rìnrìn gbẹ̀rẹ̀ pọlọ́jà Ma sòkú ọlọ́jà l'égbèje
Agbeorin:______Teremọ́bá-teremọ̀bà tere
Bí Ajá ṣe ń kọ orin yìí ni ó ń sáré lọ tete, nígbà tí Ìjàpá ń bá iṣu tí ó dì kalẹ̀ yí. Níbi tí Ìjàpá tí ń bá ẹrú iṣu ja ni olóko dé tí ó sì mú Ìjàpá lọ sí ilé Ọba. Ní ilé Ọba, Ìjàpá jẹ́wọ́ pé Ajá ni ó mú òun lọ sí inú oko tí àwọn tí lọ jí iṣu wà. Bí Ajá tí dé ilé ni ó ti mọ̀ pé wàhálà tí dé, ó dá ọgbọ́n, ó di ẹyin adìye sí kọ̀rọ̀ ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì, ó sì ṣe bí ẹni tí ara rẹ̀ kò yá, ó pirọrọ bí ẹni tí ó sùn lọ. Ọba si pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Ajá tí wọ́n jíṣẹ́ fún un pé ọba ń pè é, ó fi ẹyin tẹ ọkàn nínú ẹyin tí ó fi sí kọ̀rọ̀ ẹ̀rẹ̀kẹ́, ẹyin fọ́, ó sì dà sílè bí ẹni tí èébì gbe. Wọ́n mú Ajá dé ilé ọba ní àpàpàǹdodo. Bí wọ́n ṣe dé ilé ọba tí ọba sì bí léèrè bóyá òun ni ó mú Ìjàpá lọ jí iṣu wà lóko olóko, Ajá ní kí í ṣe òun torí pé òun ti ń ṣe àìsàn fún bíi ọ̀sẹ̀ kan. Bí ó sì ti wí báyìí ni ó tún fi eyín tẹ ẹyin tí ó wà ní kọ̀rọ̀ ẹ̀rẹ̀kẹ́ kejì ó sì dà sílè gọ̀ọ̀rọ̀gọ̀, ó dà bí pé Ajá ń bì. Ọba gba ohun tí Ajá sọ pé ara òun kò yá fún bí ìgbà díè. Ọba wá pàṣẹ pé kí wọ́n ti ojú Ìjàpá yọ idà, kí wọ́n sì ti ẹ̀yìn rẹ̀ ti bọọ.
Ẹ̀KỌ́ INÚ ÀÀLỌ́
àtúnṣeÌtàn yìí kọ́ wa wí pé kò yẹ kí á máa ṣe àṣejù sì gbogbo nǹkan.