Àjọ Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá, China, (The Chinese Football Association), (CFA) jẹ́ àjọ ẹgbẹ́ tí wọ́n ń darí eré bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá, eré bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá tí etí òkun àti eré bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá orí àpáta tí orílẹ̀ èdè China,[1][2] ní Mainland China. Wọ́n dá àjọ yìí sílẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ní Beijing, olú-ìlú China lọ́dún 1924, tí wọ́n sìn darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ FIFA lọ́dún 1931 kí wọ́n tó darí sí Taiwan lẹ́yìn ogun abẹ́lé Chinese Civil War. CFA dara pọ̀ mọ́ Asian Football Confederation lọ́dún 1974[3], lẹ́yìn èyí, wọ́n tún dara pọ̀ mọ́ FIFA lẹ́ẹ̀kan si lọ́dún 1979. Láti ìgbà tí wọ́n ti dara pọ̀ mọ́ FIFA, CFA kéde ara wọn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ tí kìí ṣe ti ìjọba àti ẹgbẹ́ tí kìí ṣe fún èrè jíjẹ, ṣùgbọ́n kò yàtọ̀ sí àjọ ti ìjọba tí wọ́n jẹ́ ẹ̀ka ìṣèjọba lábala bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá àjọ lẹ́ka eré-ìdárayá ìjọba China State General Administration of Sports.[4]
Nígbà tí wọ́n ṣe àtúndásílẹ̀ àjọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá China, (Chinese Football Association) lọ́dún 1955, wọ́n ṣe èyí láti wà lábẹ́ ìṣàkóso àjọ tó ń darí eré-ìdárayá tí China, the General Administration of Sports, tí wọn yóò sìn gba Ààrẹ àjọ náà, tí ó gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó ti wà lára àwọn alákòóso China PR national football teamyálà gẹ́gẹ́ bí adarí tàbí agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún 1989, àtúnṣe dé bá èyí nígbà tí àjọ náà ṣe àtúntò, tí wọ́n fẹ́ kí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ máa ṣàkóso àjọ náà, àti pàápàá, wọn kò fẹ́ kó lọ́wọ́ ìjọba nínú tàbí jẹ́ ẹgbẹ́ tí ó wà fún ìṣòwò jèrè, tí wọ́n sìn gba igbá-kejì àkọ́kọ́, èyí ipò tí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba nípa eré-ìdárayá bọ́lọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá máa ń dìmú tẹ́lẹ̀. Láti ìgbà náà lọ ní ìṣàkóso nípa àwọn ìdíje àti ìṣàkóso gbogbo nnkan tó jẹ mọ́ bọ́lọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá lórílẹ̀-èdè China tí wà lábẹ́ àkóso gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àjọ náà, tí Ààrẹ wọn kàn jẹ́ olùdarí wọn.