ÀÀLỌ́ ERINMI, ÌJÀPÁ ÀTI ERIN ÒKÈ
Apààlọ́: Ààlọ́ o
Agbe Ààlọ: Ààlọ̀
Apààlọ́: Ààlọ mi dá lórí Ìjàpá tó dá'jà ṣílẹ̀ láárín Erin òkè àti Erinmi.[1]
Nígbà láíláí Erin Òkè àti Ìjàpá jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, Ìjàpá jẹ́ àgbè nígbà tí Erin òkè jẹ́ ògbójú ọdẹ apẹran. Ìjàpá àti Erin a máa ṣe pàṣípààrọ oúnjẹ oko bíi iṣu, ikàn ẹ̀gẹ́ ṣùgbọ́n kò tẹ́ Ìjàpá lọ́run bíi kí Erin Òkè máa fún ní eran lọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rẹ́ àti àgbà. Ijàpá ní lọ́kàn láti fi ìyà jẹ Erin òkè, Ìjàpá jẹ́ jomijòkè: ẹranko tó le gbé nílè àti nínú omi. Bíi Ìjàpá ṣe ń gba ẹran lọ́wọ́ Erin òkè bẹ́ẹ̀ lo ń gba eja lọ́wọ́ Erinmi.
Ní ọjọ́ kan, Ìjàpá lo bá Erin òkè pé kí ó bá òun wá ẹran ńlá ki òun fi se àsè fún àwọn ẹgbẹ́ òun, lèyí tí òun ṣe tán láti fi ẹja nla pààrò fun. Inú Erin òkè dùn láti bá Ìjàpá wá ẹran ńlá fi pààrò fún ẹja kí òun lè jẹ nkan mìíràn yàtọ̀ sí ẹran gbogbo ìgbà láì mọ̀ pé Ìjàpá fẹ́ fi ìyà jẹ òun ni.
Bákannáà, Ìjàpá tún lo bá Erinmi pé kí ó fún òun ní ẹja ńlá kí òun fi ẹran ńlá pààrò fun. Erinmi fun Ìjàpá ni ẹja bẹ́ẹ̀ ni Erin òkè fun Ìjàpá ni ẹran, ó sì dá ọjọ́ méje fún àwọn méjèèjì. Ìjàpá tòun taya àti àwọn ọmọ rẹ̀ ńṣe bẹ́ẹ̀ni wọ́n sọ. Kí ọjọ́ méje tó pe, ó twa i okùn àgbà to yii, o gbé lọ fún Erin òkè pe okùn náà ni yóò fi wọ́ ẹja ninu. Bẹ́ẹ̀ ó sọ fún Erinmi pé òun ti wá okùn tí yóò fi wọ́ ẹran láti òkè sinu omi
Nigbati ọjọ́ méje pe, Ìjàpá mú Erin òkè lọ sí etí odò lati fa eja jáde nínú ibu, bákan náà ó wọ inú omi lọ láti sọ okùn mó Erinmi lọ́rùn lát wọ́ ẹran sínú omi[3]. Bi Ìjàpá ṣe kúrò ni ọdọ Erinmi, tí ó rìn sókè díẹ̀ lo ti sọ fún àwọn méjèèjì pé ó yá o. Bẹ́ẹ̀ ni Erinmi n fa eran láti òkè tí Erin òkè sì ń ẹja láti inú ibú, gbogbo igi ń wo lókè bi Erin òkè ṣe ń jà fitafita láti fa eja bẹ́ẹ̀ ni odò n daru bí Erinmi náà se ń jà láti fa ẹran sínú omi. Àwọn méjèèjì gbìyànjú títí di ọ̀sán kí Erinmi tó so pé òun yóò gòkè lo wo ẹran naa. Báyìí ni o gán-án ní ọ̀rẹ́ re Erin òkè, wọ́n kí ara wọn pé Ìjàpá ló dá a ṣílẹ̀, inú bí Erin òkè ṣùgbọ́n Ìjàpá ti sa sábẹ́ ìràwé. Erinmi padà sínú omi bẹ́ẹ̀ni Erin Òkè padà sílé tí ó sì pinnu pé oun kò ṣíṣe ọdẹ mọ, bẹ́ẹ̀ ni ko jẹ eran mọ, ìṣe ọdẹ pípa ẹran ló fìyà jẹ òun lọ́wọ́ Ìjàpá. Láti ìgbà náà ni Erin ti ń jẹ koríko.[2]
Ẹ̀kọ́ Ààlọ
àtúnṣeÀlọ́ yí kọ́ wa pé:
Kí á ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú gbogbo ohun tí a bá ti ní.