Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 ní Ceuta

Wọ́n kọ́kọ́ kéde àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 ní àgbègbè ní agbègbè Ceuta lórílẹ̀ èdè Spain ní oṣù kẹta ọdún 2020.

Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 ní Ceuta
ÀrùnCOVID-19
Irú kòkòrò èrànSARS-CoV-2
IbiCeuta
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́Wuhan, Hubei, China via Spain
Arrival date13 March 2020
(4 years, 7 months, 1 week and 4 days)
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn222
Iye àwọn tí ara wọn ti yá218
Iye àwọn aláìsí
4

Bí ó ṣe ń jàkálẹ̀ láti ìgbà dé ìgbà

àtúnṣe

Oṣù kẹta ọdún 2020

àtúnṣe

Arákùnrin kan láti àgbègbè kan ní orílẹ̀-èdè Làìbéríà ló dé sí Ceuta pẹ̀lú àmìn àrùn Covid-19 lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kẹta ọdún 2020,tí wọ́n sìn gbé e lọ sílé ìwòsàn fún àyẹ̀wò fún ọjọ́ márùn-ún. Lẹ́yìn àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe fún un lọ́jọ́ kẹtàlá oṣù kẹta, èsì rẹ̀ fihàn pé ó ti kó àrùn náà.[1]

Oṣù kẹrin ọdún 2020

àtúnṣe

Lọ́jọ́ kẹrin Osun kẹrin, iye àwọn tí wọ́n ti ní àrùn náà ni àgbègbè Ceuta jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83), mẹ́rìnléláàádọ́rin ni wọ́n wà ní ilé wọn, méjì rí ìwòsàn, méje wà nílé ìwòsàn, tí ènìyàn méjì sìn ṣaláìsí.[2]

Odidi ènìyàn ọgọ́rùn-ún ni iye àpapọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n kéde pé wọ́n ti ní àrùn náà lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹrin ọdún 2020. Ẹni méjìlélógójì ni wọ́n rí ìwòsàn, tí ènìyàn mẹ́rin kú.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe