Ìṣí ojúewé ètò àkọ́kọ́

Àyọkà tí a ṣàfihàn rẹ̀ lóní

Àwòrán Ise-ona funfun Iboju Iyaoba Idia ilu Benin

Ẹ̀gbà ọrùn bí ìbòju tí Benin jẹ́ ẹ̀gbà ọrùn tí wọ́n gbẹ́ lére tí ó sì jẹ́ àwòrán akọni obìrin tí a mọ̀ si ìyá wa Olorì Idia ti ọ̀rundún mẹ́rìndínlógún ṣẹ́yìn. Ọmọ rẹ̀ Esigie tí ó jẹ́ ọba  ti Benin maa ń wọ́ èyí tí ó jọọ́ fún àwọn ọmọ ogun ẹ̀yìn ìya olorì. Ibojú yìyí tí ó jọrawọ méjì ní ó wà: Ìkan wà ní Ilé ọnà ti a mọ̀ sí British Museum ní ìlú London tí ìkejì sì wà ní ilé ọnà tí a mọ̀ sí Metropolitan Museum of Art in New York City.

Àwọn àpẹẹrẹ rẹ̀ lórí àkọ́lé kan náà wà ní Seattle Art Museum àti Linden Museum, tí ìkan ná sì wà ní ilé ibi tí wọ́n kò gba gbogboògbò láyè láti wọ̀, gbogbo rẹ̀ ní wọ́n kó nígbà ìwádí lọ sí ìlú Benin ti ọdún 1897.

Ìbojú yìí ti di àmì ìdánimọ̀ lóde òní ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríá̀ láti ìgbà ìpéjọpọ̀ kan tí a mọ̀ sí FESTAC 77 tí ó wáyé ní ọdún 1977.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ó ní ìrísí èyí tí ó jọ Ìbojú Ìbílẹ̀ Aláwọ̀dúdú, kíní kékeré tí gúngùn rẹ̀ kò ju 24cm lọ kìí ṣé fún wíwọ̀ sójú, Ọba lè wọ̀ọ́ sọ́rùn (tí ó sì maa bá mu) tàbí bi "ìlẹ̀kẹ̀ ìbàdí " (èyí tí ó sì maa bá ayẹyẹ tí ó fẹ́ sẹe mu). Èyí tí ó wà ní ilé ọnà Met àti èyí tí ó wà ní ilé ọnà British fẹ́ jọ ara wọn, méjèèjì ni ó jẹ́ àwòràn Olorì Idia wearing ìlẹ̀kẹ̀ lórí, ìlẹ̀kẹ̀ lọ́rùn, ọgbẹ́ níwájú orí àti gbígbẹ́  èyí tí ó fàyè ọ̀nà méjì tí wọ́n lè fi ẹ̀gbà kọ́.

Lóde òní àwọn ènìyàn m,aa ń gbé onírú irú àworan tí ó jọ́ọ níbi ayẹyẹ láti lé ẹbọra búrúkú, ṣùgbọ́n ní bí ọrundún mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn, wọ́n lè maa lòó fún ayẹyẹ ìya ọba. Ó dàbí wípé ní bí ìbẹ̀rẹ̀ ọrúndún mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn ni wọ́n gbẹ́ àwọn ibojú méjèèjì, bóya ní ọdún 1520, nígbà tí Olorì Idia, ìyá ọba Oba Esigie, jẹ́ olùdájọ́ ní ilé ẹjọ́ ti Benin. (ìtẹ̀síwájú...)

Ìkàwé ní èdè míràn