Àjẹsára Àwàlù Eyín

Àjẹsára Àwàlù Eyín (en:Tetanus), tí a tún mọ̀ sí tetanus toxoid (TT), jẹ́ àjẹsára tí à ń lò láti dènà àwalù eyín.[1] Ní ìgbà èwe, a gba ni nímọ̀ràn láti lo ìwọ̀n egbògi náà máàrún lẹ́yìn èyítí a ó ò má a lo àfikún ìwọ̀n egbògi náà tó yẹ ní ọdọọdún mẹ́ẹ̀wá mẹ́ẹ̀wá. Lẹ́yìn lílò ìwọ̀n egbògi náà mẹ́ta, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo ẹnití ó lòó ni yóò ní ààbò tó péye lọ́wọ́ àìsàn náà.[1] Fún àwọn tí kò gba àjẹsára àwàlù eyín wọn bó ti yẹ àti ní àkókò tó yẹ, a gbọ́dọ̀ fún wọn ní ìwọ̀n àjẹsára náà tí ń mú iṣẹ́ èyítí wọ́n ti gbà tẹ́lẹ̀ gbèrú síi, láàárín wákàtí 48 sí ìgbà yòówù tí wọ́n bá ní ìpalára tó bá egbò lọ.[2] Fún àwọn tí kò gba àjẹsára wọn lẹ́ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ tí wọ́n ní ìpalára tó bá egbò lọ tó léwu púpọ̀, a lè gbà wọ́n nímọ̀ràn láti gba abẹ́rẹ́ aporó àwàlù eyín. Gbígbé ìgbésẹ̀ láti ríi dájú pé àwọn obìnrin tó wà nínú oyún gba àjẹsára àwàlù eyín wọn bó ṣe tọ́ àti bó ti yẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí á fún wọn ní àjẹsára náà, jẹ́ ọ̀nà tí a lè gbà dènà àwàlù eyín àwọn ọmọ ìkókó tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí.[1]

Àjẹsára náà kò ní ewu kankan rárá, ó sì ṣeé lò bí ènìyàn bá lóyún àti bí ènìyàn bá ní àrùn HIV/AIDS. Ìrírí tó jẹ mọ́ pé kí ojú ibití a ti fún ni ní àbẹ́rẹ́ náà má a pupa yòò, kó sì má a dun ni a má a wáyé lára àwọn ènìyàn tó tó bíi 25 sí 85% nínú àwọn tó gba àjẹsára náà. Ibà, àárẹ̀, àti ìrora kékèké nínú iṣan-ara a má a wáyé lára àwọn ènìyàn tó kéré sí ìwọ̀n kan nínú ọgọ́ọ̀rún lára àwọn tó gba àjẹsára náà. Ìfèsì ara ẹni lọ́nà òdì sí ohun tí ènìyàn kòrira a má a wáyé lára àwọn ènìyàn tó kéré sí ìwọ̀n kan nínú 100,000 lára àwọn tó gba àjẹsára náà.[1]

Lára àwọn àdàlù àjẹsára tó ní àjẹsára àwàlù eyín nínú ni DTaP àti Tdap, tó ní àjẹsára gbẹ̀fun-gbẹ̀fun (diphtheria), ti àwàlù eyín, àti ti ikọ́ọfe (pertussis) nínú, pẹ̀lú DT àti Td tó ní àjẹsára gbẹ̀fun-gbẹ̀fun àti ti àwàlù eyín nínú. DTaP àti DT ni a ń fún àwọn ọmọdé tí ọjọ́-orí wọn kò tíì tó ọdún méèje nígbàtí a ń fún àwọn ọmọdé tó ti pé ọmọ ọdún méèje tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní Tdap àti Td.[3] Lẹ́tà kékeré tí a fi kọ d àti p ń ṣe àfihàn kíkéré agbára àjẹsára gbẹ̀fun-gbẹ̀fun àti ti ikọ́ọfe nínú àwọn àdàlù àjẹsára náà.[3]

Àjẹsára àwàlù eyín di ohun tó wà fún lílò ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà ní àwọn ọdún 1940.[1] Ìmúlò rẹ̀ mú kí ìwọ̀n ìṣẹ̀lẹ̀ àwàlù eyín dín kù pẹ̀lú ìwọ̀n 95%.[1] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé (World Health Organization), àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[4] Iye owó rẹ̀ lójú pálí jẹ́ 0.17 sí 0.65 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo ní ọdún 2014.[5] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó rẹ̀ jẹ́ 25 sí 50 USD.[6]

References

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 "Tetanus vaccine: WHO position paper" (PDF).
  2. "Puncture wounds: First aid".
  3. 3.0 3.1 "Vaccines: VPD-VAC/Tetanus/main page".
  4. "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF).
  5. "Vaccine, Tetanus Toxoid"[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́].
  6. Hamilton, Richart (2015).