Àjàkálẹ̀ Àrùn COVID-19 ní Orilẹ̀-èdè Niger
Àjàkálẹ̀ Àrùn COVID-19 ni wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ó ti tàn dé orílẹ̀-èdè olòmìnira Niger nínú oṣù Kẹ́ta ọdún 2020. Àjọ Amnesty International jábọ̀ rẹ̀ wípé àwọn kan fòfin gbé àwọn oníròyìn tí wọ́n ń kọ nípa àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ní orílẹ̀-èdè Niger, tí wọ́n sì ké sí ìjọba kí wọ́n dẹ́kùn ìwà ìtẹ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀.[2]
Àjàkálẹ̀ Àrùn COVID-19 ní Orilẹ̀-èdè Niger | |
---|---|
Àrùn | COVID-19 |
Irú kòkòrò èràn | SARS-CoV-2 |
Ibi | Niger |
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́ | Wuhan, China |
Index case | Niamey |
Arrival date | 19 March 2020 (4 years, 7 months and 5 days) |
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn | 1,099 (as of 12 July)[1] |
Active cases | 39 (as of 12 July) |
Iye àwọn tí ara wọn ti yá | 992 (as of 12 July) |
Iye àwọn aláìsí | 68 (as of 12 July) |
Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀
àtúnṣeNí ọjọ́ Kejìlá oṣù Kíní ọdún 2020, Àjọ ìṣọ̀kan tí ó ń rí sí ìlera ní àgbáyé fìdí àrùn Kòrónà tí a tún ń pè ní Kofid-19 ní orílẹ̀-m àgbáyé ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kínní ní ọdún 2020. Tí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àrùn yí bẹ̀rẹ̀ ní ìlú kan tí wọ́n ń pè ní Wuhan, ní ẹkùn Hubei ní orílẹ̀-èdè China. Àmọ́ ó tó ọjọ́ Kẹtalélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2019 kí wọ́n tó fi tó àjọ ìṣòkan àgbáyé létí.[3][4]
Wón tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ siwájú si wípé bí àrùn yí bá ti mú ènìyàn, oun ni ó ń fa ìfúnpinpin ní ní inú káà ọ̀fun ati àyà, tí ó sì ma ń fa kàtá tàbí kí ènìyàn ó ma wú ikọ́ tàbí sín léra léra. Iye ìjàmbá tí àrùn Kòrónà ti fà lágbáyé kéré sí iye ìjàmbá tí àìsàn àrùn ọ̀fun SARS ti fà láti ọdún 2003,[5][6] Àmọ́ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n tó àrùn Kòrónà látàrí ríràn tí ó ń ràn kálẹ̀ ti.pọ̀ ju ti SARS lọ, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wípé ìtànkálé àrùn COVID-19 ń gbópọn si lójojúmọ́ tí ó sì ti ṣekú pa ọ̀pọ̀lọpò ènìyàn lágbáyé.[7][5]
Bí ó ṣe ń ṣẹlẹ̀ láwọn àsìkò kọ̀ọ̀kan
àtúnṣeOṣù Kẹ́ta ọdún 2020
àtúnṣeOrílẹ̀-èdè olómìnira Niger ní akọsílẹ̀ akọ́kọ́ ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù Kẹ́ta ọdún 2020, ní ìlú Niamey. Ẹni tí ó kó àrùn náà wọ orílẹ̀-èdè náà ni ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógójì. Wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀.wípé aláàárẹ̀ náà ti ṣe ìrìn-àjò lọ sí àwọn ìlú bí Accra, Abidjan, Lomé ati Ouagadougou, ṣáájú kí ó tó darí sí orílẹ̀-èdè Niger.[8] Lẹ́yìn tí ìròyìn àrùn yí kálẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Niger, wọ́n ti àwọn pápákọ̀ òfurufú wọn pa láti tètè dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àrùn náà.[8] Ẹnìkẹta tí yóò kó àrùn yí wọ orílẹ̀-èdè Niger ni obìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Brazil kan tí ó wọ orílẹ̀-èdè Niger ní 9jọ́ Kẹfà oṣù Kẹ́ta ọdún 2020.[9]
Orílẹ̀-èdè Niger ti ní akọsílẹ̀ tí ó tó méje lápapọ̀ nígbà tí yóò fi di ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹ́ta ọdún 2020, ẹni kan ṣoṣo ni ó papò dà ní ọjọ́ Kẹrìnlélógún oṣù kẹta ní Ìlú Niamey, tí aláìsí náà sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta tí ó wá láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àpapọ̀ iye akọsílẹ̀ tí wọ́n pada rí ní orílẹ̀-èdè Niger ní inú oṣù Kẹ́ta jẹ́ Mẹ́rìnlélọ́gvọ̀n lápapọ̀, nígbà tí ènìyàn mẹ́ta papò dá nínú wọn. Èyí wá dín wọn kù sí mọ́kanlélọ́gbọ̀n. [10][11][12]
Oṣù Kẹ́rin ọdún 2020
àtúnṣeWọ́n tún ní akọsílẹ̀ iye ènìyàn tí ó tó 685 tí wọ́n ní àrùn COVID-19, èyí sì mú kí iye gbogbo àwọn aláìsàn Kòrónà ó di 719. Àwọn 452 rí ìwòsàn gbà nígbà tí àwọn 32 papò dà tí wọ́n gbọ̀run lọ. [13] .[14]
