Ààlọ́ Ìjàpá , Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ àti Adìẹ

Apààlọ́ :Ààlọ́ o!

Agbe Ààlọ́ :Ààlọ̀!

Apààlọ́ : Ààlọ́ mí dá gbà-á, ó dá gbò-ó, ó dá fìrìgbagbóò, o dálérí Ìjàpá tí ó fi ogbe orí Àkùkọ fún Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ jẹ.

Nígbà láíláí Ìjàpá àti Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn, àwọn ẹranko kéékèèké ni Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ máa ń jẹ, Ìjàpá a máa bá àwọn ẹranko náà ṣeré láti tàn wọ́n lọ fún Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láti pajẹ, a sì tún máa gbèjà Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹranko yókù. Ṣùgbọ́n gbogbo ìgbà tí Ìjàpá bá tan Àkùkọ lọ sọ́dọ̀ Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ni Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ máa n sá fun Àkùkọ. Àkùkọ kò fura pé Ìjàpá fẹ́ se òun ní ìjàmbá ni. Ìjàpá ṣe ìbéèrè lọ́wọ́ Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ìdí tí ó fi ń sá fún Àkókò, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ daa lóhùn pé iná orí Àkùkọ ni òun sa fún, pé ó lè jọ oun. Ìjàpá jẹ́ kó yé Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ pé kí ṣe iná, ẹran jọ̀bọ̀jọbọ ni, Ọlọ́run ló dá a pẹ̀lú rẹ̀ kí o le dá bò bò ó lọ́wọ́ ọ̀tá. Ìjàpá ní kí Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ wá kí àwọn lọ sílé Àkùkọ lálé kí ó le rí ìdánilójú nítorípé Àkùkọ má n tètè sùn bẹ́ẹ̀ni yóò sì tètè jí kí o le kéde fún àwọn ènìyàn pé ilé ti mọ́.

Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ gbà láti tẹ́lé Ìjàpá lọ sí ilé Àkùkọ, Ìjàpá di ogbe orí Àkùkọ mú, ó sì kí Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láyà pé kí ó wá di imú, tí o sì rí pé ẹran ni ogbe orí Adìe kì í ṣe iná. Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ já ogbe náà sẹ́nu, o dùn mọ́ ọn lẹ́nu, Adìẹ ta jí ẹ̀jẹ̀ ń dà lórí re; bẹ́ẹ̀ni ó feré gé e Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì gbá tẹ̀le, bẹ́ẹ̀ ladìẹ ń fò diẹ̀ díẹ̀, tó fìyẹ́ ńgbá lẹ̀ gẹẹrẹ, ló ń ké́ pé:

     Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, kí lorí?
     Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, kí lorí?
     Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, kí lorí? 

Báyì ni Adìẹ sá títí dé ahéré àgbẹ̀ kan. Àgbẹ̀ náà ló gba Adìẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀. Láti ìgbàyí ni Àgbẹ̀ ti n ́ sin Adìẹ, ti Adìẹ ti di èrò ilé, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì dì ọ̀tá Adìẹ di òní; bẹ́ẹ̀ ni Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì kúndùn Adìẹ.


Ẹ̀kọ́ Ààlọ́ àtúnṣe

Àlọ́ yí kọ́ wa pé" Ẹ̀hìnkùlè lọ̀tá wà, ilé laseni ńgbé." Ìjàpá tó jẹ́ òrẹ́ Àkùko ló fi ogbe orí rẹ̀ fún Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ jẹ. Nítorínáà, ẹ jẹ́ ká sóra fún ọ̀rẹ́ amọniseni, ọ̀rẹ́ ní pa ni, ọ̀rẹ́ ni la ni.

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

https://dokumen.tips/documents/akojopo-alo-ijapa-babalola.

https://ng.loozap.com/ads/akojopo-alo-ijapa-apa-kini/19079098[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́].