Àìsùn Kérésìmesì
Àìsùn Kérésìmesì ni ọjọ́ tàbí ìrólé tí ó kàn kí ó tó kan ọjọ́ Kérésìmesì, ìjọ tí a fi ń ṣe ayẹyẹ ibí Jésù.[2] Ìjọ Kérésìmesì jẹ́ ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yẹ́ sí káàkiri àgbáyé, Àìsùn Kérésìmesì sì wà lára àwọn ọjọ́ tí wón yẹ́ sí ní ìrètí ọjọ́ Kérésìmesì. Wọ́n ma ń ka ọjọ́ méjèèjì gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ayẹyẹ tí ó ṣe pàtàkì julo ni àwùjọ àwọn Kristẹni
Àìsùn Kérésìmesì | |
---|---|
Àìsùn Kérésìmesì, àwòrán kan tí J. Hoover àti ọmọ rẹ̀ yà ní ọdún 1878 | |
Also called | Irole Kérésìmesì Isoru Kérésìmesì ọjọ́ tí ó kàn kí ó tó kan Kérésìmesì |
Observed by | Àwọn Kristẹni Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí kì ń ṣe Kristẹni[1] |
Type | Christian, cultural |
Significance | Ọjọ́ tí ó kàn kí ó tó kan Kérésìmesì tàbí ọjọ́ ìbí Jésù |
Date | Àdàkọ:Blist |
Observances | Rira ẹ̀bùn, fífúnni ní ẹ̀bùn, ìkíni kú ọdún, ìwóde , ìṣe àwọn ìsìn kọ̀kan ni ìjọ, jíjẹ un, ìṣe ìpèsè fún Kérésìmesì |
Related to | Ìjọ Kérésìmesì, Àìsùn ọdún tungun, Ọjọ́ ọdún tuntun |
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjọ ma ń kóra jọ pò láti ṣe ìsìn, kọrin Kérésìmesì àti láti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan mìíràn láti ṣe ayẹyẹ ibí Jésù.[3] Nítorí pé Bíbélì mimọ ṣe àkọlé rẹ̀ pé a bí Jésù ni òru(Lúùkù 2:6-8), ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjọ ma ń ṣayẹyẹ ibí Jésù ní òru mọ́jú mọ ọjọ́ Kérésìmesì.[4]
Orísìírísìí ọ̀nà ni àwọn ènìyàn ń gbà ṣe ayẹyẹ ibí Jesu ní Àìsùn Kérésìmesì kakiri àgbáyé. Ọpọlọpọ ó kó jọ pẹ̀lú ará àti ìdílé wọn, àwọn mìíràn á kọrin Kérésìmesì, àwọn miran a fi iná àti àwọn nkan miran ṣe ilé ní ọ̀ṣọ́, wón ó sì ma gbà àti fún ni ní ẹ̀bùn.
Àwọn Ìtókasí
àtúnṣe- ↑ Christmas as a Multi-faith Festival—BBC News. Retrieved 24 November 2011.
- ↑ Mary Pat Fisher (1997). Living Religions: an encyclopedia of the world's faiths. I.B.Tauris. ISBN 9781860641480. https://books.google.com/books?id=ytOHbLdtSY4C&pg=PA314. Retrieved 29 December 2010. "Christmas is the celebration of Jesus' birth on earth."
- ↑ "Helgmålsringning". Natinalencyclopedin. Retrieved 29 December 2010.
- ↑ "Vatican Today". Archived from the original on 1 January 2011. Retrieved 29 December 2010. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)