Oṣù Karùún ọdún 2020
àtúnṣeNínú oṣù yí, wọ́n tún ṣàwárí ọ̀tun nípa àwọn tí wọ́n ní kòkòrò àrùn COVID-9 tí wọ́n tó 239. Èyí mu kí ggbogbo iye àwọn aláìsàn náà di 958 lápapọ̀, tí iye àwọn tí wó di aláìsí di ìlópo méjì 64, tí àwọn 387 sì rí ìwòsàn gbà. Iye àwọn tó kù tí wọn kò kú tí wọn kò sí tíì gbádùn jẹ́ 55 ní ìparí oṣù Karùún. .[15]
Oṣù Kẹfà ọdún 2020
àtúnṣeNínú oṣù yí, wọ́n tún ṣàkọsílẹ̀ iye ènìyàn tí ó tó ọgọ́rùún kna àti mẹ́tàdìnlógún aláàrẹ̀. Èyí mú kí iye àwọn aláìsàn náà lápapọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ àjakálẹ̀ àrùn náà ó gùnkè lọ sí 1075. Iye àwọn tí kú jẹ́ 67 nígbà tí iye àwọn tí wọ́n rí ìwòsàn gbà jẹ́ 943, tí Iye àwọn tó kù tí wọn kò kú tí wọn kò sí tíì gbádùn jẹ́ 65. [16]
Ẹ tún lè wo
àtúnṣeÀwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Évolution du Coronavirus au Niger en temps réel – Coronavirus, Covid19" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-07-12.
- ↑ "Niger: Civil society organisations call on authorities to end harassment of human rights defenders" (in en). www.amnesty.org. https://www.amnesty.org/en/latest/news/2020/03/niger-societe-civile-demandent-un-terme/. Retrieved 25 March 2020.
- ↑ Elsevier. "Novel Coronavirus Information Center". Elsevier Connect. Archived from the original on 30 January 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Reynolds, Matt (4 March 2020). "What is coronavirus and how close is it to becoming a pandemic?". Wired UK. ISSN 1357-0978. https://www.wired.co.uk/article/china-coronavirus.
- ↑ 5.0 5.1 "Crunching the numbers for coronavirus". Imperial News. Archived from the original on 19 March 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "High consequence infectious diseases (HCID); Guidance and information about high consequence infectious diseases and their management in England". GOV.UK (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 3 March 2020. Retrieved 17 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "World Federation Of Societies of Anaesthesiologists – Coronavirus". www.wfsahq.org. Archived from the original on 12 March 2020. Retrieved 15 March 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ 8.0 8.1 "Le Niger enregistre son premier cas de coronavirus (Officiel)". Agence Nigérienne de Presse. 19 March 2020. http://www.anp.ne/?q=article/le-niger-enregistre-son-premier-cas-de-coronavirus-officiel.
- ↑ "CORONAVIRUS : 3ÈME CAS DÉCLARÉ AU NIGER…". L`innovation au service de l`information pour mieux informer. (in Èdè Faransé). Archived from the original on 2020-03-25. Retrieved 2020-03-25.
- ↑ "CORONAVIRUS : Sept (7) CAS ENREGISTRÉS DONT UN (1)MORT…". Archived from the original on 2020-04-13. Retrieved 2020-07-26.
- ↑ "CORONAVIRUS : Sept (7) CAS ENREGISTRÉS DONT UN (1)MORT…". L`innovation au service de l`information pour mieux informer. (in Èdè Faransé). Archived from the original on 2020-03-25. Retrieved 2020-03-25.
- ↑ "(COVID-19) Niger : le nombre de cas confirmés de coronavirus s’alourdit à 34" (in fr-FR). aNiamey.com. 1 April 2020. http://news.aniamey.com/h/96977.html.
- ↑ Future scenarios of the healthcare burden of COVID-19 in low- or middle-income countries, MRC Centre for Global Infectious Disease Analysis at Imperial College London.
- ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 102" (PDF). World Health Organization. 1 May 2020. p. 5. Retrieved 17 July 2020.
- ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 133" (PDF). World Health Organization. 1 June 2020. p. 6. Retrieved 17 July 2020.
- ↑ "Coronavirus disease (COVID-19) situation report 163" (PDF). World Health Organization. 1 July 2020. p. 7. Retrieved 17 July 2020.